Míkà
2 “Àwọn tó ń gbìmọ̀ ìkà gbé,
Tí wọ́n ń gbèrò ibi lórí ibùsùn wọn!
Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n ṣe ohun tí wọ́n gbèrò,
Torí pé agbára wọn ká a.+
2 Oko olóko wọ̀ wọ́n lójú, wọ́n sì gbà á;+
Bẹ́ẹ̀ náà ni wọ́n gba ilé onílé;
Wọ́n fi jìbìtì gba ilé mọ́ onílé lọ́wọ́,+
Wọ́n gba ogún lọ́wọ́ ẹni tó ni ín.
3 Torí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
‘Mò ń gbèrò àjálù kan sí ìdílé yìí,+ ẹ kò sì ní yè bọ́.*+
Ẹ kò ní lè gbéra ga mọ́,+ torí àkókò àjálù ló máa jẹ́.+
Wọ́n á sọ pé: “Ó ti pa wá run pátápátá!+
Ó ti gba ìpín àwọn èèyàn wa. Ó sì ti fún àwọn ẹlòmíì!+
Ó ti fún àwọn aláìṣòótọ́ ní ilẹ̀ wa.”
5 Torí náà, kò ní sí ẹnì kankan tó máa bá yín ta okùn,
Láti fi pín ilẹ̀ nínú ìjọ Jèhófà.
6 Wọ́n ń pàrọwà fún wọn pé: “Ẹ má wàásù mọ́!
Kò yẹ kí wọ́n máa wàásù nípa àwọn nǹkan yìí;
Ojú kò ní tì wá!”
7 Ilé Jékọ́bù, ṣé ohun tí àwọn èèyàn ń sọ ni pé:
“Àbí Jèhófà* kò ní sùúrù mọ́ ni?
Ṣé iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ nìyí?”
Àbí, ṣé ọ̀rọ̀ mi kì í ṣe àwọn olódodo láǹfààní ni?
8 Àmọ́ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn èèyàn mi ti sọ ara wọn di ọ̀tá.
Ẹ bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ tó gbayì àti ẹ̀wù* lọ́rùn àwọn èèyàn ní gbangba,
Lọ́rùn àwọn tó ń kọjá lọ tí ọkàn wọn sì balẹ̀ bí ẹni tó ń ti ogun bọ̀.
9 Ẹ lé àwọn obìnrin àwọn èèyàn mi kúrò nínú ilé tí wọ́n fẹ́ràn;
Ògo tí mo fún àwọn ọmọ wọn lẹ gbà lọ́wọ́ wọn títí láé.
10 Ẹ dìde, kí ẹ máa lọ, torí ibí kì í ṣe ibi ìsinmi.
Torí ìwà àìmọ́ yín,+ ẹ máa pa run, ìparun pátápátá.+
11 Bí èèyàn kan bá wà tó ń lépa asán, tó ń tanni jẹ, tó sì ń parọ́ pé:
“Màá wàásù fún yín nípa wáìnì àti ọtí,”
Irú ẹni bẹ́ẹ̀ gan-an ni oníwàásù táwọn èèyàn yìí fẹ́!+
Màá mú kí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, bí àgùntàn ní ilé ẹran,
Bí agbo ẹran ní pápá ìjẹko wọn;+
Ariwo àwọn èèyàn máa gba ibẹ̀ kan.’+
13 Ẹni tó ń la ọ̀nà yóò lọ ṣáájú wọn;
Wọ́n á la ọ̀nà, wọ́n á gba ẹnubodè kọjá, wọ́n á sì gba ibẹ̀ jáde.+
Ọba wọn yóò ṣáájú wọn,
Jèhófà yóò sì ṣe olórí wọn.”+