Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín. Ti Dáfídì.
61 Ọlọ́run, gbọ́ igbe ìrànlọ́wọ́ mi.
Fetí sí àdúrà mi.+
2 Màá ké pè ọ́ láti ìkángun ayé
Nígbà tí ìrẹ̀wẹ̀sì bá bá ọkàn mi.+
Darí mi lọ sórí àpáta tó ga jù mí lọ.+
3 Nítorí ìwọ ni ibi ààbò mi,
Ilé gogoro alágbára tó ń dáàbò bò mí lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.+
4 Màá wà nínú àgọ́ rẹ títí láé;+
Màá fi abẹ́ ìyẹ́ apá rẹ ṣe ibi ààbò.+ (Sélà)
5 Nítorí ìwọ, Ọlọ́run, ti gbọ́ àwọn ẹ̀jẹ́ mi.
O ti fún mi ní ogún tó jẹ́ ti àwọn tó bẹ̀rù orúkọ rẹ.+
6 Wàá mú kí ẹ̀mí ọba gùn,+
Àwọn ọdún rẹ̀ yóò sì jẹ́ láti ìran dé ìran.
7 Yóò jókòó lórí ìtẹ́ níwájú Ọlọ́run títí láé;+
Fún un ní ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti òtítọ́, kí wọ́n lè máa dáàbò bò ó.+
8 Nígbà náà, màá fi orin yin orúkọ rẹ títí láé+
Bí mo ṣe ń san àwọn ẹ̀jẹ́ mi láti ọjọ́ dé ọjọ́.+