Sáàmù
Orin Ásáfù.+
2 Láti Síónì, tí ó ní ẹwà pípé,+ ni Ọlọ́run ti tàn jáde.
3 Ọlọ́run wa yóò wá, kò sì ní dákẹ́.+
6 Àwọn ọ̀run ń kéde òdodo rẹ̀,
Nítorí Ọlọ́run fúnra rẹ̀ jẹ́ Onídàájọ́.+ (Sélà)
7 “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin èèyàn mi, mo fẹ́ sọ̀rọ̀;
Ìwọ Ísírẹ́lì, màá ta kò ọ́.+
Èmi ni Ọlọ́run, àní Ọlọ́run rẹ.+
8 Mi ò bá ọ wí nítorí àwọn ẹbọ rẹ
Tàbí nítorí àwọn odindi ẹbọ sísun rẹ tó wà níwájú mi nígbà gbogbo.+
10 Nítorí pé tèmi ni gbogbo ẹran inú igbó,+
Títí kan àwọn ẹranko tó wà lórí gbogbo òkè.
11 Mo mọ gbogbo ẹyẹ tó wà lórí àwọn òkè;+
Àìlóǹkà àwọn ẹran tó wà nínú pápá jẹ́ tèmi.
12 Ká ní ebi ń pa mí, mi ò ní sọ fún ọ,
Nítorí ilẹ̀ eléso àti gbogbo ohun tó wà nínú rẹ̀ jẹ́ tèmi.+
Màá gbà ọ́ sílẹ̀, wàá sì máa yìn mí lógo.”+
16 Àmọ́ Ọlọ́run yóò sọ fún ẹni burúkú pé:
19 Ò ń fi ẹnu rẹ sọ ohun búburú kiri,
Ẹ̀tàn sì wà lórí ahọ́n rẹ.+
21 Nígbà tí o ṣe àwọn nǹkan yìí, mi ò sọ̀rọ̀,
Torí náà, o rò pé màá dà bíi tìẹ.
Àmọ́ ní báyìí, màá bá ọ wí,
Màá sì pè ọ́ lẹ́jọ́.+
22 Ẹ jọ̀wọ́, ẹ rò ó wò ná, ẹ̀yin tí ẹ gbàgbé Ọlọ́run,+
Kí n má bàa fà yín ya pẹ́rẹpẹ̀rẹ láìsí ẹni tó máa gbà yín sílẹ̀.