Ẹ́sítà
5 Ní ọjọ́ kẹta,+ Ẹ́sítà wọ aṣọ ayaba, ó sì dúró ní àgbàlá inú ilé* ọba ní òdìkejì ààfin ọba, ọba jókòó lórí ìtẹ́ nínú ilé ọba tó wà ní òdìkejì ẹnu ọ̀nà. 2 Bí ọba ṣe rí Ẹ́sítà Ayaba tó dúró ní àgbàlá, ó rí ojú rere ọba, ọba sì na ọ̀pá àṣẹ wúrà+ tó wà lọ́wọ́ rẹ̀ sí Ẹ́sítà. Ẹ́sítà sún mọ́ tòsí, ó sì fọwọ́ kan orí ọ̀pá àṣẹ náà.
3 Ọba béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: “Ẹ́sítà Ayaba, ṣé kò sí o? Kí lo fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó fi fún ọ!” 4 Ẹ́sítà fèsì pé: “Tó bá dáa lójú ọba, kí ọba àti Hámánì+ wá lónìí síbi àsè tí mo ti sè fún ọba.” 5 Torí náà, ọba sọ fún àwọn ọkùnrin rẹ̀ pé: “Ẹ sọ fún Hámánì pé kó wá kíákíá, gẹ́gẹ́ bí Ẹ́sítà ṣe sọ.” Ọba àti Hámánì sì lọ síbi àsè tí Ẹ́sítà sè.
6 Lẹ́yìn àkókò díẹ̀, nígbà tí wọ́n ń mu wáìnì lọ́wọ́, ọba sọ fún Ẹ́sítà pé: “Kí lo fẹ́ tọrọ? A ó fi fún ọ! Kí lo sì fẹ́ béèrè? Kódà tí ó bá tó* ìdajì ìjọba mi, a ó ṣe é fún ọ!”+ 7 Ẹ́sítà dáhùn, ó ní: “Ohun tí mo fẹ́ tọrọ, tí mo sì fẹ́ béèrè ni pé, 8 Tí mo bá rí ojú rere ọba, tó bá sì wu ọba láti ṣe ohun tí mo fẹ́, kó sì fún mi ní ohun tí mo béèrè, kí ọba àti Hámánì wá síbi àsè tí màá sè fún wọn lọ́la; ọ̀la ni màá sì béèrè ohun tí ọba ní kí n béèrè.”
9 Lọ́jọ́ náà, tayọ̀tayọ̀ ni Hámánì fi jáde lọ, inú rẹ̀ sì ń dùn. Ṣùgbọ́n nígbà tí Hámánì rí Módékáì ní ẹnubodè ọba, tó sì rí i pé kò dìde, kò sì wárìrì níwájú òun, inú bí Hámánì gan-an sí Módékáì.+ 10 Àmọ́, Hámánì pa á mọ́ra, ó sì lọ sí ilé rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ránṣẹ́ pe àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti Séréṣì+ ìyàwó rẹ̀. 11 Hámánì wá ń fọ́nnu nípa ọlá ńlá rẹ̀, bí àwọn ọmọ rẹ̀+ ṣe pọ̀ tó, bí ọba ṣe gbé e ga àti bó ṣe gbé e lékè àwọn ìjòyè àti àwọn ìránṣẹ́ ọba.+
12 Hámánì tún sọ pé: “Àfi bíi pé ìyẹn ò tó, èmi nìkan ni Ẹ́sítà Ayaba ní kó bá ọba wá síbi àsè tó sè.+ Ó tún pè mí pé kí n wá lọ́la sọ́dọ̀ òun àti ọba.+ 13 Àmọ́ gbogbo èyí kò tíì tẹ́ mi lọ́rùn tí mo bá ṣì ń rí Módékáì, Júù tó ń jókòó ní ẹnubodè ọba.” 14 Torí náà, Séréṣì aya rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Jẹ́ kí wọ́n gbé òpó igi kan nàró, kí ó ga ní àádọ́ta (50) ìgbọ̀nwọ́.* Tó bá di àárọ̀, sọ fún ọba pé kí wọ́n gbé Módékáì kọ́ sórí rẹ̀.+ Lẹ́yìn náà, kí o bá ọba lọ gbádùn ara rẹ níbi àsè náà.” Àbá yìí dára lójú Hámánì, torí náà ó ní kí wọ́n gbé òpó igi kan nàró.