Oníwàásù
8 Ta ló dà bí ọlọ́gbọ́n? Ta ló mọ ojútùú ìṣòro?* Ọgbọ́n tí èèyàn ní máa ń mú kí ojú rẹ̀ dán, ó sì máa ń mú kí ojú rẹ̀ tó le rọ̀.
2 Mo ní: “Pa àṣẹ ọba mọ́+ nítorí o ti búra níwájú Ọlọ́run.+ 3 Má ṣe yára kúrò níwájú rẹ̀.+ Má ṣe lọ́wọ́ sí ohunkóhun tó burú;+ torí ohun tó bá wù ú ló lè ṣe, 4 nítorí ohun tí ọba bá sọ ni abẹ gé;+ ta ló sì lè bi í pé, ‘Kí lò ń ṣe?’”
5 Ẹni tó ń pa àṣẹ mọ́ kò ní rí ibi,+ ọkàn ọlọ́gbọ́n á sì mọ àkókò àti ọ̀nà tó yẹ láti gbà ṣe nǹkan.*+ 6 Gbogbo ọ̀ràn ló ní àkókò àti ọ̀nà tó yẹ kéèyàn gbà ṣe é,*+ torí wàhálà aráyé pọ̀ gan-an. 7 Nítorí kò sẹ́ni tó mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀, ta ló lè sọ bó ṣe máa ṣẹlẹ̀ fún un?
8 Bí kò ṣe sí èèyàn tó lágbára lórí ẹ̀mí* tàbí tó lè dá ẹ̀mí dúró, bẹ́ẹ̀ ni kò sẹ́ni tó lágbára lórí ọjọ́ ikú.+ Bí ẹnikẹ́ni kò ṣe lè dá ara rẹ̀ sílẹ̀ lójú ogun, bẹ́ẹ̀ ni ìwà burúkú kò ní jẹ́ kí àwọn tó ń hù ú yè bọ́.*
9 Gbogbo èyí ni mo ti rí, mo sì fọkàn sí gbogbo iṣẹ́ tí a ti ṣe lábẹ́ ọ̀run,* ní àkókò tí èèyàn ti jọba lórí èèyàn sí ìpalára* rẹ̀.+ 10 Mo tún rí i tí wọ́n ń sìnkú àwọn ẹni burúkú, àwọn tó máa ń wọlé, tí wọ́n sì ń jáde ní ibi mímọ́, àmọ́ kò pẹ́ tí wọ́n fi gbàgbé wọn ní ìlú tí wọ́n ti hu irú ìwà yìí.+ Asán ni èyí pẹ̀lú.
11 Nítorí pé a kò tètè mú ìdájọ́ ṣẹ lórí ìwà burúkú,+ ọkàn àwọn èèyàn le gbagidi láti ṣe búburú.+ 12 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹlẹ́ṣẹ̀ lè ṣe búburú ní ọgọ́rùn-ún ìgbà, kó sì pẹ́ láyé, síbẹ̀ mo mọ̀ pé ó máa dára fún àwọn tó bẹ̀rù Ọlọ́run tòótọ́, nítorí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀.+ 13 Àmọ́ kò ní dára fún ẹni burúkú,+ bẹ́ẹ̀ ni kò lè mú kí àwọn ọjọ́ rẹ̀ tó dà bí òjìji gùn,+ nítorí kò bẹ̀rù Ọlọ́run.
14 Ohun kan wà tó jẹ́ asán* tó ń ṣẹlẹ̀ láyé: Àwọn olódodo wà tí aráyé ń hùwà sí bíi pé wọ́n ti ṣe ibi,+ àwọn ẹni burúkú sì wà tí aráyé ń hùwà sí bíi pé wọ́n ti ṣe rere.+ Mo sọ pé asán ni èyí pẹ̀lú.
15 Nítorí náà, ìmọ̀ràn mi ni pé kéèyàn máa yọ̀,+ torí kò sí ohun tó dára fún èèyàn lábẹ́ ọ̀run* ju pé kó jẹ, kó mu, kó sì máa yọ̀; kí inú rẹ̀ máa dùn bó ṣe ń ṣiṣẹ́ àṣekára ní gbogbo ọjọ́ ayé rẹ̀,+ tí Ọlọ́run tòótọ́ fún un lábẹ́ ọ̀run.
16 Mo fi ọkàn mi sí mímọ ọgbọ́n àti sí rírí gbogbo ohun* tó ń lọ nínú ayé,+ kódà mi ò fojú ba oorun* ní ọ̀sán tàbí ní òru. 17 Mo wá wo gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run tòótọ́, mo sì rí i pé aráyé kò lè lóye ohun tó ń lọ lábẹ́ ọ̀run.*+ Bó ti wù kí aráyé sapá tó, kò lè yé wọn. Kódà, tí wọ́n bá sọ pé ọgbọ́n àwọn gbé e láti mọ̀ ọ́n, wọn ò lè lóye rẹ̀ ní ti gidi.+