Sáàmù
א [Áléfì]
Aláyọ̀ ni ẹni tó bẹ̀rù Jèhófà,+
ב [Bétì]
Tó sì fẹ́ràn àwọn àṣẹ rẹ̀ gan-an.+
ג [Gímélì]
2 Àtọmọdọ́mọ rẹ̀ yóò di alágbára ní ayé,
ד [Dálétì]
Ìran àwọn adúróṣinṣin yóò sì rí ìbùkún.+
ה [Híì]
3 Ọlá àti ọrọ̀ wà nínú ilé rẹ̀,
ו [Wọ́ọ̀]
Òdodo rẹ̀ sì wà títí láé.
ז [Sáyìn]
4 Nínú òkùnkùn, ó ń tàn yanran bí ìmọ́lẹ̀ sí àwọn adúróṣinṣin.+
ח [Hétì]
Ó jẹ́ agbatẹnirò* àti aláàánú+ àti olódodo.
ט [Tétì]
5 Nǹkan máa ń lọ dáadáa fún ẹni tó bá ń yáni ní nǹkan tọkàntọkàn.*+
י [Yódì]
Ìdájọ́ òdodo ló fi ń ṣe nǹkan.
כ [Káfì]
ל [Lámédì]
A ó máa rántí àwọn olódodo títí láé.+
מ [Mémì]
נ [Núnì]
Ọkàn rẹ̀ dúró ṣinṣin, ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.+
ס [Sámékì]
Níkẹyìn, yóò rí ìṣubú àwọn ọ̀tá rẹ̀.+
פ [Péè]
9 Ó ti pín nǹkan fún àwọn èèyàn káàkiri;* ó ti fún àwọn aláìní.+
צ [Sádì]
Òdodo rẹ̀ wà títí láé.+
ק [Kófì]
A ó gbé agbára* rẹ̀ ga nínú ògo.
ר [Réṣì]
10 Ẹni burúkú á rí i, inú á sì bí i.
ש [Ṣínì]
Á wa eyín pọ̀, á sì pa rẹ́.
ת [Tọ́ọ̀]
Ìfẹ́ ọkàn àwọn ẹni burúkú yóò ṣègbé.+