Àìsáyà
20 Ní ọdún tí Ságónì ọba Ásíríà rán Tátánì* lọ sí Áṣídódì,+ ó bá Áṣídódì jagun, ó sì gbà á.+ 2 Ní àkókò yẹn, Jèhófà gbẹnu Àìsáyà+ ọmọ Émọ́ọ̀sì sọ̀rọ̀, ó ní: “Lọ, kí o tú aṣọ ọ̀fọ̀* kúrò ní ìbàdí rẹ, kí o sì bọ́ bàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó wá ń rìn káàkiri ní ìhòòhò* àti láìwọ bàtà.
3 Jèhófà wá sọ pé: “Bí ìránṣẹ́ mi Àìsáyà ṣe rìn káàkiri ní ìhòòhò, láìwọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, láti fi ṣe àmì+ àti àpẹẹrẹ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sí Íjíbítì+ àti Etiópíà,+ 4 bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọba Ásíríà máa kó àwọn ẹrú Íjíbítì+ àti Etiópíà lọ sí ìgbèkùn, àwọn ọmọdékùnrin àtàwọn àgbà ọkùnrin, ní ìhòòhò àti láìwọ bàtà, ìdí wọn á sì hàn síta, Íjíbítì máa rin ìhòòhò.* 5 Ẹ̀rù máa bà wọ́n, ojú sì máa tì wọ́n torí Etiópíà tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé àti Íjíbítì tí wọ́n fi ń yangàn.* 6 Ní ọjọ́ yẹn, àwọn tó ń gbé ilẹ̀ etíkun yìí máa sọ pé, ‘Ẹ wo ohun tó ṣẹlẹ̀ sí ẹni tí a gbẹ́kẹ̀ lé, tí a sá lọ bá pé kó ràn wá lọ́wọ́, kó sì gbà wá lọ́wọ́ ọba Ásíríà! Báwo la ṣe máa yè bọ́ báyìí?’”