Ìsíkíẹ́lì
36 “Ní tìrẹ, ọmọ èèyàn, sọ tẹ́lẹ̀ nípa àwọn òkè Ísírẹ́lì, kí o sì sọ pé, ‘Ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà. 2 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ọ̀tá ti sọ̀rọ̀ sí yín pé, ‘Àháà! Kódà àwọn ibi gíga àtijọ́ ti di ohun ìní wa!’”’+
3 “Torí náà, sọ tẹ́lẹ̀, kí o sì sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Torí pé wọ́n ti sọ yín di ahoro, wọ́n sì ti gbógun jà yín láti ibi gbogbo, kí ẹ lè di ohun ìní àwọn tó là á já* láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ yín ṣáá, wọ́n sì ń bà yín lórúkọ jẹ́,+ 4 torí náà, ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ! Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké nìyí, fún àwọn ìṣàn omi àti àwọn àfonífojì, fún àwọn àwókù tó ti di ahoro+ àti fún àwọn ìlú tí wọ́n pa tì, tí àwọn tó là á já nínú àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ti kó ní ẹrù, tí wọ́n sì fi ṣe ẹlẹ́yà;+ 5 ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ fún àwọn yìí ni pé: ‘Èmi yóò fi ìtara mi tó ń jó bí iná+ sọ̀rọ̀ sí àwọn tó là á já nínú àwọn orílẹ̀-èdè àti sí gbogbo Édómù, àwọn tí inú wọn dùn gan-an, tí wọ́n sì fi mí ṣẹlẹ́yà*+ nígbà tí wọ́n sọ ilẹ̀ mi di ohun ìní wọn, kí wọ́n lè gba àwọn ibi ìjẹko inú ilẹ̀ náà, kí wọ́n sì kó ohun tó wà nínú rẹ̀.’”’+
6 “Torí náà, sọ tẹ́lẹ̀ nípa ilẹ̀ Ísírẹ́lì, kí o sì sọ fún àwọn òkè ńlá àti àwọn òkè kéékèèké, fún àwọn ìṣàn omi àti àwọn àfonífojì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Wò ó! Èmi yóò fi ìtara àti ìbínú sọ̀rọ̀, torí àwọn orílẹ̀-èdè ti fi ọ́ ṣẹlẹ́yà.”’+
7 “Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Mo gbé ọwọ́ mi sókè láti búra pé ojú yóò ti àwọn orílẹ̀-èdè tó wà yí ká.+ 8 Àmọ́ ẹ̀yin òkè Ísírẹ́lì, ẹ ó yọ ẹ̀ka, ẹ ó sì so èso fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì,+ torí wọn ò ní pẹ́ pa dà. 9 Torí mo wà pẹ̀lú yín, èmi yóò sì yíjú sí yín. Wọ́n á fi yín dáko, wọ́n á sì fún irúgbìn sínú yín. 10 Màá mú kí àwọn èèyàn rẹ pọ̀ sí i, gbogbo ilé Ísírẹ́lì, gbogbo rẹ̀ pátá, wọ́n á máa gbé inú àwọn ìlú náà,+ wọ́n á sì tún àwọn àwókù náà kọ́.+ 11 Àní màá sọ àwọn èèyàn rẹ àti ẹran ọ̀sìn rẹ di púpọ̀;+ wọ́n á bí sí i, wọ́n á sì pọ̀ sí i. Èmi yóò mú kí wọ́n máa gbé inú rẹ bíi ti tẹ́lẹ̀,+ èmi yóò sì mú kí nǹkan dáa fún yín ju ti tẹ́lẹ̀ lọ;+ ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.+ 12 Èmi yóò mú kí àwọn èèyàn mi, àní àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, rìn lórí yín, wọ́n á sì sọ yín di ohun ìní.+ Ẹ ó di ogún wọn, ẹ ò sì tún ní sọ wọ́n di ẹni tí kò lọ́mọ mọ́.’”+
13 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Torí wọ́n ń sọ fún yín pé, “Ilẹ̀ tó ń jẹ àwọn èèyàn run tó sì ń mú kí àwọn èèyàn rẹ̀ ṣòfò ọmọ ni ìwọ jẹ́,”’ 14 ‘torí náà, o ò ní jẹ àwọn èèyàn run mọ́, o ò sì ní sọ àwọn èèyàn rẹ di ẹni tí kò lọ́mọ mọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. 15 ‘Mi ò ní mú kí àwọn orílẹ̀-èdè sọ̀rọ̀ èébú sí ọ mọ́, mi ò ní mú kí àwọn èèyàn kẹ́gàn rẹ mọ́,+ o ò sì ní mú àwọn èèyàn rẹ kọsẹ̀ mọ́,’ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.”
16 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 17 “Ọmọ èèyàn, nígbà tí ilé Ísírẹ́lì ń gbé lórí ilẹ̀ wọn, wọ́n fi ìwà àti ìṣe wọn sọ ọ́ di aláìmọ́.+ Lójú mi, ìwà wọn dà bí ìdọ̀tí tó ń jáde lára obìnrin tó ń ṣe nǹkan oṣù.+ 18 Torí náà, mo bínú sí wọn gan-an torí ẹ̀jẹ̀ tí wọ́n ta sórí ilẹ̀ náà+ àti torí pé wọ́n fi òrìṣà ẹ̀gbin* wọn sọ ilẹ̀ náà di aláìmọ́.+ 19 Mo wá tú wọn ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè, mo sì fọ́n wọn ká sí àwọn ilẹ̀.+ Mo fi ìwà àti ìṣe wọn dá wọn lẹ́jọ́. 20 Àmọ́ nígbà tí wọ́n wá sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè yẹn, àwọn èèyàn kó ẹ̀gàn bá orúkọ mímọ́ mi+ bí wọ́n ṣe ń sọ nípa wọn pé, ‘Àwọn èèyàn Jèhófà nìyí, àmọ́ wọ́n fi ilẹ̀ rẹ̀ sílẹ̀.’ 21 Torí náà, màá káàánú orúkọ mímọ́ mi tí ilé Ísírẹ́lì kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n lọ.”+
22 “Torí náà, sọ fún ilé Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ilé Ísírẹ́lì, kì í ṣe torí yín ni mo ṣe gbé ìgbésẹ̀, àmọ́ torí orúkọ mímọ́ mi ni, èyí tí ẹ kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè tí ẹ lọ.”’+ 23 ‘Ó dájú pé màá sọ orúkọ ńlá mi di mímọ́,+ èyí tí wọ́n kó ẹ̀gàn bá láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, tí ẹ kẹ́gàn rẹ̀ láàárín wọn; àwọn orílẹ̀-èdè yóò sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, ‘nígbà tí mo bá fi hàn lójú wọn pé mo jẹ́ mímọ́ láàárín yín. 24 Èmi yóò kó yín látinú àwọn orílẹ̀-èdè, màá pa dà kó yín jọ láti gbogbo ilẹ̀, màá sì mú yín wá sórí ilẹ̀ yín.+ 25 Èmi yóò wọ́n omi tó mọ́ sí yín lára, ẹ ó sì mọ́;+ màá wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ìdọ̀tí yín+ àti gbogbo òrìṣà ẹ̀gbin yín.+ 26 Èmi yóò fún yín ní ọkàn tuntun,+ màá sì fi ẹ̀mí tuntun sínú yín.+ Màá mú ọkàn òkúta+ kúrò lára yín, màá sì fún yín ní ọkàn ẹran.* 27 Èmi yóò fi ẹ̀mí mi sínú yín, màá sì mú kí ẹ máa tẹ̀ lé àwọn ìlànà mi.+ Ẹ ó máa tẹ̀ lé ìdájọ́ mi, ẹ ó sì máa pa wọ́n mọ́. 28 Ẹ ó wá máa gbé ní ilẹ̀ tí mo fún àwọn baba ńlá yín, ẹ ó di èèyàn mi, màá sì di Ọlọ́run yín.’+
29 “‘Èmi yóò gbà yín kúrò nínú gbogbo ìdọ̀tí yín, màá fún yín ní ọkà, èmi yóò sì mú kó pọ̀ gidigidi, mi ò sì ní jẹ́ kí ìyàn mú ní ilẹ̀ yín.+ 30 Èmi yóò mú kí èso igi àti irè oko pọ̀ jaburata, kí ojú má bàa tì yín mọ́ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè torí ìyàn.+ 31 Ẹ ó wá rántí àwọn ìwà búburú yín àti àwọn ohun tí kò dáa tí ẹ ṣe, ẹ ó sì kórìíra ara yín torí pé ẹ jẹ̀bi àti torí ìwà ìríra yín.+ 32 Àmọ́ mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé: Kì í ṣe torí yín ni mo fi ń ṣe èyí,’+ ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí. ‘Àmọ́, kí ojú tì yín, ilé Ísírẹ́lì, kí ẹ sì tẹ́ torí ìwà yín.’
33 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Ní ọjọ́ tí mo bá wẹ̀ yín mọ́ kúrò nínú gbogbo ẹ̀bi yín, èmi yóò mú kí wọ́n máa gbé inú àwọn ìlú náà,+ màá sì mú kí wọ́n tún àwọn àwókù kọ́.+ 34 Wọ́n á dáko sí ilẹ̀ tó ti di ahoro tí gbogbo àwọn tó ń kọjá lọ ń wò. 35 Àwọn èèyàn á sì sọ pé: “Ilẹ̀ tó ti di ahoro náà ti dà bí ọgbà Édẹ́nì,+ àwọn ìlú tó ti di àwókù, tó ti di ahoro, tí wọ́n sì ya lulẹ̀ ti wá ní odi, wọ́n sì ti ń gbé ibẹ̀.”+ 36 Àwọn orílẹ̀-èdè tó ṣẹ́ kù ní àyíká yín yóò wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti kọ́ ohun tó ya lulẹ̀, mo sì ti gbin ohun tó ti di ahoro. Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é.’+
37 “Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: ‘Màá tún jẹ́ kí ilé Ísírẹ́lì sọ pé kí n ṣe nǹkan yìí fún wọn: Èmi yóò mú kí àwọn èèyàn wọn pọ̀ sí i bí agbo ẹran. 38 Bí agbo àwọn ẹni mímọ́, bí agbo Jerúsálẹ́mù* nígbà àjọ̀dún rẹ̀,+ bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìlú tó ti di àwókù yóò kún fún agbo àwọn èèyàn;+ wọ́n á sì wá mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”