Ìwé Kìíní sí Àwọn Ará Kọ́ríńtì
14 Ẹ máa lépa ìfẹ́, síbẹ̀ ẹ máa wá* àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí, àmọ́ ohun tó sàn jù ni pé kí ẹ máa sọ tẹ́lẹ̀.+ 2 Nítorí kì í ṣe èèyàn ni ẹni tó ń fi èdè fọ̀* ń bá sọ̀rọ̀, Ọlọ́run ni, torí kò sẹ́ni tó ń fetí sílẹ̀,+ bó tilẹ̀ ń sọ àwọn àṣírí mímọ́ + nípasẹ̀ ẹ̀mí. 3 Síbẹ̀, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ń gbéni ró, ó ń fúnni ní ìṣírí, ó sì ń tuni nínú nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. 4 Ẹni tó ń fi èdè fọ̀* ń gbé ara rẹ̀ ró, àmọ́ ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ ń gbé ìjọ ró. 5 Ní báyìí, ó wù mí kí gbogbo yín máa fi èdè fọ̀,*+ àmọ́ kí ẹ máa sọ tẹ́lẹ̀ ló wù mí jù.+ Ní tòótọ́, ẹni tó ń sọ tẹ́lẹ̀ tóbi ju ẹni tó ń fi èdè fọ̀, àfi tó bá ń túmọ̀* rẹ̀, kó lè máa gbé ìjọ ró. 6 Àmọ́ lọ́tẹ̀ yìí, ẹ̀yin ará, tí mo bá wá sọ́dọ̀ yín tí mo sì ń fi èdè fọ̀,* àǹfààní wo ni màá ṣe yín láìjẹ́ pé mo bá yín sọ̀rọ̀ bóyá pẹ̀lú ìfihàn+ tàbí pẹ̀lú ìmọ̀+ tàbí pẹ̀lú àsọtẹ́lẹ̀ tàbí pẹ̀lú ẹ̀kọ́?
7 Bẹ́ẹ̀ ló ṣe rí pẹ̀lú àwọn ohun aláìlẹ́mìí tó ń mú ìró jáde, ì báà jẹ́ fèrè tàbí háàpù. Tí àyè ò bá sí láàárín ìró wọn, báwo la ṣe máa mọ ohun tí wọ́n ń fi fèrè tàbí háàpù sọ? 8 Nítorí tí kàkàkí kò bá dún ketekete, ta ló máa gbára dì fún ogun? 9 Lọ́nà kan náà, láìjẹ́ pé ẹ fi ahọ́n yín sọ ọ̀rọ̀ tó rọrùn láti lóye, báwo ni ẹnì kan ṣe máa mọ ohun tí ẹ̀ ń sọ? Ní tòótọ́, ẹ̀ẹ́ kàn máa sọ̀rọ̀ sínú afẹ́fẹ́ ni. 10 Oríṣiríṣi ọ̀rọ̀ ló wà nínú ayé, síbẹ̀, kò sí èyí tí kò ní ìtúmọ̀. 11 Nítorí tí ọ̀rọ̀ náà ò bá yé mi, màá di àjèjì sí ẹni tó ń sọ̀rọ̀, ẹni tó ń sọ̀rọ̀ náà á sì di àjèjì sí mi. 12 Bó ṣe rí fún ẹ̀yin náà nìyẹn, torí pé ẹ̀ ń fẹ́ ẹ̀bùn ẹ̀mí lójú méjèèjì, ẹ máa wá ọ̀nà láti ní ẹ̀bùn púpọ̀ tó máa gbé ìjọ ró.+
13 Nítorí náà, kí ẹni tó ń fi èdè fọ̀* máa gbàdúrà kí ó lè ṣe ìtúmọ̀.*+ 14 Torí tí mo bá ń fi èdè* àjèjì gbàdúrà, ẹ̀bùn ẹ̀mí tí mo ní ló ń gbàdúrà, àmọ́ èrò inú mi ò ṣiṣẹ́. 15 Kí wá ni ṣíṣe? Màá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí gbàdúrà, àmọ́ màá tún fi èrò inú mi gbàdúrà. Màá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí kọrin ìyìn, àmọ́ màá tún fi èrò inú mi kọrin ìyìn. 16 Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, tí o bá fi ẹ̀bùn ẹ̀mí mú ìyìn wá, báwo ni ẹni tí kò lóye tó wà láàárín yín ṣe máa ṣe “Àmín” sí ìdúpẹ́ rẹ, nígbà tí kò mọ ohun tí ò ń sọ? 17 Lóòótọ́, ò ń dúpẹ́ lọ́nà tó dáa, àmọ́ kò gbé ẹnì kejì rẹ ró. 18 Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé mò ń sọ ọ̀pọ̀ èdè* ju gbogbo yín lọ. 19 Àmọ́ nínú ìjọ, ó yá mi lára kí n fi èrò inú* mi sọ ọ̀rọ̀ márùn-ún, kí n lè kọ́* àwọn míì, ju pé kí n sọ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá ọ̀rọ̀ ní èdè* àjèjì.+
20 Ẹ̀yin ará, ẹ má ṣe di ọmọ kékeré nínú òye,+ àmọ́ ẹ di ọmọ kékeré ní ti ìwà burúkú;+ ẹ sì dàgbà di géńdé nínú òye.+ 21 Ó wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin pé: “‘Màá bá àwọn èèyàn yìí sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ ahọ́n àwọn àjèjì àti nípasẹ̀ ètè àwọn àjèjì, síbẹ̀ náà, wọn ò ní fetí sí mi,’ ni Jèhófà* wí.”+ 22 Nítorí náà, àwọn ahọ́n àjèjì kì í ṣe àmì fún àwọn onígbàgbọ́, àwọn aláìgbàgbọ́ ló wà fún,+ nígbà tó jẹ́ pé àsọtẹ́lẹ̀ kò wà fún àwọn aláìgbàgbọ́, àwọn onígbàgbọ́ ló wà fún. 23 Nítorí náà, tí gbogbo ìjọ bá kóra jọ síbì kan, tí gbogbo wọn sì ń fi èdè fọ̀,* àmọ́ tí àwọn tí kò lóye tàbí àwọn aláìgbàgbọ́ wọlé wá, ṣé wọn ò ní sọ pé orí yín ti dà rú? 24 Àmọ́ tí gbogbo yín bá ń sọ tẹ́lẹ̀, tí aláìgbàgbọ́ tàbí ẹni tí kò mọ méjì sì wọlé wá, gbogbo ọ̀rọ̀ yín á bá a wí, á sì mú kó yẹ ara rẹ̀ wò fínnífínní. 25 Àwọn àṣírí tó wà lọ́kàn rẹ̀ á wá hàn síta, débi pé á dojú bolẹ̀, á sì jọ́sìn Ọlọ́run, á sọ pé: “Ọlọ́run wà láàárín yín lóòótọ́.”+
26 Kí wá ni ṣíṣe, ẹ̀yin ará? Nígbà tí ẹ bá kóra jọ, ẹnì kan ní sáàmù, ẹlòmíì ní ẹ̀kọ́, ẹlòmíì ní ìfihàn, ẹlòmíì ní èdè* àjèjì, ẹlòmíì sì ní ìtúmọ̀.+ Kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ láti gbéni ró. 27 Tí ẹnì kan bá ń fi èdè fọ̀,* kí ó fi mọ sí méjì tàbí ó pọ̀ jù, mẹ́ta, kí wọ́n máa sọ̀rọ̀ ní ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn, kí ẹnì kan sì máa ṣe ìtúmọ̀.*+ 28 Àmọ́ tí kò bá sí olùtúmọ̀,* kí ó dákẹ́ nínú ìjọ, kí ó sì máa bá ara rẹ̀ àti Ọlọ́run sọ̀rọ̀. 29 Kí wòlíì+ méjì tàbí mẹ́ta sọ̀rọ̀, kí àwọn tó kù sì fi òye mọ ìtúmọ̀. 30 Àmọ́ tí ẹlòmíì bá rí ìfihàn nígbà tó wà ní ìjókòó, kí ẹni àkọ́kọ́ tó ń sọ̀rọ̀ dákẹ́. 31 Torí náà, gbogbo àwọn tó ń sọ tẹ́lẹ̀ á máa sọ tẹ́lẹ̀, ọ̀kan tẹ̀ lé òmíràn, kí gbogbo yín lè kẹ́kọ̀ọ́, kí ẹ sì gba ìṣírí.+ 32 Kí àwọn wòlíì máa kápá ẹ̀bùn ẹ̀mí tí àwọn wòlíì ní. 33 Nítorí Ọlọ́run kì í ṣe Ọlọ́run rúdurùdu, bí kò ṣe ti àlàáfíà.+
Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú gbogbo ìjọ àwọn ẹni mímọ́, 34 kí àwọn obìnrin máa dákẹ́ nínú ìjọ, nítorí a kò gbà wọ́n láyè láti sọ̀rọ̀.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí wọ́n wà ní ìtẹríba,+ gẹ́gẹ́ bí Òfin ṣe sọ. 35 Tí wọ́n bá fẹ́ mọ nǹkan kan, kí wọ́n béèrè lọ́wọ́ ọkọ wọn nílé, nítorí ohun ìtìjú ni kí obìnrin máa sọ̀rọ̀ nínú ìjọ.
36 Ṣé ọ̀dọ̀ yín ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wá ni àbí ọ̀dọ̀ yín nìkan ni ó dé?
37 Tí ẹnikẹ́ni bá rò pé òun jẹ́ wòlíì tàbí pé òun ní ẹ̀bùn ẹ̀mí, kí ó gbà pé àwọn ohun tí mò ń kọ sí yín jẹ́ àṣẹ Olúwa. 38 Àmọ́ tí ẹnì kan ò bá kà á sí, a ò ní ka òun náà sí.* 39 Nítorí náà, ẹ̀yin ará mi, ẹ máa wá ọ̀nà láti sọ tẹ́lẹ̀,+ síbẹ̀ náà, ẹ má ka fífi èdè fọ̀*+ léèwọ̀. 40 Àmọ́ ẹ jẹ́ kí ohun gbogbo máa ṣẹlẹ̀ lọ́nà tó bójú mu àti létòlétò.*+