Jèhófà Ni Ibi Ìsádi Wa
“Nítorí tí ìwọ wí pé: ‘Jèhófà ni ibi ìsádi mi,’ . . . àjálù kankan kì yóò dé bá ọ.”—SÁÀMÙ 91:9, 10.
1. Èé ṣe tá a fi lè sọ pé Jèhófà ni ibi ìsádi wa?
JÈHÓFÀ jẹ́ ibi ìsádi tòótọ́ fáwọn èèyàn rẹ̀. Bí a bá ń sìn ín tọkàntọkàn, bí a tilẹ̀ ‘há wa gádígádí ní gbogbo ọ̀nà, a kò ní há wa ré kọjá yíyíra; bí ọkàn wa tilẹ̀ dàrú, kò ní jẹ́ láìsí ọ̀nà àbájáde rárá; bí a tilẹ̀ ń ṣe inúnibíni sí wa, a kò ní fi wá sílẹ̀ láìsí ìrànlọ́wọ́; bí a tilẹ̀ gbé wa ṣánlẹ̀, a kò ní pa wá run.’ Kí nìdí? Nítorí pé Jèhófà máa ń fún wa ní “agbára tí ó ré kọjá ìwọ̀n ti ẹ̀dá.” (2 Kọ́ríńtì 4:7-9) Bẹ́ẹ̀ ni o, Baba wa ọ̀run máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti gbé ìgbé ayé olùbẹ̀rù Ọlọ́run, a sì lè fi ọ̀rọ̀ onísáàmù náà sọ́kàn, pé: “Nítorí tí ìwọ wí pé: ‘Jèhófà ni ibi ìsádi mi,’ ìwọ ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé rẹ; ìyọnu àjálù kankan kì yóò dé bá ọ.”—Sáàmù 91:9, 10.
2. Kí la lè sọ nípa Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún àti ohun tó ṣèlérí?
2 Ó jọ pé Mósè ló kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún. Àkọlé kan sọ pé òun ló kọ Sáàmù àádọ́rùn-ún, Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún sì tẹ̀ lé e láìsí gbólóhùn kankan tó sọ pé ẹlòmíràn ló kọ ọ́. Bóyá ọ̀nà tá a gbà kọ Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún ni pé ńṣe làwọn kan ń dárin, táwọn míì ń gbè é; ìyẹn ni pé, ó lè jẹ́ ẹnì kan ló kọ́kọ́ gbé ohùn orin (91:1, 2), tí ẹgbẹ́ akọrin kan sì wá gbè é (91:3-8). Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé akọrin kan ṣoṣo ló kọrin tẹ̀ lé e (91:9a), tí ẹgbẹ́ akọrin sì wá gberin (91:9b-13). Lẹ́yìn náà, kó wá jẹ́ pé akọrin kan ṣoṣo ló kọ ìyókù (91:14-16). Èyí ó wù kó jẹ́, Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún ṣèlérí ààbò tẹ̀mí fáwọn Kristẹni ẹni àmì òróró gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ kan, ó sì pèsè irú ìdánilójú kan náà fún àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún Ọlọ́run.a Ẹ jẹ́ kí gbogbo àwa ìránṣẹ́ Jèhófà jùmọ̀ gbé sáàmù yìí yẹ̀ wò.
Ààbò ní ‘Ibi Ìkọ̀kọ̀ Ọlọ́run’
3. (a) Kí ni “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ”? (b) Kí ni a rí bá a ṣe ń gbé “lábẹ́ òjìji Olódùmarè”?
3 Onísáàmù náà kọ ọ́ lórin pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń gbé ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ yóò rí ibùwọ̀ fún ara rẹ̀ lábẹ́ òjìji Olódùmarè. Ṣe ni èmi yóò wí fún Jèhófà pé: ‘Ìwọ ni ibi ìsádi mi àti ibi odi agbára mi, Ọlọ́run mi, ẹni tí èmi yóò gbẹ́kẹ̀ lé dájúdájú.’” (Sáàmù 91:1, 2) “Ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ” jẹ́ ibi ààbò ìṣàpẹẹrẹ fún wa, pàápàá jù lọ fáwọn ẹni àmì òróró, tí Èṣù dìídì gbógun tì. (Ìṣípayá 12:15-17) Ì bá ti pa gbogbo wa run, bí kì í bá ṣe pé a wà nínú ààbò bí àwọn tó ń gbé lọ́dọ̀ Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí àlejò rẹ̀ nípa tẹ̀mí. Gbígbé “lábẹ́ òjìji Olódùmarè” túmọ̀ sí pé a forí pa mọ́ sábẹ́ òjìji, tàbí ìbòòji Ọlọ́run. (Sáàmù 15:1, 2; 121:5) Kò sí ibi ìsádi tàbí odi agbára tó tún láàbò tó Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ wa.—Òwe 18:10.
4. Kí ni onírúurú nǹkan tí Sátánì, “pẹyẹpẹyẹ” náà, ń lò, báwo sì ni a ṣe ń ja àjàbọ́?
4 Onísáàmù náà fi kún un pé: “Òun [Jèhófà] tìkára rẹ̀ yóò dá ọ nídè kúrò nínú pańpẹ́ pẹyẹpẹyẹ, kúrò nínú àjàkálẹ̀ àrùn tí ń fa àgbákò.” (Sáàmù 91:3) Ìdẹkùn tàbí pańpẹ́ ni pẹyẹpẹyẹ sábà máa ń lò ní Ísírẹ́lì ìgbàanì láti fi mú ẹyẹ. Ara pańpẹ́ tí Sátánì, “pẹyẹpẹyẹ” náà, ń lò ni ètò àjọ burúkú rẹ̀ àti “àwọn ètekéte” rẹ̀. (Éfésù 6:11) Ó máa ń dẹ pańpẹ́ pa mọ́ sójú ọ̀nà wa, láti ré wa lọ sínú ìwà búburú, kí ó sì ba tiwa jẹ́ nípa tẹ̀mí. (Sáàmù 142:3) Ṣùgbọ́n, nítorí pé a ti pa ìwà àìṣòdodo tì, “ọkàn wa dà bí ẹyẹ tí ó . . . yè bọ́ lọ́wọ́ pańpẹ́.” (Sáàmù 124:7, 8) A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà ń gbà wá lọ́wọ́ “pẹyẹpẹyẹ” burúkú yìí!—Mátíù 6:13.
5, 6. “Àjàkálẹ̀ àrùn” wo ló ń fa “àgbákò,” ṣùgbọ́n kí nìdí tí kò fi lè rí àwọn èèyàn Jèhófà gbé ṣe?
5 Onísáàmù náà mẹ́nu kan “àjàkálẹ̀ àrùn tí ń fa àgbákò.” Gẹ́gẹ́ bí àjàkálẹ̀ àrùn tí ń gbèèràn, nǹkan kan wà tí ń fa “àgbákò” fún ìdílé ẹ̀dá ènìyàn àti fún àwọn tí ń gbé ipò ọba aláṣẹ Jèhófà lárugẹ. Látàrí èyí, òpìtàn nì, Arnold Toynbee, kọ̀wé pé: “Látìgbà tí Ogun Àgbáyé Kejì ti parí ni ìfẹ́ orílẹ̀-èdè ẹni ti mú kí iye ìpínlẹ̀ tó fẹ́ gbòmìnira pọ̀ ní ìlọ́po méjì . . . Ẹ̀mí kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ló ń gun ọmọ aráyé lọ́wọ́ tá a wà yìí.”
6 Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá ni àwọn alákòóso kan ti ń tapo sí gbọ́nmi-si omi-ò-to láàárín àwọn orílẹ̀-èdè. Wọ́n ti sọ ọ́ di túláàsì fáwọn èèyàn láti máa júbà wọn tàbí onírúurú ère tàbí àwòrán. Ṣùgbọ́n láéláé, Jèhófà kò ní jẹ́ kí irú “àjàkálẹ̀ àrùn” bẹ́ẹ̀ ran àwọn èèyàn rẹ̀ olóòótọ́. (Dáníẹ́lì 3:1, 2, 20-27; 6:7-10, 16-22) Gẹ́gẹ́ bí ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé tó nífẹ̀ẹ́ ara wọn, Jèhófà là ń fún ní ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe, a kì í dá sí tọ̀tún tòsì níbàámu pẹ̀lú ìlànà Ìwé Mímọ́, a sì gbà láìsí ẹ̀tanú pé “ní gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù [Ọlọ́run], tí ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo ṣe ìtẹ́wọ́gbà fún un.” (Ìṣe 10:34, 35; Ẹ́kísódù 20:4-6; Jòhánù 13:34, 35; 17:16; 1 Pétérù 5:8, 9) Bí àwa Kristẹni tilẹ̀ ń fojú winá “àgbákò,” ìyẹn inúnibíni, inú wa ń dùn, a sì wà lábẹ́ ààbò tẹ̀mí ní “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ.”
7. Báwo ni Jèhófà ṣe ń ‘fi àwọn ìyẹ́ rẹ̀’ dáàbò bò wá?
7 Níwọ̀n bí Jèhófà ti jẹ́ ibi ìsádi wa, a ń rí ìtùnú nínú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Òun yóò fi àwọn ìyẹ́ rẹ̀ àfifò dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ rẹ, ìwọ yóò sì sá di abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ̀. Òótọ́ rẹ̀ yóò jẹ́ apata ńlá àti odi ààbò.” (Sáàmù 91:4) Ọlọ́run máa ń dáàbò bò wá, àní gẹ́gẹ́ bí ẹyẹ ti ń ràdọ̀ bo ọmọ rẹ̀. (Aísáyà 31:5) ‘Ó ń fi ìyẹ́ rẹ̀ dí ọ̀nà àbáwọlé sọ́dọ̀ wa.’ Ẹyẹ máa ń na ìyẹ́ bo àwọn ọmọ rẹ̀, kí ó lè fi dáàbò bò wọ́n kúrò lọ́wọ́ àwọn tó fẹ́ pa wọ́n jẹ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹyẹ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gúnyẹ̀ẹ́, kò séwu fún wa lábẹ́ ìyẹ́ ìṣàpẹẹrẹ Jèhófà, nítorí pé a ti fara pa mọ́ sábẹ́ ètò àjọ rẹ̀ tó jẹ́ ti àwọn Kristẹni tòótọ́.—Rúùtù 2:12; Sáàmù 5:1, 11.
8. Báwo ni “òótọ́” Jèhófà ṣe jẹ́ apata ńlá àti odi ààbò?
8 A gbẹ́kẹ̀ lé “òótọ́.” Ńṣe ló dà bí apata ńlá ayé ọjọ́un, tó ní igun mẹ́rin, tó sì tóbi tó láti dáàbò bo gbogbo ara èèyàn. (Sáàmù 5:12) Gbígbẹ́kẹ̀lé irú ààbò bẹ́ẹ̀ kì í jẹ́ ká fòyà. (Jẹ́nẹ́sísì 15:1; Sáàmù 84:11) Gẹ́gẹ́ bíi ti ìgbàgbọ́ wa, òótọ́ tó tọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá jẹ́ apata ààbò ńlá tó ń paná ohun ọṣẹ́ oníná Sátánì, tó sì ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ ìkọlù ọ̀tá. (Éfésù 6:16) Ó tún jẹ́ odi ààbò, ìyẹn odi lílágbára tá a lè dúró sẹ́yìn rẹ̀ láìmikàn.
‘A Ò Ní Fòyà’
9. Èé ṣe tí òru fi lè jẹ́ àkókò ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀, àmọ́ kí nìdí tí ẹ̀rù ò fi bà wá?
9 Nítorí ààbò Ọlọ́run, onísáàmù náà sọ pé: “Ìwọ kì yóò fòyà ohunkóhun tí ń múni kún fún ìbẹ̀rùbojo ní òru, tàbí ọfà tí ń fò ní ọ̀sán, tàbí àjàkálẹ̀ àrùn tí ń rìn nínú ìṣúdùdù, tàbí ìparun tí ń fini ṣe ìjẹ ní ọjọ́kanrí.” (Sáàmù 91:5, 6) Níwọ̀n bí àwọn èèyàn ti máa ń fi òkùnkùn bojú ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ ibi, òru lè jẹ́ àkókò ẹ̀rùjẹ̀jẹ̀. Nínú òkùnkùn tẹ̀mí tó bo ayé báyìí, àwọn ọ̀tá wa sábà máa ń fi àwọn nǹkan kan ṣe bojúbojú kí wọ́n lè ráyè ba ìdúró tẹ̀mí wa jẹ́, kí wọ́n sì dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Ṣùgbọ́n ‘a ò fòyà ohunkóhun tí ń múni kún fún ìbẹ̀rùbojo ní òru,’ torí pé Jèhófà ń ṣọ́ wa.—Sáàmù 64:1, 2; 121:4; Aísáyà 60:2.
10. (a) Kí ló jọ pé “ọfà tí ń fò ní ọ̀sán” ń tọ́ka sí, báwo la sì ṣe ń kojú rẹ̀? (b) Báwo ni “àjàkálẹ̀ àrùn tí ń rìn nínú ìṣúdùdù” ṣe rí, èé sì ti ṣe tí a kò bẹ̀rù rẹ̀?
10 Ó jọ pé àwọn òkò ọ̀rọ̀ ni “ọfà tí ń fò ní ọ̀sán” ń tọ́ka sí. (Sáàmù 64:3-5; 94:20) Bí a ṣe ń tẹra mọ́ fífún àwọn èèyàn ní ìsọfúnni tòótọ́, òtúbáńtẹ́ ni irú àtakò ojúkorojú bẹ́ẹ̀ lòdì sí iṣẹ́ ìsìn mímọ́ wa ń já sí. Láfikún sí i, a kì í bẹ̀rù “àjàkálẹ̀ àrùn tí ń rìn nínú ìṣúdùdù.” Èyí jẹ́ àjàkálẹ̀ àrùn ìṣàpẹẹrẹ, tí ń gbèèràn nínú òkùnkùn ayé yìí tó ti di olókùnrùn nípa ti ìwà rere àti nípa ti ọ̀ràn ẹ̀sìn, tó sì wà lábẹ́ agbára Sátánì. (1 Jòhánù 5:19) Àjàkálẹ̀ àrùn yìí ń pa èrò inú àti ọkàn kú, ó ń sọ àwọn èèyàn di aláìmọ̀kan nípa Jèhófà, nípa ète rẹ̀, àti nípa àwọn ìpèsè onífẹ̀ẹ́ rẹ̀. (1 Tímótì 6:4) Ẹ̀rù ò bà wá nínú òkùnkùn yìí, níwọ̀n bí a ti wà nínú ìmọ́lẹ̀ yòò nípa tẹ̀mí.—Sáàmù 43:3.
11. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn tí a ‘ń fi ṣe ìjẹ ní ọjọ́kanrí’?
11 Bẹ́ẹ̀ náà ni “ìparun tí ń fini ṣe ìjẹ ní ọjọ́kanrí” kì í kó jìnnìjìnnì bá wa. “Ọjọ́kanrí” lè tọ́ka sí ohun tí ayé ń pè ní ọ̀làjú. Àwọn tó bá jẹ́ kí ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì kó sí àwọn lórí máa ń kàgbákò nípa tẹ̀mí. (1 Tímótì 6:20, 21) Bá a ti ń fi àìṣojo pòkìkí ìhìn rere Ìjọba náà, a kì í bẹ̀rù èyíkéyìí lára àwọn ọ̀tá wa, torí pé Jèhófà ni Aláàbò wa.—Sáàmù 64:1; Òwe 3:25, 26.
12. Ẹ̀gbẹ́ ta ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti ń “ṣubú,” lọ́nà wo sì ni?
12 Onísáàmù náà tẹ̀ síwájú, ó ní: “Ẹgbẹ̀rún yóò ṣubú àní lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ, àti ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ; kì yóò sún mọ́ ọ. Kìkì ojú rẹ ni ìwọ yóò máa fi wò ó, tí ìwọ yóò sì rí, àní ẹ̀san iṣẹ́ àwọn ẹni burúkú.” (Sáàmù 91:7, 8) Nítorí pé àwọn èèyàn kọ̀ láti fi Jèhófà ṣe ibi ìsádi wọn, ọ̀pọ̀ ló ń “ṣubú,” tí wọ́n ń kú nípa tẹ̀mí, “àní lẹ́gbẹ̀ẹ́” wa. Ká kúkú sọ pé “ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá” ti ṣubú ní “ọwọ́ ọ̀tún” àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tẹ̀mí lóde òní. (Gálátíà 6:16) Àmọ́, yálà a jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ti ṣèyàsímímọ́, a wà lábẹ́ ààbò ní “ibi ìkọ̀kọ̀” Ọlọ́run. A kàn ‘ń wo bí ẹ̀san ṣe ń ké lórí àwọn ẹni burúkú’ ni, bí wọ́n ti ń tinú àjálù kan bọ́ sínú àjálù mìíràn nínú ọ̀ràn ọrọ̀ ajé, nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn, àti láwọn ọ̀nà míì.—Gálátíà 6:7.
‘Àjálù Kankan Kò Ní Dé Bá Wa’
13. Àwọn àjálù wo ni kì í dé bá wa, èé sì ti ṣe?
13 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ààbò gidi kò sí nínú ayé yìí mọ́, a ń fi Ọlọ́run sí ipò àkọ́kọ́, a sì ń fi ọ̀rọ̀ onísáàmù náà gba ara wa níyànjú, pé: “Nítorí tí ìwọ wí pé: ‘Jèhófà ni ibi ìsádi mi,’ ìwọ ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ibùgbé rẹ; ìyọnu àjálù kankan kì yóò dé bá ọ, àní àrùnkárùn kì yóò sún mọ́ àgọ́ rẹ.” (Sáàmù 91:9, 10) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà ni ibi ìsádi wa. Àmọ́, a tún ti fi Ẹni Gíga Jù Lọ ṣe ‘ibùgbé wa,’ níbi tá a ti lè rí ààbò. A ń kókìkí Jèhófà gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ Ayé òun Ọ̀run, a ń ‘gbé’ inú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Orísun ààbò wa, a sì ń kéde ìhìn rere Ìjọba rẹ̀. (Mátíù 24:14) Fún ìdí yìí, ‘àjálù kankan kì yóò dé bá wa’—kò síkankan lára àjálù tá a ti mẹ́nu kàn ṣáájú nínú sáàmù yìí tí yóò dé bá wa. Kódà nígbà tí àwọn àjálù bí ìsẹ̀lẹ̀, ìjì líle, ìkún omi, ìyàn, àti rògbòdìyàn ogun bá ṣẹlẹ̀ láyìíká wa, àjálù wọ̀nyí kì í ba ìgbàgbọ́ wa tàbí ààbò tẹ̀mí wa jẹ́.
14. Èé ṣe tí àwọn àjàkálẹ̀ àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí kì í ran àwa ìránṣẹ́ Jèhófà?
14 Àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró dà bí àtìpó tí ń gbé inú àwọn àgọ́ tó jìnnà sí ètò àwọn nǹkan yìí. (1 Pétérù 2:11) ‘Àní àrùnkárùn kì í tiẹ̀ sún mọ́ àgọ́ wọn.’ Ìrètí wa ì báà jẹ́ ti ọ̀run tàbí ti ayé, a kì í ṣe apá kan ayé, àwọn àjàkálẹ̀ àrùn gbẹ̀mígbẹ̀mí tó ń bá ayé fínra nípa tẹ̀mí kì í sì í ràn wá, irú bí ìṣekúṣe, ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì, ẹ̀sìn èké, àti ìjọsìn “ẹranko ẹhànnà náà” àti “ère” rẹ̀, ìyẹn Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè.—Ìṣípayá 9:20, 21; 13:1-18; Jòhánù 17:16.
15. Ọ̀nà wo làwọn áńgẹ́lì gbà ń ràn wá lọ́wọ́?
15 Onísáàmù náà tún sọ síwájú sí i nípa ààbò tá a ń gbádùn, pé: “Òun [Jèhófà] yóò pa àṣẹ fún àwọn áńgẹ́lì rẹ̀ nítorí rẹ, láti máa ṣọ́ ọ ní gbogbo ọ̀nà rẹ. Ọwọ́ wọn ni wọn yóò fi gbé ọ, kí ìwọ má bàa fi ẹsẹ̀ rẹ gbún òkúta kankan.” (Sáàmù 91:11, 12) A ti fún àwọn áńgẹ́lì láṣẹ láti dáàbò bò wá. (2 Àwọn Ọba 6:17; Sáàmù 34:7-9; 104:4; Mátíù 26:53; Lúùkù 1:19) Wọ́n ń fi ìṣọ́ ṣọ́ wa ‘ní gbogbo ọ̀nà wa.’ (Mátíù 18:10) Àwa olùpòkìkí Ìjọba náà ń rí ìtọ́sọ́nà àti ààbò àwọn áńgẹ́lì, a kì í sì í kọsẹ̀ nípa tẹ̀mí. (Ìṣípayá 14:6, 7) Àní ‘àwọn òkúta’ bíi fífòfinde iṣẹ́ wa kò lè mú wa kọsẹ̀, ká sì pàdánù ojú rere Ọlọ́run.
16. Báwo ni ìgbéjàkoni “ẹgbọrọ kìnnìún” ṣe yàtọ̀ sí ti “ṣèbé,” báwo la sì ṣe ń kojú wọn?
16 Onísáàmù náà tẹ̀ síwájú pé: “Ìwọ yóò rìn lórí ẹgbọrọ kìnnìún àti ṣèbé; ìwọ yóò tẹ ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ejò ńlá mọ́lẹ̀.” (Sáàmù 91:13) Gan-an gẹ́gẹ́ bí ẹgbọrọ kìnnìún ti ń kù gìrì láti gbéjà koni, bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọ̀tá wa kan ṣe ń pa kuuru mọ́ wa nípa ṣíṣe àwọn òfin tí wọ́n fẹ́ fi dá iṣẹ́ ìwàásù wa dúró. Ṣùgbọ́n àwọn kan tún máa ń yọ sí wa ní ìjafùú, bíi ṣèbé tí ń gbéjà koni láti ibi ìlùmọ́. Nígbà míì, àwọn àlùfáà máa ń gọ sẹ́yìn àwọn aṣòfin, àwọn adájọ́, àtàwọn míì, láti gbéjà kò wá. Àmọ́ pẹ̀lú ìtìlẹyìn Jèhófà, láìjà, láìta, a máa ń ké gbàjarè lọ sílé ẹjọ́, a sì ń tipa báyìí ‘gbèjà, a sì ń fìdí ìhìn rere múlẹ̀ lọ́nà òfin.’—Fílípì 1:7; Sáàmù 94:14, 20-22.
17. Báwo la ṣe ń tẹ “ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀” mọ́lẹ̀?
17 Onísáàmù náà sọ̀rọ̀ nípa títẹ “ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ àti ejò ńlá” mọ́lẹ̀. Ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ lè fa ẹran ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ, àkòtagìrì sì ni ejò ńlá. (Aísáyà 31:4) Àmọ́ bó ti wù kí ẹgbọrọ kìnnìún onígọ̀gọ̀ rorò tó nígbà tó bá ń yọwọ́ ìjà, ńṣe la ń tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nípa ṣíṣègbọràn sí Ọlọ́run dípò àwọn èèyàn tàbí ètò àjọ oníwà bíi kìnnìún. (Ìṣe 5:29) Nítorí náà, “kìnnìún” tí ń bú ramúramù kò lè ṣe wá léṣe nípa tẹ̀mí.
18. “Ejò ńlá” náà lè rán wa létí nípa ta ni, kí ló sì yẹ ká ṣe tó bá gbéjà kò wá?
18 Nínú ìtumọ̀ ti Septuagint lédè Gíríìkì, “dírágónì” ni wọ́n pe “ejò ńlá” náà. Ó ṣeé ṣe kí èyí tètè rán wa létí “dírágónì ńlá náà . . . , ejò ìpilẹ̀ṣẹ̀ náà, ẹni tí a ń pè ní Èṣù àti Sátánì.” (Ìṣípayá 12:7-9; Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ńṣe ló dà bí òjòlá tó máa ń ṣẹ́ ẹran tó bá fẹ́ pa jẹ léegun ẹ̀yìn, táá sì wá gbé e mì. (Jeremáyà 51:34) Nígbà tí Sátánì bá ń gbìyànjú láti wé ara rẹ̀ mọ́ wa, kí ó lè fi àwọn pákáǹleke ayé yìí ṣẹ́ wa léegun ẹ̀yìn, kí ó sì gbé wa mì, ẹ jẹ́ ká já ara wa gbà, ká sì tẹ “ejò ńlá” yìí ní àtẹ̀rẹ́. (1 Pétérù 5:8) Ìyókù àwọn ẹni àmì òróró gbọ́dọ̀ ṣe èyí, bí wọn yóò bá kópa nínú ìmúṣẹ Róòmù 16:20.
Jèhófà—Orísun Ìgbàlà Wa
19. Kí nìdí tá a fi fi Jèhófà ṣe ibi ìsádi wa?
19 Onísáàmù náà gbẹnu sọ fún Ọlọ́run, nígbà tó sọ nípa olùjọsìn tòótọ́ pé: “Nítorí pé òun darí ìfẹ́ni rẹ̀ sí mi, èmi pẹ̀lú yóò pèsè àsálà fún un. Èmi yóò dáàbò bò ó nítorí pé ó ti wá mọ orúkọ mi.” (Sáàmù 91:14) Gbólóhùn náà, “Èmi yóò dáàbò bò ó,” ní ṣáńgílítí túmọ̀ sí, “Èmi yóò gbé e lékè,” ìyẹn níbi tí ọwọ́ ò ti ní tó o. Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà fi í ṣe ibi ìsádi wa, pàápàá jù lọ nítorí pé ‘a nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.’ (Máàkù 12:29, 30; 1 Jòhánù 4:19) Ẹ̀wẹ̀, Ọlọ́run ‘ń dáàbò bò wá’ kúrò lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa. A ò ní run kúrò lórí ilẹ̀ ayé láé. Kàkà bẹ́ẹ̀, a ó gbà wá là nítorí pé a mọ orúkọ Ọlọ́run, a sì ń fi ìgbàgbọ́ ké pè é. (Róòmù 10:11-13) A sì ti pinnu láti ‘máa rìn ní orúkọ Jèhófà títí láé.’—Míkà 4:5; Aísáyà 43:10-12.
20. Ní apá ìparí Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún, kí ni Jèhófà ṣèlérí fún ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?
20 Ní apá ìparí Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún, Jèhófà sọ nípa ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ pé: “Òun yóò ké pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn. Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú wàhálà. Èmi yóò gbà á sílẹ̀, èmi yóò sì ṣe é lógo. Gígùn ọjọ́ ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn, èmi yóò sì jẹ́ kí ó rí ìgbàlà mi.” (Sáàmù 91:15, 16) Ọlọ́run máa ń gbọ́ wa nígbà tá a bá ké pè é nínú àdúrà, níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ rẹ̀. (1 Jòhánù 5:13-15) Kékeré kọ́ lohun tójú wa ti rí nítorí ogun tí Sátánì ń gbé kò wá. Ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ náà, “Èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú wàhálà,” ń múra wa sílẹ̀ fún àwọn àdánwò ọjọ́ iwájú, ó sì fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé Ọlọ́run yóò mẹ́sẹ̀ wa dúró nígbà tá a bá pa ètò búburú yìí run.
21. Báwo ló ṣe jẹ́ pé a ti ṣe àwọn ẹni àmì òróró lógo ní báyìí ná?
21 Láìfi àtakò onínú burúkú tí Sátánì ń ṣe pè, gbogbo àwọn ẹni àmì òróró tí ń bẹ láàárín wa pátá ni a ó ṣe lógo ní ọ̀run nígbà tó bá tó àkókò lójú Jèhófà—lẹ́yìn “gígùn ọjọ́” lórí ilẹ̀ ayé. Síbẹ̀, ìgbàlà pípabanbarì látọwọ́ Ọlọ́run ti mú ògo tẹ̀mí wá fún àwọn ẹni àmì òróró ní báyìí ná. Ẹ sì wo iyì ńláǹlà tí wọ́n ní, bí wọ́n ti ń mú ipò iwájú gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórí ilẹ̀ ayé ní àwọn ọjọ́ ìkẹyìn wọ̀nyí! (Aísáyà 43:10-12) Ìgbàlà gíga jù lọ tí Jèhófà máa ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ yóò wáyé nígbà ogun ńlá rẹ̀ ní Amágẹ́dọ́nì, nígbà tí yóò dá ipò ọba aláṣẹ rẹ̀ láre, tí yóò sì sọ orúkọ mímọ́ rẹ̀ di mímọ́.—Sáàmù 83:18; Ìsíkíẹ́lì 38:23; Ìṣípayá 16:14, 16.
22. Àwọn wo ni yóò ‘rí ìgbàlà Jèhófà’?
22 Yálà a jẹ́ Kristẹni ẹni àmì òróró tàbí alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ti ṣèyàsímímọ́, ojú Ọlọ́run là ń wò fún ìgbàlà. A ó gba àwọn tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run là ní “ọjọ́ ńlá àti ọjọ́ amúnikún-fún-ẹ̀rù ti Jèhófà.” (Jóẹ́lì 2:30-32) Àwa tí yóò para pọ̀ jẹ́ “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí yóò là á já sínú ayé tuntun Ọlọ́run, tí yóò sì jẹ́ olóòótọ́ nígbà àdánwò ìkẹyìn ni ‘òun yóò fi ọjọ́ gígùn tẹ́ lọ́rùn’—ìyẹn, ìyè àìnípẹ̀kun. Pẹ̀lúpẹ̀lù, òun yóò jí ọ̀kẹ́ àìmọye dìde. (Ìṣípayá 7:9; 20:7-15) Àní sẹ́, Jèhófà yóò ní inú dídùn kíkọyọyọ sí ‘jíjẹ́ kí a rí ìgbàlà’ nípasẹ̀ Jésù Kristi. (Sáàmù 3:8) Pẹ̀lú ìrètí gíga lọ́lá wọ̀nyí níwájú wa, ẹ jẹ́ ká máa wojú Ọlọ́run fún ìrànlọ́wọ́ bá a ti ń ka àwọn ọjọ́ wa láti mú ògo bá a. Ní ọ̀rọ̀ àti ìṣe, ǹjẹ́ ká máa fi hàn pé Jèhófà ni ibi ìsádi wa.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn tó kọ Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì kò ṣàlàyé Sáàmù kọkànléláàádọ́rùn-ún lọ síbi àsọtẹ́lẹ̀ nípa Mèsáyà. Dájúdájú, Jèhófà jẹ́ ibi ìsádi àti odi agbára fún ọkùnrin náà Jésù Kristi, gan-an gẹ́gẹ́ bí Ó ṣe jẹ́ fún àwọn ẹni àmì òróró ọmọlẹ́yìn Jésù àti àwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ní “àkókò òpin” yìí.—Dáníẹ́lì 12:4.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí ni “ibi ìkọ̀kọ̀ Ẹni Gíga Jù Lọ”?
• Kí nìdí tá ò fi bẹ̀rù?
• Báwo ló ṣe jẹ́ pé ‘àjálù kankan kì yóò dé bá wa’?
• Kí nìdí tá a fi lè sọ pé Jèhófà ni orísun ìgbàlà wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]
Ǹjẹ́ o mọ bí òótọ́ Jèhófà ṣe jẹ́ apata ńlá fún wa?
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Jèhófà ń ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn lójú àtakò tó ń dé ní ìjafùú àti ti ojúkorojú
[Credit Line]
Ṣèbé: A. N. Jagannatha Rao, Trustee, Madras Snake Park Trust