Sáàmù
3 Nítorí yóò gbà ọ́ lọ́wọ́ pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ,
Lọ́wọ́ àjàkálẹ̀ àrùn tó ń pani run.
Òtítọ́ rẹ̀+ yóò jẹ́ apata+ ńlá àti odi* ààbò.
5 O ò ní bẹ̀rù àwọn ohun tó ń kó jìnnìjìnnì báni ní òru+
Tàbí ọfà tó ń fò ní ọ̀sán+
6 Tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tó ń yọ́ kẹ́lẹ́ nínú òkùnkùn
Tàbí ìparun tó ń ṣọṣẹ́ ní ọ̀sán gangan.
7 Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú ní ẹ̀gbẹ́ rẹ
Àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ,
Àmọ́ kò ní sún mọ́ ọ.+
9 Nítorí o sọ pé: “Jèhófà ni ibi ààbò mi,”
O ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé* rẹ;+
Àjàkálẹ̀ àrùn kankan kò sì ní sún mọ́ àgọ́ rẹ.
14 Ọlọ́run sọ pé: “Nítorí ó nífẹ̀ẹ́ mi,* màá gbà á sílẹ̀.+
Màá dáàbò bò ó torí pé ó mọ* orúkọ mi.+
15 Yóò ké pè mí, màá sì dá a lóhùn.+
Màá dúró tì í nígbà wàhálà.+
Màá gbà á sílẹ̀, màá sì ṣe é lógo.