Ìfihàn Èyí Tí Jòhánù Rí
9 Áńgẹ́lì karùn-ún fun kàkàkí rẹ̀.+ Mo sì rí ìràwọ̀ kan tó ti já bọ́ láti ọ̀run sí ayé, a sì fún un ní kọ́kọ́rọ́ àbáwọlé* ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ 2 Ó ṣí àbáwọlé* ọ̀gbun àìnísàlẹ̀ náà, èéfín sì jáde látinú ọ̀gbun náà bí èéfín iná ìléru ńlá, èéfín tó ń jáde látinú ọ̀gbun náà sì mú kí oòrùn ṣókùnkùn+ bẹ́ẹ̀ náà sì ni afẹ́fẹ́. 3 Àwọn eéṣú wá jáde sí ayé látinú èéfín náà,+ a sì fún wọn ní àṣẹ, àṣẹ kan náà tí àwọn àkekèé tó wà ní ayé ní. 4 A sọ fún wọn pé kí wọ́n má pa koríko ayé lára tàbí ewéko tútù tàbí igi èyíkéyìí, àwọn èèyàn tí kò ní èdìdì Ọlọ́run ní iwájú orí wọn nìkan ni kí wọ́n pa lára.+
5 A ò gbà kí àwọn eéṣú náà pa wọ́n, àmọ́ kí wọ́n dá wọn lóró fún oṣù márùn-ún, oró wọn sì dà bí ìgbà tí àkekèé+ bá ta èèyàn. 6 Ní àwọn ọjọ́ yẹn, àwọn èèyàn máa wá ikú, àmọ́ wọn ò ní rí i rárá, wọ́n máa fẹ́ kú, ṣùgbọ́n ikú máa sá fún wọn.
7 Àwọn eéṣú náà rí bí àwọn ẹṣin tó ṣe tán láti jagun;+ ohun tó dà bí adé tí wọ́n fi wúrà ṣe wà ní orí wọn, ojú wọn sì dà bíi ti èèyàn, 8 àmọ́ wọ́n ní irun bíi ti obìnrin. Eyín wọn sì dà bíi ti kìnnìún,+ 9 wọ́n sì ní ìgbàyà tó dà bí èyí tí wọ́n fi irin ṣe. Ìró ìyẹ́ wọn sì dà bí ìró àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tó ń sáré lọ sójú ogun.+ 10 Bákan náà, wọ́n ní ìrù tó lè tani bíi ti àkekèé, àṣẹ sì wà ní ìrù wọn láti ṣe àwọn èèyàn náà léṣe fún oṣù márùn-ún.+ 11 Wọ́n ní ẹni tó ń jọba lé wọn lórí, áńgẹ́lì ọ̀gbun àìnísàlẹ̀.+ Orúkọ rẹ̀ lédè Hébérù ni Ábádónì,* àmọ́ lédè Gíríìkì orúkọ rẹ̀ ni Ápólíónì.*
12 Ìyọnu àkọ́kọ́ ti kọjá. Wò ó! Ìyọnu méjì míì+ ń bọ̀ lẹ́yìn àwọn nǹkan yìí.
13 Áńgẹ́lì kẹfà+ fun kàkàkí rẹ̀.+ Mo sì gbọ́ ohùn kan, ó wá látinú àwọn ìwo tó wà lórí pẹpẹ, èyí tí wọ́n fi wúrà ṣe+ tó wà níwájú Ọlọ́run, 14 ó sọ fún áńgẹ́lì kẹfà tó mú kàkàkí dání pé: “Tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin tí wọ́n dè síbi odò ńlá Yúfírétì+ sílẹ̀.” 15 A sì tú àwọn áńgẹ́lì mẹ́rin náà sílẹ̀, àwọn tí a ti múra sílẹ̀ fún wákàtí àti ọjọ́ àti oṣù àti ọdún náà, kí wọ́n lè pa ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà.
16 Iye àwọn ọmọ ogun tó gẹṣin jẹ́ ẹgbàárùn-ún méjì lọ́nà ẹgbàárùn-ún;* mo gbọ́ iye wọn. 17 Báyìí sì ni àwọn ẹṣin tí mo rí nínú ìran náà àti àwọn tó jókòó sórí wọn ṣe rí: Wọ́n ní ìgbàyà tó pupa bí iná àti búlúù bíi háyásíǹtì àti yẹ́lò bí imí ọjọ́, orí àwọn ẹṣin náà sì dà bí orí kìnnìún,+ iná, èéfín àti imí ọjọ́ sì jáde láti ẹnu wọn. 18 Ìyọnu mẹ́ta yìí, ìyẹn iná, èéfín àti imí ọjọ́ tó jáde lẹ́nu wọn, pa ìdá mẹ́ta àwọn èèyàn náà. 19 Torí àṣẹ àwọn ẹṣin náà wà ní ẹnu wọn àti ìrù wọn, nítorí ìrù wọn dà bí ejò, wọ́n sì ní orí, àwọn nǹkan yìí ni wọ́n fi ń ṣe àwọn èèyàn léṣe.
20 Àmọ́ àwọn èèyàn yòókù tí àwọn ìyọnu yìí kò pa kò ronú pìwà dà iṣẹ́ ọwọ́ wọn; wọn ò ṣíwọ́ láti máa jọ́sìn àwọn ẹ̀mí èṣù àti àwọn òrìṣà tí wọ́n fi wúrà àti fàdákà àti bàbà àti òkúta àti igi ṣe, tí kò lè ríran, tí kò lè gbọ́ràn, tí kò sì lè rìn.+ 21 Wọn ò sì ronú pìwà dà nínú ìpànìyàn, ìbẹ́mìílò, ìṣekúṣe* tàbí olè jíjà wọn.