Diutarónómì
25 “Tí àwọn èèyàn bá ń bára wọn fa ọ̀rọ̀, kí wọ́n kó ara wọn lọ sọ́dọ̀ àwọn adájọ́,+ wọ́n á sì bá wọn dá ẹjọ́ wọn, wọ́n á dá olódodo láre, wọ́n á sì dá ẹni burúkú lẹ́bi.+ 2 Tí ẹgba bá tọ́ sí ẹni burúkú náà,+ kí adájọ́ dá a dọ̀bálẹ̀, kí wọ́n sì nà án níṣojú rẹ̀. Bí ohun tó ṣe bá ṣe burú tó ni kí iye ẹgba tó máa jẹ ṣe pọ̀ tó. 3 Ó lè nà án ní ogójì [40] ẹgba,+ àmọ́ kó má jù bẹ́ẹ̀ lọ. Tó bá nà án ní iye tó ju ìyẹn lọ, ó máa dójú ti arákùnrin rẹ níṣojú rẹ.
4 “O ò gbọ́dọ̀ di ẹnu akọ màlúù nígbà tó bá ń pa ọkà.+
5 “Tí àwọn arákùnrin bá jọ ń gbé, tí ọ̀kan nínú wọn sì kú láìní ọmọ, ìyàwó èyí tó kú kò gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹni tí kì í ṣe mọ̀lẹ́bí ọkọ rẹ̀. Kí ẹ̀gbọ́n tàbí àbúrò ọkọ rẹ̀ lọ bá a, kó sì fi ṣe aya, kó ṣú u lópó.+ 6 Ọmọ tí obìnrin náà bá kọ́kọ́ bí á mú kí orúkọ arákùnrin rẹ̀ tó kú náà ṣì máa wà,+ kí orúkọ náà má bàa pa rẹ́ ní Ísírẹ́lì.+
7 “Àmọ́ tí ọkùnrin náà kò bá fẹ́ ṣú ìyàwó arákùnrin rẹ̀ lópó, kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ tó kú náà lọ bá àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú, kó sì sọ fún wọn pé, ‘Arákùnrin ọkọ mi kò fẹ́ kí orúkọ arákùnrin rẹ̀ ṣì máa wà ní Ísírẹ́lì. Kò gbà láti ṣú mi lópó.’ 8 Kí àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ wá pè é, kí wọ́n sì bá a sọ̀rọ̀. Tó bá ṣì takú, tó ń sọ pé, ‘Mi ò fẹ́ ẹ,’ 9 kí ìyàwó arákùnrin rẹ̀ tó kú náà wá sún mọ́ ọn níṣojú àwọn àgbààgbà, kó bọ́ bàtà ẹsẹ̀ ọkùnrin náà,+ kó tutọ́ sí i lójú, kó sì sọ pé, ‘Ohun tó yẹ kí wọ́n ṣe sí ọkùnrin tí kò fẹ́ kí ìdílé arákùnrin rẹ̀ ṣì máa wà nìyẹn.’ 10 Lẹ́yìn náà, wọ́n á mọ orúkọ ilé rẹ̀* sí ‘Ilé ẹni tí wọ́n bọ́ bàtà lẹ́sẹ̀ rẹ̀’ ní Ísírẹ́lì.
11 “Tí ọkùnrin méjì bá ń bára wọn jà, tí ìyàwó ọ̀kan sì wá gbèjà ọkọ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó ń lù ú, tó na ọwọ́ rẹ̀, tó sì rá ọkùnrin náà mú ní abẹ́, 12 ṣe ni kí o gé ọwọ́ obìnrin náà. O* ò gbọ́dọ̀ káàánú rẹ̀.
13 “O ò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òkúta ìwọ̀n méjì nínú àpò rẹ,+ èyí tó tóbi àti èyí tó kéré. 14 O ò gbọ́dọ̀ ní oríṣi òṣùwọ̀n méjì nínú ilé rẹ,*+ èyí tó tóbi àti èyí tó kéré. 15 Ìwọ̀n tó péye tó sì tọ́ àti òṣùwọ̀n tó péye tó sì tọ́ ni kí o máa lò, kí o lè pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ.+ 16 Torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ kórìíra gbogbo ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí, tó ń rẹ́ ẹlòmíì jẹ.+
17 “Ẹ rántí ohun tí Ámálékì ṣe sí yín lójú ọ̀nà nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì,+ 18 bó ṣe pàdé yín lójú ọ̀nà nígbà tó ti rẹ̀ yín, tí ẹ ò sì lókun, tó sì gbógun ja gbogbo àwọn tó ń wọ́ rìn lẹ́yìn yín. Kò bẹ̀rù Ọlọ́run. 19 Tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ti mú kí o sinmi lọ́wọ́ gbogbo ọ̀tá rẹ tó yí ọ ká, ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún,+ kí o pa orúkọ Ámálékì rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run.+ O ò gbọ́dọ̀ gbàgbé.