Diutarónómì
24 “Tí ọkùnrin kan bá fẹ́ obìnrin kan, àmọ́ tí obìnrin náà ò tẹ́ ẹ lọ́rùn torí ó rí ohun kan tí kò dáa nípa rẹ̀, kó kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un,+ kó fi lé e lọ́wọ́, kó sì ní kó kúrò ní ilé òun.+ 2 Tí obìnrin náà bá ti kúrò ní ilé rẹ̀, ó lè lọ fẹ́ ọkùnrin míì.+ 3 Tí ọkùnrin kejì bá kórìíra rẹ̀,* tó sì kọ ìwé ẹ̀rí ìkọ̀sílẹ̀ fún un, tó fi lé e lọ́wọ́, tó sì ní kó kúrò ní ilé òun tàbí tí ọkùnrin kejì tó fẹ́ ẹ bá kú, 4 ọkọ rẹ̀ àkọ́kọ́ tó lé e kúrò nílé ò ní lè gbà á pa dà mọ́ láti fi ṣe aya lẹ́yìn tó ti di aláìmọ́, torí ohun ìríra ló jẹ́ lójú Jèhófà. O ò gbọ́dọ̀ mú ẹ̀ṣẹ̀ wá sí ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kí o jogún.
5 “Tí ọkùnrin kan bá ṣẹ̀ṣẹ̀ gbéyàwó, kò gbọ́dọ̀ dara pọ̀ mọ́ àwọn ọmọ ogun, wọn ò sì gbọ́dọ̀ yan àwọn iṣẹ́ míì fún un. Kó wà lómìnira fún ọdún kan, kó sì dúró sílé kó lè máa múnú ìyàwó rẹ̀ dùn.+
6 “Ẹnikẹ́ni ò gbọ́dọ̀ gba ọlọ tàbí ọmọ ọlọ láti fi ṣe ìdúró,*+ torí ohun tó ń gbé ẹ̀mí onítọ̀hún ró* ló fẹ́ gbà láti fi ṣe ìdúró yẹn.
7 “Tí ẹ bá rí ẹnì kan tó jí ọ̀kan* lára àwọn arákùnrin rẹ̀ tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì gbé, tó ti fìyà jẹ ẹ́, tó sì ti tà á,+ ṣe ni kí ẹ pa ẹni tó jí èèyàn gbé náà.+ Kí ẹ mú ohun tó burú kúrò láàárín yín.+
8 “Tí àrùn ẹ̀tẹ̀* bá yọ, kí ẹ rí i pé ẹ ṣe gbogbo ohun tí àwọn àlùfáà tó jẹ́ ọmọ Léfì bá ní kí ẹ ṣe.+ Kí ẹ rí i pé ẹ ṣe ohun tí mo pa láṣẹ fún wọn gẹ́lẹ́. 9 Ẹ rántí ohun tí Jèhófà Ọlọ́run yín ṣe sí Míríámù lójú ọ̀nà, nígbà tí ẹ kúrò ní Íjíbítì.+
10 “Tí o bá yá ọmọnìkejì rẹ ní ohunkóhun,+ o ò gbọ́dọ̀ wọ inú ilé lọ bá a láti gba ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró. 11 Ìta ni kí o dúró sí, kí ẹni tí o yá ní nǹkan mú ohun tó fẹ́ fi ṣe ìdúró wá bá ọ níta. 12 Tí ẹni náà bá sì jẹ́ aláìní, ohun tó fi ṣe ìdúró ò gbọ́dọ̀ sun ọ̀dọ̀ rẹ mọ́jú.+ 13 Gbàrà tí oòrùn bá wọ̀ ni kí o rí i pé o dá ohun tó fi ṣe ìdúró pa dà fún un, kó lè rí aṣọ fi sùn,+ á sì súre fún ọ; èyí á sì jẹ́ òdodo lójú Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
14 “O ò gbọ́dọ̀ rẹ́ alágbàṣe tó jẹ́ aláìní àti tálákà jẹ, ì báà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn arákùnrin rẹ tàbí àjèjì tó wà ní ilẹ̀ rẹ, nínú àwọn ìlú* rẹ.+ 15 Ọjọ́ yẹn gan-an ni kí o fún un ní owó iṣẹ́ rẹ̀,+ kí oòrùn tó wọ̀, torí pé aláìní ni, owó iṣẹ́ yìí ló sì ń gbé ẹ̀mí* rẹ̀ ró. Àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, ó máa fi ẹjọ́ rẹ sun Jèhófà, wàá sì jẹ̀bi ẹ̀ṣẹ̀.+
16 “Ẹ má pa àwọn bàbá torí ohun tí àwọn ọmọ wọn ṣe, ẹ má sì pa àwọn ọmọ torí ohun tí àwọn bàbá wọn ṣe.+ Kí a pa kálukú nítorí ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.+
17 “O ò gbọ́dọ̀ ṣe èrú tí o bá ń dá ẹjọ́ àjèjì tàbí ọmọ aláìníbaba,*+ o ò sì gbọ́dọ̀ gba aṣọ opó láti fi ṣe ìdúró.*+ 18 Rántí pé o di ẹrú ní Íjíbítì, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì rà ọ́ pa dà kúrò níbẹ̀.+ Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe èyí.
19 “Tí o bá kórè oko rẹ, tí o sì gbàgbé ìtí ọkà kan sínú oko, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ gbé e. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó,+ kí Jèhófà Ọlọ́run rẹ lè máa bù kún ọ nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe.+
20 “Tí o bá lu igi ólífì rẹ, o ò gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ sí àwọn ẹ̀ka rẹ̀. Kí o fi ohun tó bá ṣẹ́ kù sílẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó.+
21 “Tí o bá kórè èso àjàrà inú ọgbà rẹ, o ò gbọ́dọ̀ pa dà lọ kó àwọn èso tó bá ṣẹ́ kù. Fi sílẹ̀ níbẹ̀ fún àjèjì, ọmọ aláìníbaba àti opó. 22 Rántí pé o di ẹrú ní ilẹ̀ Íjíbítì. Ìdí nìyẹn tí mo fi ń pàṣẹ fún ọ pé kí o ṣe èyí.