Sí Àwọn Hébérù
7 Nítorí Melikisédékì yìí, ọba Sálẹ́mù, àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, pàdé Ábúráhámù nígbà tó ń pa dà bọ̀ látibi tó ti pa àwọn ọba, ó sì súre fún un,+ 2 Ábúráhámù wá fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.* Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ìtúmọ̀ orúkọ rẹ̀ ni “Ọba Òdodo,” bákan náà, ọba Sálẹ́mù, ìyẹn “Ọba Àlàáfíà.” 3 Bó ṣe jẹ́ pé kò ní bàbá, kò ní ìyá, kò ní ìran, kò ní ìbẹ̀rẹ̀ ọjọ́, kò sì ní òpin ìwàláàyè, àmọ́ tí a ṣe é bí Ọmọ Ọlọ́run, ó jẹ́ àlùfáà títí láé.*+
4 Ẹ wo bí ọkùnrin yìí ṣe tóbi tó, ẹni tí Ábúráhámù, olórí ìdílé,* fún ní ìdá mẹ́wàá àwọn ẹrù ogun tó dáa jù.+ 5 Lóòótọ́, bí Òfin ṣe sọ, a pàṣẹ fún àwọn ọmọ Léfì+ tí wọ́n gba iṣẹ́ àlùfáà wọn pé kí wọ́n máa gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ àwọn èèyàn,+ ìyẹn lọ́wọ́ àwọn arákùnrin wọn, bí àwọn yìí tiẹ̀ jẹ́ àtọmọdọ́mọ* Ábúráhámù. 6 Àmọ́ ọkùnrin yìí tí kò wá láti ìran wọn gba ìdá mẹ́wàá lọ́wọ́ Ábúráhámù, ó sì súre fún ẹni tí a ṣèlérí fún.+ 7 Torí náà, ó ṣe kedere pé ẹni tí ó tóbi súre fún ẹni tí ó kéré. 8 Àti pé nínú ọ̀rọ̀ àkọ́kọ́, àwọn èèyàn tó ń kú ló ń gba ìdá mẹ́wàá, àmọ́ nínú ọ̀rọ̀ kejì, ẹnì kan tí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé ó wà láàyè ni.+ 9 A sì lè sọ pé Léfì tó ń gba ìdá mẹ́wàá pàápàá ti san ìdá mẹ́wàá nípasẹ̀ Ábúráhámù, 10 torí àtọmọdọ́mọ tí a kò tíì bí ló ṣì jẹ́ sí* baba ńlá rẹ̀ nígbà tí Melikisédékì pàdé rẹ̀.+
11 Tó bá jẹ́ pé iṣẹ́ àlùfáà+ àwọn ọmọ Léfì lè mú ìjẹ́pípé wá ni (torí ó wà lára Òfin tí a fún àwọn èèyàn), ṣé a tún máa nílò kí àlùfáà míì dìde, ẹni tí a sọ pé ó wà ní ọ̀nà ti Melikisédékì,+ tí kì í ṣe ní ọ̀nà ti Áárónì? 12 Torí nígbà tí a ti yí ètò ṣíṣe àlùfáà pa dà, ó di dandan ká yí Òfin náà pa dà.+ 13 Torí ẹ̀yà míì ni ọkùnrin tí a sọ àwọn nǹkan yìí nípa rẹ̀ ti wá, ẹnì kankan látinú ẹ̀yà náà ò sì ṣiṣẹ́ nídìí pẹpẹ rí.+ 14 Torí ó ṣe kedere pé ọ̀dọ̀ Júdà ni Olúwa wa ti ṣẹ̀ wá,+ síbẹ̀, Mósè ò sọ pé àlùfáà kankan máa wá látinú ẹ̀yà yẹn.
15 Èyí wá túbọ̀ ṣe kedere nígbà tí àlùfáà+ míì tó dà bíi Melikisédékì+ dìde, 16 ẹni tó jẹ́ pé kì í ṣe ohun tí òfin sọ nípa ibi tí èèyàn ti ṣẹ̀ wá ló mú kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó jẹ́ nípasẹ̀ agbára ìwàláàyè tí kò ṣeé pa run.+ 17 Torí a jẹ́rìí nípa rẹ̀ pé: “Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé ní ọ̀nà ti Melikisédékì.”+
18 Torí náà, a pa àṣẹ ti tẹ́lẹ̀ tì torí pé kò lágbára, kò sì gbéṣẹ́ mọ́.+ 19 Torí Òfin ò sọ ohunkóhun di pípé,+ àmọ́ ìrètí tó dáa jù+ tó wọlé wá ṣe bẹ́ẹ̀, èyí tí à ń tipasẹ̀ rẹ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.+ 20 Bákan náà, nígbà tó jẹ́ pé a ò ṣe èyí láìsí ìbúra 21 (torí ní tòótọ́, àwọn èèyàn wà tí wọ́n ti di àlùfáà láìsí ìbúra, àmọ́ ti ẹni yìí rí bẹ́ẹ̀ nípasẹ̀ ìbúra tí a ṣe nípa rẹ̀ látọ̀dọ̀ Ẹni tó sọ pé: “Jèhófà* ti búra, kò sì ní pèrò dà,* ó ní, ‘Ìwọ jẹ́ àlùfáà títí láé’”),+ 22 Jésù wá tipa bẹ́ẹ̀ di ẹni tó fìdí májẹ̀mú tó dáa jù múlẹ̀.*+ 23 Bákan náà, ó di dandan kí ọ̀pọ̀ di àlùfáà tẹ̀ léra+ torí pé ikú ò jẹ́ kí wọ́n lè máa bá iṣẹ́ náà lọ, 24 àmọ́ torí pé òun wà láàyè títí láé,+ kò sí pé ẹnì kan ń rọ́pò rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ àlùfáà. 25 Èyí jẹ́ kó lè gba àwọn tó ń tipasẹ̀ rẹ̀ wá sọ́dọ̀ Ọlọ́run là pátápátá, torí ó wà láàyè nígbà gbogbo láti bá wọn bẹ̀bẹ̀.+
26 Torí irú àlùfáà àgbà yìí ló yẹ wá, ẹni tó jẹ́ adúróṣinṣin, aláìṣẹ̀, aláìlẹ́gbin,+ ẹni tí a yà sọ́tọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí a sì gbé ga ju ọ̀run lọ.+ 27 Kò nílò kó máa rúbọ lójoojúmọ́,+ bíi ti àwọn àlùfáà àgbà yẹn, fún àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tiẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́, lẹ́yìn náà fún ẹ̀ṣẹ̀ àwọn èèyàn,+ torí ó ti ṣe èyí nígbà tó fi ara rẹ̀ rúbọ lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo láìtún ní ṣe é mọ́ láé.+ 28 Torí àwọn èèyàn tó ní àìlera ni Òfin ń yàn ṣe àlùfáà àgbà,+ àmọ́ Ọmọ ni ọ̀rọ̀ ìbúra+ tí a ṣe lẹ́yìn Òfin yàn, ẹni tí a ti sọ di pípé+ títí láé.