Nehemáyà
2 Ní oṣù Nísàn,* ní ogún ọdún + Ọba Atasásítà,+ wáìnì wà níwájú ọba, mo gbé wáìnì bí mo ti máa ń ṣe, mo sì gbé e fún ọba.+ Àmọ́ mi ò fajú ro níwájú rẹ̀ rí. 2 Ni ọba bá sọ fún mi pé: “Kí ló dé tí o fajú ro nígbà tí kì í ṣe pé ò ń ṣàìsàn? Mo mọ̀ pé ìbànújẹ́ ló mú kí o fajú ro, kì í ṣe nǹkan míì.” Ẹ̀rù sì bà mí gan-an.
3 Nígbà náà, mo sọ fún ọba pé: “Kí ẹ̀mí ọba ó gùn! Báwo ni ojú mi ò ṣe ní fà ro nígbà tí ìlú tí wọ́n sin àwọn baba ńlá mi sí ti di àwókù, tí iná sì ti jó àwọn ẹnubodè rẹ̀?”+ 4 Ọba wá sọ fún mi pé: “Kí ni ohun tí o fẹ́ gan-an?” Lójú ẹsẹ̀, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run ọ̀run.+ 5 Mo sì sọ fún ọba pé: “Tó bá dáa lójú ọba, tí ìránṣẹ́ rẹ bá sì ti rí ojú rere rẹ, kí o rán mi lọ sí Júdà, ní ìlú tí wọ́n sin àwọn baba ńlá mi sí, kí n lè tún un kọ́.”+ 6 Ni ọba pẹ̀lú ayaba* tó jókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ bá sọ fún mi pé: “Báwo ni ìrìn àjò rẹ ṣe máa pẹ́ tó, ìgbà wo lo sì máa pa dà?” Torí náà, ó dáa lójú ọba pé kó rán mi lọ,+ mo sì dá ìgbà fún un.+
7 Lẹ́yìn náà, mo sọ fún ọba pé: “Tó bá dáa lójú ọba, jẹ́ kí wọ́n fún mi ní àwọn lẹ́tà tí màá fún àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò,*+ kí wọ́n lè jẹ́ kí n kọjá títí màá fi dé Júdà 8 àti lẹ́tà tí màá fún Ásáfù tó ń ṣọ́ Ọgbà Ọba,* kó lè fún mi ní gẹdú tí màá fi ṣe òpó àwọn ẹnubodè Odi+ Ilé Ọlọ́run* àti ògiri ìlú náà+ pẹ̀lú ilé tí màá gbé.” Nítorí náà, ọba kó wọn fún mi,+ torí pé ọwọ́ rere Ọlọ́run mi wà lára mi.+
9 Nígbà tó yá, mo dé ọ̀dọ̀ àwọn gómìnà agbègbè tó wà ní Ìkọjá Odò, mo sì fún wọn ní àwọn lẹ́tà ọba. Bákan náà, ọba rán àwọn olórí ọmọ ogun àti àwọn agẹṣin tẹ̀ lé mi. 10 Nígbà tí Sáńbálátì+ ará Hórónì àti Tòbáyà + ọmọ Ámónì+ tó jẹ́ òṣìṣẹ́* ọba, gbọ́ nípa rẹ̀, inú wọn ò dùn rárá pé ẹnì kan wá láti wá ṣe ohun rere fún àwọn èèyàn Ísírẹ́lì.
11 Níkẹyìn, mo dé Jerúsálẹ́mù, mo sì lo ọjọ́ mẹ́ta níbẹ̀. 12 Mo dìde ní òru, èmi àti àwọn ọkùnrin díẹ̀ tó wà pẹ̀lú mi, mi ò sọ fún ẹnikẹ́ni nípa ohun tí Ọlọ́run mi fi sí mi lọ́kàn láti ṣe fún Jerúsálẹ́mù, kò sì sí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ kankan lọ́dọ̀ mi àfi èyí tí mo gùn. 13 Mo gba Ẹnubodè Àfonífojì+ jáde ní òru, mo kọjá níwájú Ojúsun Ejò Ńlá lọ sí Ẹnubodè Òkìtì Eérú,+ mo sì ṣàyẹ̀wò àwọn ògiri Jerúsálẹ́mù tó ti wó lulẹ̀ àti àwọn ẹnubodè rẹ̀ tí iná ti jó.+ 14 Mo kọjá lọ sí Ẹnubodè Ojúsun+ àti sí Odò Ọba, kò sì sí àyè tí ó tó fún kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tí mo gùn láti kọjá. 15 Àmọ́ mò ń gba àfonífojì náà+ lọ ní òru, mo sì ń yẹ àwọn ògiri náà wò, lẹ́yìn èyí, mo yíjú pa dà, mo sì gba Ẹnubodè Àfonífojì wọlé, lẹ́yìn náà, mo pa dà.
16 Àwọn alábòójútó+ kò mọ ibi tí mo lọ àti ohun tí mò ń ṣe, torí mi ò tíì sọ ohunkóhun fún àwọn Júù, àwọn àlùfáà, àwọn èèyàn pàtàkì, àwọn alábòójútó àti àwọn òṣìṣẹ́ yòókù. 17 Níkẹyìn, mo sọ fún wọn pé: “Ẹ wo ìṣòro ńlá tó wà níwájú wa, bí Jerúsálẹ́mù ṣe di àwókù, tí wọ́n sì ti dáná sun àwọn ẹnubodè rẹ̀. Ẹ wá, ẹ jẹ́ ká tún ògiri Jerúsálẹ́mù mọ, ká lè bọ́ lọ́wọ́ ìtìjú tó bá wa yìí.” 18 Lẹ́yìn náà, mo sọ fún wọn nípa bí ọwọ́ rere Ọlọ́run mi ṣe wà lára mi,+ mo sì tún sọ ohun tí ọba sọ fún mi.+ Ni wọ́n bá sọ pé: “Ẹ jẹ́ ká dìde, ká sì kọ́lé.” Torí náà, wọ́n fún ara wọn níṣìírí* láti ṣe iṣẹ́ rere náà.+
19 Nígbà tí Sáńbálátì ará Hórónì àti Tòbáyà + ọmọ Ámónì+ tó jẹ́ òṣìṣẹ́ ọba* pẹ̀lú Géṣémù ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í fi wá ṣe yẹ̀yẹ́,+ wọ́n sì ń fojú pa wá rẹ́, wọ́n ní: “Kí lẹ̀ ń ṣe yìí? Ẹ fẹ́ ṣọ̀tẹ̀ sí ọba, àbí?”+ 20 Àmọ́, mo fún wọn lésì pé: “Ọlọ́run ọ̀run ni Ẹni tó máa jẹ́ ká ṣàṣeyọrí,+ àwa ìránṣẹ́ rẹ̀ yóò dìde, a ó sì kọ́lé; àmọ́ ẹ̀yin ò ní ìpín kankan, bẹ́ẹ̀ ni ẹ ò ní ẹ̀tọ́ tàbí ìrántí ní Jerúsálẹ́mù.”+