Ọ̀rọ̀ Jèhófà Yè
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Diutarónómì
ỌDÚN 1473 ṣáájú Sànmánì Tiwa ni. Ogójì ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí Jèhófà dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò lóko ẹrú Íjíbítì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sì ti rìn nínú aginjù fún ogójì ọdún wọ̀nyí, síbẹ̀ wọn ò tíì ní ilẹ̀ tiwọn. Àmọ́ nígbẹ̀yìngbẹ́yín, wọ́n dé ààlà Ilẹ̀ Ìlérí. Kí ló máa ṣẹlẹ̀ sí wọn bí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í gba ilẹ̀ ìlérí, nítorí àtilè máa gbé níbẹ̀? Àwọn ìṣòro wo ni wọ́n máa ní? Báwo ló sì ṣe yẹ kí wọ́n yanjú àwọn ìṣòro náà?
Kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó sọdá Odò Jọ́dánì lọ sí ilẹ̀ ìlérí, Mósè mú wọn gbára dì fún iṣẹ́ bàǹtàbanta tí wọ́n máa tó ṣe. Báwo ló ṣe mú wọn gbára dì? Nípa sísọ ọ̀wọ́ àwọn àsọyé ni. Ó fi àwọn àsọyé náà mú wọn lọ́kàn le, ó fi gbà wọ́n níyànjú, ó fi ṣí wọn létí, ó sì fi kì wọ́n nílọ̀. Mósè rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé Jèhófà yẹ lẹ́ni à ń fún ní ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe. Ó rán wọn létí pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe bí àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká. Àwọn àsọyé wọ̀nyí ló pọ̀ jù lọ nínu àwọn àkọsílẹ̀ inú ìwé Diutarónómì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé Bíbélì. Àwa náà nílò ìmọ̀ràn tó wà nínú àwọn àsọyé yẹn lóde òní o, nítorí pé à ń gbé nínú ayé tí ò ti rọrùn láti fún Ọlọ́run ní ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe.—Hébérù 4:12.
Tá a bá yọwọ́ orí tó kẹ́yìn, Mósè ló kọ gbogbo ìwé Diutarónómì. Ó sì lé díẹ̀ lóṣù méjì tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú ìwé Diutarónómì fi wáyé.a (Diutarónómì 1:3; Jóṣúà 4:19) Ẹ wá jẹ́ ká wo bí ìmọ̀ràn tó wà nínú ìwé Bíbélì yìí ṣe lè mú ká fi gbogbo ọkàn wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run ká sì fi ìṣòtítọ́ sìn ín.
‘MÁ ṢE GBÀGBÉ ÀWỌN OHUN TÍ OJÚ RẸ TI RÍ’
Nínú àsọyé àkọ́kọ́, Mósè sọ díẹ̀ lára àwọn ìrírí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní nígbà tí wọ́n wà láginjù lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, ní pàtàkì àwọn ìrírí tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́ bí wọ́n ṣe ń múra àtigba Ilẹ̀ Ìlérí. Ọ̀rọ̀ nípa bí Jèhófà ṣe yan àwọn onídàájọ́ ti ní láti rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé ọ̀nà tí Jèhófà gbà ń ṣètò àwọn ènìyàn rẹ̀ fi hàn pé ó máa ń bójú tóni tìfẹ́tìfẹ́. Mósè tún sọ fún wọn pé ìròyìn búburú tí àwọn amí mẹ́wàá mú wá láti ilẹ̀ ìlérí ló fà á tí ìran ìṣáájú ò fi lè dé Ilẹ̀ Ìlérí. Ronú lórí ipa tí àpẹẹrẹ tí ń kini nílọ̀ yẹn á ti ní lórí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bí wọ́n ti ń wo ilẹ̀ ìlérí lọ́ọ̀ọ́kán.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rántí bí Jèhófà ṣe mú kí wọ́n ṣẹ́gun nínú ìjà tí wọ́n jà kí wọ́n tó sọdá Jọ́dánì. Ìyẹn ti ní láti fún wọn ní ìgboyà bí wọ́n ṣe múra tán láti bẹ̀rẹ̀ ìjà àjàṣẹ́gun ní òdìkejì odò Jọ́dánì. Ìbọ̀rìṣà pọ̀ gan-an ní ilẹ̀ tí wọ́n máa tó gbà náà. Ẹ ò rí i pé ó dára bí Mósè ṣe kìlọ̀ fún wọn gidigidi pé wọn ò gbọ́dọ̀ jọ́sìn òrìṣà!
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
2:4-6, 9, 19, 24, 31-35; 3:1-6—Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi pa àwọn èèyàn kan tí wọ́n ń gbé ní ìlà oòrùn Jọ́dánì run tí wọ́n sì dá àwọn kan tí wọ́n ń gbé ní àgbègbè kan náà sí? Jèhófà pàṣẹ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé wọn ò gbọ́dọ̀ bá àwọn ọmọ Ísọ̀ jà. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọmọ ìyá Jékọ́bù ni Ísọ̀ baba ńlá wọn. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ gbógun ti àwọn ará Móábù àtàwọn ọmọ Ámónì nítorí pé wọ́n jẹ́ ìran ọmọ Lọ́ọ̀tì tó jẹ́ ọmọ ẹ̀gbọ́n Ábúráhámù. Àmọ́ Síhónì àti Ógù tí wọ́n jẹ́ ọba Ámórì ò lè sọ pé àwọn lẹ́tọ̀ọ́ sí ilẹ̀ táwọn ń ṣàkóso lé lórí nítorí pé wọn ò bá Ísírẹ́lì tan ní tiwọn. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí Síhónì fàáké kọ́rí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ gba ilẹ̀ òun kọjá, tí Ógù náà wá gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, Jèhófà pàṣẹ pé kí Ísírẹ́lì pa àwọn ìlú wọn run, kí wọ́n má sì jẹ́ kí ẹnì kankan nínú wọn sálà.
4:15-20, 23, 24—Ǹjẹ́ kíkà tí Jèhófà ka ṣíṣe ère gbígbẹ́ léèwọ̀ túmọ̀ sí pé ó burú láti gbẹ́ ère ohun kan fún fífi ṣe ọ̀ṣọ́ lásán? Rárá. Ohun tí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kà léèwọ̀ ni ṣíṣe ère nítorí àtijọ́sìn rẹ̀, ìyẹn ni pé wọn ò gbọ́dọ̀ ‘tẹrí ba fún ère wọn ò sì gbọ́dọ̀ sìn ín.’ Bíbélì ò ka gbígbẹ́ ère tàbí yíya àwòrán ohun kan láti fi ṣe ọ̀ṣọ́ léèwọ̀.—1 Àwọn Ọba 7:18, 25.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
1:2, 19. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì rìn gbéregbère kiri nínú aginjù fún nǹkan bí ọdún méjìdínlógójì bó tilẹ̀ jẹ́ pé “ìrìn ọjọ́ mọ́kànlá” péré ni Kadeṣi-bánéà ‘láti Hórébù [àgbègbè olókè tó yí Òkè Sínáì ká níbi ti Mósè ti gba Òfin Mẹ́wàá] béèyàn bá gba Òkè Ńlá Séírì wọ̀ ọ́.’ Ẹ ò rí i pé baba ńlá ìyà ló jẹ wọ́n nítorí àìgbọràn wọn sí Jèhófà Ọlọ́run!—Númérì 14:26-34.
1:16, 17. Ìlànà tí Ọlọ́run fi ṣèdájọ́ láyé ọjọ́un ò tíì yí padà. Àwọn tá a fún ní ẹrù iṣẹ́ láti sìn gẹ́gẹ́ bí ara ìgbìmọ̀ onídàájọ́ ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ojúsàájú tàbí ìbẹ̀rù ènìyàn mú wọn yí ìdájọ́ po.
4:9. Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yóò bá ṣàṣeyọrí, ‘wọn ò gbọ́dọ̀ gbàgbé àwọn ohun tí ojú wọn ti rí.’ Bí ayé tuntun tí Ọlọ́run ṣèlérí ti ń sún mọ́lé, ó ṣe pàtàkì pé kí àwa náà máa fọkàn wa sí àwọn ohun àgbàyanu tí Jèhófà ń ṣe nípa fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ rẹ̀.
NÍFẸ̀Ẹ́ JÈHÓFÀ KÓ O SÌ PA ÀṢẸ RẸ̀ MỌ́
Nínú àsọyé rẹ̀ kejì, Mósè rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí bí Jèhófà ṣe fún wọn ní Òfin ní Òkè Sínáì ó sì tún Òfin Mẹ́wàá sọ. Ó sọ pé orílẹ̀-èdè méje ni wọ́n máa pa run yán-ányán-án. Ó rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí ẹ̀kọ́ pàtàkì tí wọ́n kọ́ nígbà tí wọ́n wà láginjù, ìyẹn ni pé: “Ènìyàn kì í tipa oúnjẹ nìkan ṣoṣo wà láàyè, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo gbólóhùn ọ̀rọ̀ ẹnu Jèhófà ni ènìyàn fi ń wà láàyè.” Nínú ipò tuntun tí wọ́n wà yẹn, wọ́n gbọ́dọ̀ ‘pa gbogbo àṣẹ náà mọ́.’—Diutarónómì 8:3; 11:8.
Bí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì bá dé ilẹ̀ ìlérí, wọ́n á nílò òfin. Ìyẹn ò ní jẹ́ òfin lórí ọ̀ràn ìjọsìn wọn nìkan, àmọ́ ó máa kan ìdájọ́, àkóso, ogun àti bí wọ́n á ṣe máa gbé ìgbésí ayé wọn ojoojúmọ́ láwùjọ àti bí kálukú á ṣe máa gbé ìgbésí ayé rẹ̀. Mósè ṣàtúnyẹ̀wò àwọn òfin wọ̀nyí ó sì tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà kí wọ́n sì pa àṣẹ rẹ̀ mọ́.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
8:3, 4—Lọ́nà wo ni aṣọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò fi gbó tí ẹsẹ̀ wọn kò sì wú nígbà tí wọ́n ń rìn láginjù? Iṣẹ́ ìyanu Ọlọ́run ni eléyìí o, bíi mánà tí Ọlọ́run ń pèsè fún wọn déédéé. Aṣọ àti bàtà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní kí wọ́n tó dé aginjù ni wọ́n lò ní gbogbo ọdún tí wọ́n fi wà láginjù. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ńṣe ni wọ́n ń lò ó látorí ẹnì kan dé orí ẹlòmíràn bí àwọn ọmọ ṣe ń dàgbà táwọn àgbàlagbà sì ń kú. Nígbà tó sì ti jẹ́ pé Ìkànìyàn tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n dé aginjù àtèyí tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n kúrò láginjù fi hàn pé wọn ò lé sí i, aṣọ àti bàtà tí wọ́n ní kí wọ́n tó dé aginjù ti ní láti tó wọn lò.—Númérì 2:32; 26:51.
14:21—Kí nìdí táwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi lè fún àtìpó tàbí ọmọ ilẹ̀ òkèèrè ní ẹran tí wọn ò dúńbú nígbà tó jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ò lè jẹ ẹ́? Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ náà, “àtìpó” lè jẹ́ ẹnì kan tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì, àmọ́ tó di aláwọ̀ṣe. Ó tún lè jẹ́ olùtẹ̀dó tó ń pa àwọn òfin pàtàkì ilẹ̀ náà mọ́, àmọ́ tí kò di olùjọsìn Jèhófà. Ọmọ ilẹ̀ òkèèrè tàbí àtìpó tí kò di aláwọ̀ṣe kò sí lábẹ́ Òfin, wọ́n sì lè lo ẹran tí wọn ò dúńbú ní oríṣiríṣi ọ̀nà. Jèhófà fàyè gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti fún wọn ní irú ẹran bẹ́ẹ̀ tàbí kí wọ́n tà á fún wọn. Ní ìdàkejì, aláwọ̀ṣe wà lábẹ́ májẹ̀mú Òfin. Léfítíkù orí kẹtàdínlógún ẹsẹ kẹwàá sọ pé irú ẹni tó jẹ́ aláwọ̀ṣe bẹ́ẹ̀ kò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran.
24:6—Kí nìdí tá a fi fi “fífi ipá gba ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí ọmọ orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò” wé fífi ipá gba “ọkàn?” Ọlọ ọlọ́wọ́ àti ọmọ orí rẹ̀ dúró fún “ọkàn” ẹnì kan tàbí ohun tó ń gbẹ́mìí rẹ̀ ró. Tí wọ́n bá fipá gba èyíkéyìí lára ìwọ̀nyí lọ́wọ́ ìdílé kan, gbogbo ìdílé náà ò ní máa rí oúnjẹ òòjọ́ wọn jẹ.
25:9—Kí ni bíbọ́ sálúbàtà kúrò lẹ́sẹ̀ ẹnì kan tó kọ̀ láti ṣú aya arákùnrin rẹ̀ lópó àti títutọ́ sí i lójú túmọ̀ sí? Níbàámu pẹ̀lú “àṣà ìgbà àtijọ́ ní Ísírẹ́lì nípa ẹ̀tọ́ láti ṣe àtúnrà . . . , ẹnì kan ní láti bọ́ sálúbàtà rẹ̀, kí ó sì fi í fún ẹnì kejì rẹ̀.” (Rúùtù 4:7) Bíbọ́ bàtà kúrò lẹ́sẹ̀ ọkùnrin tó kọ̀ láti ṣú aya arákùnrin rẹ̀ lópó yìí ló fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé ó ti kọ ipò rẹ̀ àti ẹ̀tọ́ tó ní láti bí ọmọ tí yóò jogún arákùnrin rẹ̀ tó ti dolóògbé. Ohun ẹ̀sín nìyẹn jẹ́. (Diutarónómì 25:10) Itọ́ tí wọ́n sì tu sí i lójú jẹ́ láti fi àbùkù kàn án.—Númérì 12:14.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
6:6-9. Bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí Ọlọ́run pàṣẹ fún pé wọ́n gbọ́dọ̀ mọ òfin, àwa náà gbọ́dọ̀ mọ àwọn àṣẹ Ọlọ́run nínú ọkàn wa, ká máa rántí wọn nígbà gbogbo ká sì gbìn wọ́n sínú àwọn ọmọ wa. A gbọ́dọ̀ ‘so wọ́n gẹ́gẹ́ bí àmì mọ́ ọwọ́ wa’ ní ti pé, ìwà wa, tí ọwọ́ wa ṣàpẹẹrẹ, gbọ́dọ̀ fi hàn pé a jẹ́ onígbọràn sí Jèhófà. Àti pé gẹ́gẹ́ bí “ọ̀já ìgbàjú láàárín ojú,” ìgbọràn wa gbọ́dọ̀ hàn kedere sí gbogbo ènìyàn.
6:16. Ǹjẹ́ ká má ṣe dán Jèhófà wò láé bíi tàwọn ọmọ Ísírẹ́lì tí wọ́n fi àìnígbàgbọ́ dán Jèhófà wò ní Másà, níbi tí wọ́n ti kùn nítorí pé kò sí omi.—Ẹ́kísódù 17:1-7.
8:11-18. Ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì lè mú ká gbàgbé Jèhófà.
9:4-6. A gbọ́dọ̀ ṣọ́ra ká má ṣe jẹ́ olódodo lójú ara wa.
13:6. A ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ẹnikẹ́ni fà wá kúrò nínú ìjọsìn Jèhófà.
14:1. Kíkọ ara ẹni lábẹ kò fi ọ̀wọ̀ hàn fún ara ẹ̀dá ènìyàn, ó sì lè ní í ṣe pẹ̀lú ìsìn èké, nítorí náà, a ò gbọ́dọ̀ dá a láṣà. (1 Àwọn Ọba 18:25-28) Nítorí ìrètí àjíǹde tá a ní, kò yẹ ká máa ṣọ̀fọ̀ ẹni tó ti dolóògbé débi tí a ó fi máa kọ ara wa lábẹ.
20:5-7; 24:5. Kódà bí ohun tá à ń ṣe bá tiẹ̀ ṣe pàtàkì gan-an, a gbọ́dọ̀ fi ìgbatẹnirò hàn sí ẹni tó wà ní ipò tó nílò àfiyèsí àrà ọ̀tọ̀.
22:23-27. Ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà tó gbéṣẹ́ jù lọ tí obìnrin kan fi lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ ẹni tó fẹ́ fipá bá a lò pọ̀ ni pé kó lọgun.
“YAN ÌYÈ”
Nínú àsọyé rẹ̀ kẹta, Mósè sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé tí wọ́n bá ti sọdá Jọ́dánì, wọ́n gbọ́dọ̀ kọ Òfin náà sára àwọn òkúta ńláńlá. Ó sọ àwọn ègún tó máa bá wọn tí wọ́n bà ṣàìgbọràn àti àwọn ìbùkún tó máa jẹ́ tiwọn tí wọ́n bá ṣe ìgbọràn. Sísọ májẹ̀mú tó wà láàárín Jèhófà àtàwọn ọmọ Ísírẹ́lì dọ̀tun ló bẹ̀rẹ̀ àsọyé kẹrin. Lẹ́ẹ̀kan sí i, Mósè kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣàìgbọràn ó sì gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “yan ìyè.”—Diutarónómì 30:19.
Láfikún sí àsọyé mẹ́rin tí Mósè sọ, ó sọ ẹni tó máa di aṣáájú nípò rẹ̀ lẹ́yìn tó bá kú. Ó tún kọ́ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní orin aládùn tó wà fún yíyin Jèhófà tó sì kìlọ̀ fún wọn nípa ègún tí dídi aláìṣòótọ́ á yọrí sí. Lẹ́yìn tí Mósè ti súre fún àwọn ẹ̀yà Ísírẹ́lì, ó kú lẹ́ni ọgọ́fà ọdún wọ́n sì sin ín. Ọgbọ̀n ọjọ́ làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣọ̀fọ̀ Mósè, ìyẹn sì fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìdajì àkókò tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ tá a kọ sínú ìwé Diutarónómì fi wáyé.
Ìdáhùn Àwọn Ìbéèrè Nípa Ìwé Mímọ́:
32:13, 14—Níwọ̀n bí a ti ka jíjẹ ọ̀rá léèwọ̀ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, kí ni jíjẹ tí wọ́n jẹ “ọ̀rá àwọn àgbò” túmọ̀ sí? Ọ̀rọ̀ náà “ọ̀rá” tí a lò níhìn-ín la lò lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ ó sì dúró fún ẹran tó dára jù lọ nínú agbo ẹran. Ó hàn gbangba pé ńṣe la lò ó lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ nítorí pé, ẹsẹ yẹn kan náà mẹ́nu kan “ọ̀rá kíndìnrín àlìkámà” àti “ẹ̀jẹ̀ èso àjàrà.”
33:1-29—Kí ló dé tí Mósè ò dárúkọ Síméónì nígbà tó ń súre fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì? Ìdí ni pé Síméónì àti Léfì hùwà “lọ́nà lílekoko,” ìbínú wọn sì “níkà.” (Jẹ́n. 34:13-31; 49:5-7) Ogún wọn ò bá tàwọn ẹ̀yà tó kù dọ́gba. Ìlú ńlá méjìdínláàádọ́ta ni ẹ̀yà Léfì rí gbà, nínú ilẹ̀ tí wọ́n fún Júdà sì ni ẹ̀yà Síméónì ti rí ogún tiwọn gbà. (Jóṣúà 19:9; 21:41, 42) Ìdí nìyẹn tí Mósè ò fi súrè fún Síméónì ní pàtó. Àmọ́ ṣá o, ìre tí Mósè sú fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lápapọ̀ kan Síméónì náà.
Ẹ̀kọ́ Tó Kọ́ Wa:
31:12. Ó yẹ kí àwọn ọmọdé máa jókòó ti àwọn tó dàgbà nípàdé ìjọ, kí wọ́n máa fetí sílẹ̀ kí wọ́n lè kẹ́kọ́ọ̀.
32:4. Gbogbo ìgbòkègbodò Jèhófà ló jẹ́ pípé nítorí pé ó ń fi àwọn ànímọ́ rẹ̀, ìyẹn ìdájọ́ òdodo, ọgbọ́n, ìfẹ́ àti agbára hàn lọ́nà tó wà déédéé, tí ọ̀kan kò pa èkejì lára.
Ìwé Diutarónómì Wúlò Gan-an fún Wa
Ìwé Diutarónómì fi Jèhófà hàn gẹ́gẹ́ bíi “Jèhófà kan ṣoṣo.” (Diutarónómì 6:4) Ó jẹ́ ìwé tó sọ nípa àwọn ènìyàn kan tó ní àjọṣe tó ṣàrà ọ̀tọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run. Ìwé Diutarónómì kìlọ̀ nípa ìbọ̀rìṣà ó sì tẹnu mọ́ ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká fún Ọlọ́run tòótọ́ ní ìfọkànsìn tá a yà sọ́tọ̀ gedegbe.
Dájúdájú, Ìwé Diutarónómì wúlò fún wa gan-an! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé a ò sí lábẹ́ Òfin Mósè, a lè kọ́ ohun púpọ̀ látinú rẹ̀ tí yóò mú ká ‘fi gbogbo ọkàn-àyà wa, gbogbo ọkàn wa àti gbogbo okunra wa nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run wa.’—Diutarónómì 6:5.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó lè jẹ́ pé Jóṣúà tàbí Élíásárì Àlùfáà Àgbà ló fi orí tó gbẹ̀yìn kún ìwé Diutarónómì, ìyẹn orí tó sọ nípa ikú Mósè.
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 24]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
SÉÍRÌ
Kadeṣi-bánéà
Òkè Sínáì (Hórébù)
Òkun Pupa
[Credit Line]
A gbé e ka àwọn àwòrán ilẹ̀ tí ẹ̀tọ́ rẹ̀ jẹ́ ti Pictorial Archive (Near Eastern History) Est. and Survey of Israel
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Àwọn àsọyé tí Mósè sọ ló kó apá tó pọ̀ jù nínú ìwé Diutarónómì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ẹ̀kọ́ wo ni pípèsè tí Jèhófà pèsè mánà kọ́ wa?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
A fi fífi ipá gba ọlọ ọlọ́wọ́ tàbí ọmọ orí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ohun ìdógò wé fífi ipá gba “ọkàn”