Míkà
7 Ó mà ṣe fún mi o! Mo dà bí ẹni tí
Kò rí àwọn èso àjàrà jẹ,
Tí kò sì rí àkọ́so ọ̀pọ̀tọ́ tó wù ú* jẹ,
Lẹ́yìn tí wọ́n kó èso ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn jọ,
Tí wọ́n sì ti pèéṣẹ́* lẹ́yìn ìkórè èso àjàrà.
Gbogbo wọn lúgọ kí wọ́n lè ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀.+
Kálukú wọn ń fi àwọ̀n dọdẹ arákùnrin rẹ̀.
3 Wọ́n mọ iṣẹ́ ibi ṣe dáadáa;+
Olórí ń béèrè nǹkan lọ́wọ́ àwọn èèyàn,
Adájọ́ ń béèrè àbẹ̀tẹ́lẹ̀,+
Wọ́n sì jọ gbìmọ̀ pọ̀.*
4 Ẹni tó dáa jù nínú wọn dà bí ẹ̀gún,
Ẹni tó jẹ́ olóòótọ́ jù láàárín wọn burú ju ọgbà ẹlẹ́gùn-ún lọ.
Ọjọ́ tí àwọn olùṣọ́ rẹ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ àti ọjọ́ ìyà rẹ yóò dé.+
Ẹ̀rù yóò sì bà wọ́n.+
5 Má ṣe gbára lé ẹnì kejì rẹ,
Má sì gbẹ́kẹ̀ lé ọ̀rẹ́ rẹ tímọ́tímọ́.+
Máa ṣọ́ ohun tí wàá sọ fún ẹni tó ń sùn sí àyà rẹ.
6 Torí ọmọkùnrin ń tàbùkù sí bàbá rẹ̀,
Ọmọbìnrin ń bá ìyá rẹ̀ jà,+
Ìyàwó ń gbógun ti ìyá ọkọ rẹ̀;+
Ará ilé ẹni ni ọ̀tá ẹni.+
7 Àmọ́ ní tèmi, èmi yóò máa retí Jèhófà.+
Màá dúró* de Ọlọ́run ìgbàlà mi.+
Ọlọ́run mi yóò gbọ́ mi.+
8 Má yọ̀ mí, ìwọ ọ̀tá mi.*
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé mo ti ṣubú, màá dìde;
Bí mo tiẹ̀ wà nínú òkùnkùn, Jèhófà yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ mi.
Yóò mú mi wá sínú ìmọ́lẹ̀;
Èmi yóò rí òdodo rẹ̀.
10 Ọ̀tá mi pẹ̀lú yóò rí i,
Ojú yóò sì ti ẹni tó ń sọ fún mi pé:
“Jèhófà Ọlọ́run rẹ dà?”+
Ojú mi yóò rí i.
Wọn yóò tẹ̀ ẹ́ mọ́lẹ̀ bí ẹrẹ̀ lójú ọ̀nà.
11 Ọjọ́ yẹn ni wọ́n máa mọ ògiri olókùúta rẹ;
Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa sún ààlà síwájú.*
12 Ní ọjọ́ yẹn, wọ́n máa wá sọ́dọ̀ rẹ
Láti Ásíríà lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún àti láti àwọn ìlú Íjíbítì,
Láti Íjíbítì títí lọ dé Odò;*
Láti òkun dé òkun àti láti òkè dé òkè.+
13 Ilẹ̀ náà yóò sì di ahoro torí àwọn tó ń gbé ibẹ̀,
Nítorí ohun tí wọ́n ṣe.*
14 Fi ọ̀pá rẹ ṣe olùṣọ́ àgùntàn àwọn èèyàn rẹ, agbo ẹran tó jẹ́ ogún rẹ,+
Tó ń dá gbé inú igbó, láàárín ọgbà eléso.
Jẹ́ kí Báṣánì àti Gílíádì+ fún wọn ní oúnjẹ bíi ti àtijọ́.
15 “Màá fi àwọn ohun àgbàyanu hàn án,+
Bíi ti ìgbà tí ẹ kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.
16 Àwọn orílẹ̀-èdè yóò rí i, ojú sì máa tì wọ́n bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n lágbára.+
Wọ́n á fi ọwọ́ bo ẹnu;
Etí wọn á di.
17 Wọ́n á lá erùpẹ̀ bí ejò;+
Wọ́n á máa gbọ̀n rìrì bí wọ́n ṣe ń jáde látinú ibi ààbò wọn bí àwọn ẹran tó ń fàyà fà.
Wọ́n á wá sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa pẹ̀lú ìbẹ̀rù,
Ẹ̀rù rẹ yóò sì bà wọ́n.”+
18 Ta ló dà bí rẹ, Ọlọ́run,
Tó ń dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini, tó sì ń gbójú fo ìṣìnà+ àwọn tó ṣẹ́ kù nínú ogún rẹ̀?+
Kò ní máa bínú lọ títí láé,
Torí inú rẹ̀ máa ń dùn sí ìfẹ́ tí kì í yẹ̀.+
19 Ó tún máa ṣàánú wa;+ ó sì máa pa àwọn àṣìṣe wa rẹ́.*
O máa ju gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ wọn sí ìsàlẹ̀ òkun.+
20 O máa jẹ́ olóòótọ́ sí Jékọ́bù,
Ìfẹ́ tí o ní sí Ábúráhámù kò ní yẹ̀,
Bí o ṣe búra fún àwọn baba ńlá wa láti ìgbà àtijọ́.+