Jóṣúà
14 Èyí ni ogún tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà ní ilẹ̀ Kénáánì, èyí tí àlùfáà Élíásárì àti Jóṣúà ọmọ Núnì àtàwọn olórí agbo ilé àwọn ẹ̀yà àwọn ọmọ Ísírẹ́lì fún wọn pé kí wọ́n jogún.+ 2 Kèké ni wọ́n fi pín ogún+ fún ẹ̀yà mẹ́sàn-án àtààbọ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ nípasẹ̀ Mósè.+ 3 Mósè ti pín ogún fún ẹ̀yà méjì àtààbọ̀ yòókù ní òdìkejì* Jọ́dánì,+ àmọ́ kò pín ogún kankan fún àwọn ọmọ Léfì láàárín wọn.+ 4 Ẹ̀yà méjì ni wọ́n ka àwọn àtọmọdọ́mọ Jósẹ́fù sí,+ ìyẹn Mánásè àti Éfúrémù;+ wọn ò pín lára ilẹ̀ náà fún àwọn ọmọ Léfì, àfi àwọn ìlú+ tí wọ́n á máa gbé àti ibi tí àwọn ẹran ọ̀sìn wọn á ti máa jẹko, tí ohun ìní wọn sì máa wà.+ 5 Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wá pín ilẹ̀ náà, bí Jèhófà ṣe pa á láṣẹ fún Mósè gẹ́lẹ́.
6 Àwọn ọkùnrin Júdà wá bá Jóṣúà ní Gílígálì,+ Kélẹ́bù+ ọmọ Jéfúnè, ọmọ Kénásì sì sọ fún un pé: “O mọ ohun tí Jèhófà sọ+ dáadáa, ohun tó sọ fún Mósè èèyàn Ọlọ́run tòótọ́+ nípa èmi àti ìwọ ní Kadeṣi-báníà.+ 7 Ẹni ogójì (40) ọdún ni mí nígbà tí Mósè ìránṣẹ́ Jèhófà rán mi láti Kadeṣi-báníà lọ ṣe amí ilẹ̀ náà,+ bọ́rọ̀ sì ṣe rí gẹ́lẹ́* ni mo sọ ọ́ nígbà tí mo dé.+ 8 Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn arákùnrin mi tí a jọ lọ mú kí ọkàn àwọn èèyàn wa domi,* mo fi gbogbo ọkàn mi tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.*+ 9 Mósè búra ní ọjọ́ yẹn pé: ‘Ilẹ̀ tí o fi ẹsẹ̀ rẹ tẹ̀ máa di ogún ìwọ àtàwọn ọmọ rẹ títí lọ, torí pé o ti fi gbogbo ọkàn rẹ tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run mi.’+ 10 Bí Jèhófà ṣe ṣèlérí,+ ó dá ẹ̀mí mi sí+ jálẹ̀ ọdún márùndínláàádọ́ta (45) yìí, látìgbà tí Jèhófà ti ṣe ìlérí yìí fún Mósè, nígbà tí Ísírẹ́lì rìn nínú aginjù;+ èmi náà rèé lónìí, lẹ́ni ọdún márùndínláàádọ́rùn-ún (85). 11 Mo ṣì lágbára lónìí bíi ti ọjọ́ tí Mósè rán mi jáde. Agbára mi ò dín kù sí tìgbà yẹn, mo lè jagun, mo sì lè ṣe àwọn nǹkan míì. 12 Torí náà, fún mi ní agbègbè olókè yìí, tí Jèhófà ṣèlérí ní ọjọ́ yẹn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé o gbọ́ lọ́jọ́ yẹn pé àwọn Ánákímù+ wà níbẹ̀, wọ́n sì ní àwọn ìlú olódi tó tóbi,+ ó dájú pé* Jèhófà máa wà pẹ̀lú mi,+ màá sì lé wọn kúrò,* bí Jèhófà ṣe ṣèlérí.”+
13 Jóṣúà wá súre fún un, ó sì fún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ní Hébúrónì pé kó jẹ́ ogún rẹ̀.+ 14 Ìdí nìyẹn tí Hébúrónì fi jẹ́ ogún Kélẹ́bù ọmọ Jéfúnè ọmọ Kénásì títí dòní, torí ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ tẹ̀ lé Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.+ 15 Kiriati-ábà+ ni Hébúrónì ń jẹ́ tẹ́lẹ̀ (Ábà jẹ́ ẹni ńlá láàárín àwọn Ánákímù). Ogun sì dáwọ́ dúró ní ilẹ̀ náà.+