Nehemáyà
1 Ọ̀rọ̀ Nehemáyà*+ ọmọ Hakaláyà nìyí: Ní oṣù Kísíléfì,* ní ogún ọdún ìṣàkóso ọba,* mo wà ní Ṣúṣánì*+ ilé ńlá.* 2 Lákòókò náà, Hánáánì,+ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ọkùnrin míì láti Júdà wá sọ́dọ̀ mi, mo sì béèrè lọ́wọ́ wọn nípa àwọn Júù tó ṣẹ́ kù, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú,+ mo tún béèrè nípa Jerúsálẹ́mù. 3 Wọ́n sọ pé: “Àwọn tó ṣẹ́ kù sí ìpínlẹ̀* Júdà, tí wọ́n yè bọ́ lóko ẹrú wà nínú ìṣòro ńlá, ìtìjú sì bá wọn.+ Àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù ti wó lulẹ̀,+ wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀.”+
4 Nígbà tí mo gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, mo jókòó, mo ń sunkún, mo sì fi ọ̀pọ̀ ọjọ́ ṣọ̀fọ̀, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbààwẹ̀,+ mo sì ń gbàdúrà níwájú Ọlọ́run ọ̀run. 5 Mo sọ pé: “Ìwọ Jèhófà, Ọlọ́run ọ̀run, Ọlọ́run tí ó tóbi, tó sì yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù, tó ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́, tó sì ń fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́,+ 6 jọ̀ọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sílẹ̀, kí o sì bojú wò mí láti gbọ́ àdúrà ìránṣẹ́ rẹ, tí mò ń gbà sí ọ lónìí. Tọ̀sántòru ni mò ń gbàdúrà+ nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo ìgbà yẹn ni mò ń jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dá sí ọ. A ti ṣẹ̀, àtèmi àti ilé bàbá mi.+ 7 Ó dájú pé a ti hùwà ìbàjẹ́ sí ọ,+ bí a ò ṣe pa àwọn àṣẹ àti àwọn ìlànà rẹ mọ́, tí a ò sì tẹ̀ lé àwọn ìdájọ́ rẹ, èyí tí o fún Mósè ìránṣẹ́ rẹ.+
8 “Jọ̀ọ́, rántí ọ̀rọ̀ tí o pa láṣẹ fún* Mósè ìránṣẹ́ rẹ pé: ‘Tí ẹ bá hùwà àìṣòótọ́, màá fọ́n yín ká sáàárín àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè.+ 9 Àmọ́ tí ẹ bá pa dà sọ́dọ̀ mi, tí ẹ pa àwọn àṣẹ mi mọ́, tí ẹ sì tẹ̀ lé wọn, kódà tí àwọn èèyàn yín tí a fọ́n ká bá wà ní ìpẹ̀kun ọ̀run, màá kó wọn jọ+ láti ibẹ̀, màá sì mú wọn wá sí ibi tí mo ti yàn pé kí orúkọ mi máa wà.’+ 10 Ìránṣẹ́ rẹ ni wọ́n, èèyàn rẹ sì ni wọ́n, àwọn tí o fi agbára ńlá rẹ àti ọwọ́ agbára rẹ rà pa dà.+ 11 Ìwọ Jèhófà, jọ̀ọ́, jẹ́ kí etí rẹ ṣí sí àdúrà ìránṣẹ́ rẹ àti sí àdúrà àwọn ìránṣẹ́ rẹ tí inú wọn ń dùn láti máa bẹ̀rù orúkọ rẹ, jọ̀ọ́, jẹ́ kí ìránṣẹ́ rẹ ṣàṣeyọrí lónìí, kí ọkùnrin yìí sì ṣojú àánú sí mi.”+
Lásìkò yìí, agbọ́tí ọba ni mí.+