Ìsíkíẹ́lì
47 Lẹ́yìn náà, ó mú mi pa dà wá sí ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì náà,+ mo sì rí omi tó ń ṣàn lọ sí ìlà oòrùn láti abẹ́ ẹnu ọ̀nà tẹ́ńpìlì náà,+ torí iwájú tẹ́ńpìlì náà dojú kọ ìlà oòrùn. Omi náà ń ṣàn wálẹ̀ láti abẹ́ tẹ́ńpìlì náà ní apá ọ̀tún, ní gúúsù pẹpẹ.
2 Ó wá mú mi gba ẹnubodè àríwá jáde,+ ó mú mi lọ síta, ó sì mú mi yí ká ẹnubodè ìta tó dojú kọ ìlà oòrùn,+ mo sì rí i tí omi ń sun láti apá ọ̀tún.
3 Nígbà tí ọkùnrin náà jáde lọ sí apá ìlà oòrùn tó sì mú okùn ìdíwọ̀n dání,+ ó wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́,* ó sì mú mi gba inú omi náà; omi náà dé kókósẹ̀.
4 Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, ó sì mú mi gba inú omi náà. Ó dé orúnkún.
Ó tún wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, ó mú mi gba inú rẹ̀, omi náà sì dé ìbàdí.
5 Nígbà tó tún wọn ẹgbẹ̀rún (1,000) ìgbọ̀nwọ́, mi ò lè fi ẹsẹ̀ rin omi náà kọjá torí ó kún, ó sì jìn débi pé èèyàn ní láti lúwẹ̀ẹ́ kọjá ni, àní alagbalúgbú omi téèyàn ò lè fi ẹsẹ̀ rìn kọjá ni.
6 Ó bi mí pé: “Ṣé o rí èyí, ọmọ èèyàn?”
Ó wá mú mi rìn pa dà sí etí odò náà. 7 Nígbà tí mo pa dà, mo rí i pé igi pọ̀ gan-an ní ẹ̀gbẹ́ méjèèjì etí odò náà.+ 8 Ó wá sọ fún mi pé: “Omi yìí ń ṣàn lọ sí agbègbè ìlà oòrùn títí lọ dé Árábà,*+ ó sì ń ṣàn wọnú òkun. Tó bá wọnú òkun,+ yóò wo omi ibẹ̀ sàn. 9 Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀dá alààyè* yóò máa wà láàyè níbikíbi tí omi* náà bá ṣàn dé. Ẹja máa pọ̀ gan-an níbẹ̀ torí omi yìí máa ṣàn débẹ̀. Yóò wo omi òkun náà sàn, gbogbo ohun tó bá sì wà níbi tí omi náà ṣàn dé yóò máa wà láàyè.
10 “Àwọn apẹja yóò dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ láti Ẹ́ń-gédì+ títí lọ dé Eni-égíláímù, níbi tí wọ́n ń sá àwọ̀n sí. Oríṣiríṣi ẹja yóò pọ̀ gan-an níbẹ̀, bí àwọn ẹja inú Òkun Ńlá.*+
11 “Yóò ní irà àti àbàtà, wọn kò sì ní rí ìwòsàn. Wọ́n á di ilẹ̀ iyọ̀.+
12 “Onírúurú igi tó ń so èso fún jíjẹ yóò hù lẹ́gbẹ̀ẹ́ méjèèjì odò náà. Ewé wọn ò ní rọ; èso wọn ò sì ní tán. Oṣooṣù ni wọ́n á máa so èso tuntun, torí láti ibi mímọ́ ni omi ti ń ṣàn dé ọ̀dọ̀ wọn.+ Èso wọn yóò jẹ́ oúnjẹ, ewé wọn á sì wà fún ìwòsàn.”+
13 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ilẹ̀ tí ẹ máa yàn bí ogún fún ẹ̀yà Ísírẹ́lì méjìlá (12) nìyí, Jósẹ́fù yóò sì ní ìpín méjì.+ 14 Ẹ máa jogún rẹ̀, ìpín kálukú yóò sì dọ́gba.* Mo búra pé màá fún àwọn baba ńlá yín ní ilẹ̀ yìí,+ mo sì ti pín in fún yín* láti jẹ́ ogún yín ní báyìí.
15 “Ààlà ilẹ̀ náà ní apá àríwá nìyí: Ó lọ láti Òkun Ńlá títí lọ dé Hẹ́tílónì,+ sí ọ̀nà Sédádì,+ 16 Hámátì,+ Bérótà+ àti Síbúráímù, tó wà láàárín agbègbè Damásíkù àti Hámátì, ó dé Haseri-hátíkónì, tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ààlà Háúránì.+ 17 Ààlà náà yóò jẹ́ láti òkun dé Hasari-énónì,+ lẹ́bàá ààlà Damásíkù sí àríwá àti ààlà Hámátì.+ Ààlà tó wà ní àríwá nìyí.
18 “Ààlà tó wà ní ìlà oòrùn gba àárín Háúránì àti Damásíkù, títí lọ dé ẹ̀gbẹ́ Jọ́dánì láàárín Gílíádì+ àti ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Kí ẹ wọ̀n ọ́n láti ibi tí ààlà wà dé òkun ìlà oòrùn.* Ààlà tó wà ní ìlà oòrùn nìyí.
19 “Ààlà tó wà ní gúúsù* yóò jẹ́ láti Támárì dé omi Mẹriba-kádéṣì,+ yóò dé Àfonífojì* àti Òkun Ńlá.+ Ààlà tó wà ní gúúsù* nìyí.
20 “Òkun Ńlá ló wà ní apá ìwọ̀ oòrùn, láti ibi tí ààlà wà dé ibì kan tó wà ní òdìkejì Lebo-hámátì.*+ Ààlà tó wà ní ìwọ̀ oòrùn nìyí.”
21 “Kí ẹ pín ilẹ̀ yìí láàárín ara yín, láàárín ẹ̀yà méjìlá (12) Ísírẹ́lì. 22 Kí ẹ pín in kó jẹ́ ogún láàárín ara yín àti láàárín àwọn àjèjì tó ń gbé pẹ̀lú yín tí wọ́n sì ti bímọ nígbà tí wọ́n ń gbé pẹ̀lú yín; bí ọmọ Ísírẹ́lì ni wọ́n á jẹ́ sí yín. Àwọn náà yóò rí ogún gbà bíi tiyín láàárín àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì. 23 Agbègbè tó jẹ́ ti ẹ̀yà tí àjèjì náà ń gbé ni kí ẹ ti fún un ní ogún,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.