Ẹ́sírà
4 Nígbà tí àwọn ọ̀tá Júdà àti Bẹ́ńjámínì + gbọ́ pé àwọn tó dé láti ìgbèkùn+ ń kọ́ tẹ́ńpìlì kan fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, 2 ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n lọ bá Serubábélì àti àwọn olórí agbo ilé, wọ́n sì sọ fún wọn pé: “Ẹ jẹ́ ká jọ kọ́ ilé yìí; nítorí Ọlọ́run yín làwa náà ń sìn,*+ òun la sì ń rúbọ sí láti ìgbà ayé Esari-hádónì+ ọba Ásíríà tó kó wa wá síbí.”+ 3 Àmọ́, Serubábélì àti Jéṣúà pẹ̀lú ìyókù àwọn olórí agbo ilé ní Ísírẹ́lì sọ fún wọn pé: “Kò sí ohun tó kàn yín nínú kíkọ́ ilé fún Ọlọ́run wa,+ àwa nìkan ló máa kọ́ ọ fún Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì, gẹ́gẹ́ bí Ọba Kírúsì tó jẹ́ ọba Páṣíà ṣe pàṣẹ fún wa.”+
4 Ni àwọn èèyàn ilẹ̀ náà bá ń kó ìrẹ̀wẹ̀sì bá àwọn èèyàn Júdà,* wọ́n sì ń mú kí ọkàn wọn domi, kí wọ́n má lè kọ́ ilé náà.+ 5 Wọ́n tìtorí wọn háyà àwọn agbani-nímọ̀ràn láti mú kí ìmọ̀ràn wọn já sófo+ ní gbogbo ọjọ́ Kírúsì ọba Páṣíà títí di ìgbà ìjọba Dáríúsì+ ọba Páṣíà. 6 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ìjọba Ahasuérúsì, wọ́n kọ̀wé ẹ̀sùn mọ́ àwọn tó ń gbé Júdà àti Jerúsálẹ́mù. 7 Nígbà ayé Atasásítà ọba Páṣíà, Bíṣílámù, Mítírédátì, Tábéélì àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ yòókù kọ̀wé sí Ọba Atasásítà; wọ́n túmọ̀ lẹ́tà náà sí èdè Árámáíkì,+ ọ̀nà ìkọ̀wé èdè Árámáíkì ni wọ́n sì fi kọ ọ́.*
8 * Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin kọ lẹ́tà kan mọ́ Jerúsálẹ́mù, wọ́n sì fi ránṣẹ́ sí Ọba Atasásítà, lẹ́tà náà kà pé: 9 (Ó wá látọ̀dọ̀ Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù, àwọn adájọ́ àti àwọn gómìnà kéékèèké, àwọn akọ̀wé, àwọn èèyàn Érékì,+ àwọn ará Babilóníà, àwọn tó ń gbé ní Súsà,+ ìyẹn àwọn ọmọ Élámù+ 10 àti àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí Ásénápárì ńlá àti ọlọ́lá kó lọ sí ìgbèkùn, tó sì ní kí wọ́n máa gbé ní àwọn ìlú Samáríà+ pẹ̀lú àwọn yòókù tó ń gbé ní agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò.* Ní báyìí, 11 ẹ̀dà lẹ́tà tí wọ́n fi ránṣẹ́ sí i nìyí.)
“Sí Ọba Atasásítà, látọ̀dọ̀ àwa ìránṣẹ́ rẹ, àwa tí a wà ní agbègbè Ìkọjá Odò: Ní báyìí, 12 a fẹ́ kí ọba mọ̀ pé àwọn Júù tó wá látọ̀dọ̀ rẹ sí ọ̀dọ̀ wa níbí ti dé sí Jerúsálẹ́mù. Wọ́n ń kọ́ ìlú ọ̀tẹ̀ àti ìlú burúkú, wọ́n ti ń mọ àwọn ògiri rẹ̀,+ wọ́n sì ti ń tún àwọn ìpìlẹ̀ rẹ̀ ṣe. 13 Kí ọba mọ̀ pé tí wọ́n bá tún ìlú náà kọ́, tí wọ́n sì parí àwọn ògiri rẹ̀, wọn ò ní san owó orí tàbí ìṣákọ́lẹ̀,*+ bẹ́ẹ̀ ni wọn ò ní san owó ibodè, èyí sì máa jẹ́ kí owó tó ń wọlé sí àpò ọba* dín kù. 14 Torí pé ààfin ni owó wa ti ń wá,* kò ní dáa ká rí ohun tó máa dènà àǹfààní ọba, ká má sì sọ, ìdí nìyẹn tí a fi kọ̀wé ránṣẹ́, kí ọba lè mọ̀, 15 kí o lè wádìí nínú àkọsílẹ̀ àwọn baba ńlá rẹ.+ Wàá rí i nínú àkọsílẹ̀ pé ìlú yẹn jẹ́ ìlú ọ̀tẹ̀, ó máa ń pa àwọn ọba àti àwọn ìpínlẹ̀* lára, ó sì ti pẹ́ tí àwọn tó wà nínú rẹ̀ ti máa ń dìtẹ̀. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi pa ìlú náà run.+ 16 A fẹ́ kí ọba mọ̀ pé, tí wọ́n bá tún ìlú yìí kọ́, tí wọ́n sì parí àwọn ògiri rẹ̀, o ò ní láṣẹ lórí* agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò.”+
17 Ọba wá ránṣẹ́ sí Réhúmù olórí àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn yòókù tó ń gbé ní Samáríà àti àwọn ibi yòókù ní agbègbè Ìkọjá Odò pé:
“Mo kí yín o! 18 Wọ́n ti fara balẹ̀ ka ìwé tí ẹ fi ránṣẹ́ sí wa* níwájú mi. 19 Mo ti pàṣẹ pé kí wọ́n wádìí, a sì rí i pé ó ti pẹ́ tí ìlú náà ti ń dìde sí àwọn ọba àti pé àwọn tó ń gbé inú rẹ̀ máa ń ṣọ̀tẹ̀, wọ́n sì máa ń dìtẹ̀.+ 20 Àwọn ọba alágbára ti jẹ ní Jerúsálẹ́mù, wọ́n ṣàkóso gbogbo agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò, àwọn èèyàn sì ń san owó orí, ìṣákọ́lẹ̀* àti owó ibodè fún wọn. 21 Ní báyìí, ẹ pàṣẹ fún àwọn ọkùnrin yìí pé kí wọ́n dáwọ́ iṣẹ́ dúró, kí wọ́n má bàa tún ìlú náà kọ́ títí màá fi pàṣẹ. 22 Ẹ rí i dájú pé ẹ kò fi ọ̀rọ̀ yìí falẹ̀, kí ìpalára tó ń fà fún ọba lè dáwọ́ dúró.”+
23 Lẹ́yìn tí wọ́n ka ẹ̀dà ìwé àṣẹ Ọba Atasásítà níwájú Réhúmù àti Ṣímúṣáì akọ̀wé òfin pẹ̀lú àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, wọ́n lọ sí Jerúsálẹ́mù lọ́dọ̀ àwọn Júù, wọ́n sì fipá dá wọn dúró. 24 Ìgbà náà ni iṣẹ́ ilé Ọlọ́run, èyí tó wà ní Jerúsálẹ́mù, dáwọ́ dúró; ó sì wà bẹ́ẹ̀ títí di ọdún kejì ìjọba Dáríúsì ọba Páṣíà.+