Sáàmù Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Másíkílì.* Ti Dáfídì, nígbà tí àwọn ọmọ Sífù wá sọ́dọ̀ Sọ́ọ̀lù, tí wọ́n sì sọ fún un pé: “Àárín wa ni Dáfídì fara pa mọ́ sí.”+ 54 Ọlọ́run, fi orúkọ rẹ gbà mí,+Sì fi agbára rẹ gbèjà mi.*+ 2 Ọlọ́run, gbọ́ àdúrà mi;+Fetí sí ọ̀rọ̀ ẹnu mi. 3 Nítorí àwọn àjèjì dìde sí mi,Àwọn ìkà ẹ̀dá sì ń wá ẹ̀mí* mi.+ Wọn ò ka Ọlọ́run sí.*+ (Sélà) 4 Wò ó! Ọlọ́run ni olùrànlọ́wọ́ mi;+Jèhófà wà pẹ̀lú àwọn tó ń tì mí* lẹ́yìn. 5 Yóò san ìwà ìkà àwọn ọ̀tá mi pa dà fún wọn;+Pa wọ́n run* nínú òtítọ́ rẹ.+ 6 Màá rúbọ sí ọ+ tinútinú. Màá yin orúkọ rẹ, Jèhófà, nítorí ó dára.+ 7 Nítorí o gbà mí nínú gbogbo wàhálà,+Màá sì máa wo ìṣubú àwọn ọ̀tá mi.+