Àwọn Ọba Kìíní
20 Nígbà náà, Bẹni-hádádì+ ọba Síríà+ kó gbogbo àwọn ọmọ ogun rẹ̀ jọ àti àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) pẹ̀lú àwọn ẹṣin àti àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin wọn; ó jáde lọ, ó dó ti+ Samáríà,+ ó sì gbéjà kò ó. 2 Lẹ́yìn náà, ó rán àwọn òjíṣẹ́ sí Áhábù+ ọba Ísírẹ́lì nínú ìlú náà, wọ́n sì sọ fún un pé: “Ohun tí Bẹni-hádádì sọ nìyí, 3 ‘Fàdákà àti wúrà rẹ jẹ́ tèmi, àwọn ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ tó dára jù lọ sì jẹ́ tèmi.’” 4 Ọba Ísírẹ́lì bá fèsì pé: “Olúwa mi ọba, bí o ṣe sọ, èmi àti gbogbo ohun tí mo ní jẹ́ tìrẹ.”+
5 Nígbà tó yá, àwọn òjíṣẹ́ náà pa dà wá, wọ́n sọ pé: “Ohun tí Bẹni-hádádì sọ nìyí, ‘Mo ránṣẹ́ sí ọ pé: “Kí o fún mi ní fàdákà rẹ àti wúrà rẹ àti àwọn ìyàwó rẹ pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ.” 6 Àmọ́ ní ìwòyí ọ̀la, màá rán àwọn ìránṣẹ́ mi sí ọ, wọn á sì fara balẹ̀ wá inú ilé rẹ àti ilé àwọn ìránṣẹ́ rẹ, gbogbo nǹkan rẹ tó ṣeyebíye ni wọ́n á gbà, tí wọ́n á sì kó lọ.’”
7 Ni ọba Ísírẹ́lì bá pe gbogbo àwọn àgbààgbà ilẹ̀ náà, ó sì sọ pé: “Ṣé ẹ rí i pé wàhálà ni ọkùnrin yìí fẹ́ dá sílẹ̀, ó ní kí n fún òun ní àwọn ìyàwó mi, àwọn ọmọ mi, fàdákà mi àti wúrà mi, mi ò sì jiyàn.” 8 Gbogbo àwọn àgbààgbà àti gbogbo àwọn èèyàn náà wá sọ fún un pé: “Má dá a lóhùn, má sì gbà fún un.” 9 Torí náà, ó sọ fún àwọn òjíṣẹ́ Bẹni-hádádì pé: “Ẹ sọ fún olúwa mi ọba pé, ‘Gbogbo ohun tí o kọ́kọ́ béèrè lọ́wọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni màá ṣe, àmọ́ ní ti eléyìí, mi ò lè ṣe é.’” Àwọn òjíṣẹ́ náà bá gbéra, wọ́n sì lọ jíṣẹ́ fún un.
10 Bẹni-hádádì wá ránṣẹ́ sí i pé: “Kí àwọn ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an tí iyẹ̀pẹ̀ tó máa ṣẹ́ kù sí Samáríà bá máa kún ọwọ́ àwọn tó tẹ̀ lé mi!” 11 Ọba Ísírẹ́lì dáhùn pé: “Ẹ sọ fún un pé, ‘Kí ẹni tó ń dira ogun má ṣe fọ́nnu bí ẹni tó ti togun dé.’”+ 12 Gbàrà tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ yìí, bí òun àti àwọn ọba ṣe ń mutí nínú àwọn àgọ́* wọn, ó sọ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé: “Ẹ gbára dì!” Torí náà, wọ́n gbára dì láti gbéjà ko ìlú náà.
13 Àmọ́ wòlíì kan wá bá Áhábù+ ọba Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Ṣé o rí gbogbo èèyàn rẹpẹtẹ yìí? Màá fi wọ́n lé ọ lọ́wọ́ lónìí, wàá sì mọ̀ pé èmi ni Jèhófà.’”+ 14 Áhábù bá béèrè pé: “Ta ló máa lò?” ó fèsì pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀* ni.’” Torí náà, ó béèrè pé: “Ta ló máa kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ ogun náà?” ó fèsì pé: “Ìwọ ni!”
15 Áhábù wá ka iye àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀, wọ́n jẹ́ igba ó lé méjìlélọ́gbọ̀n (232); lẹ́yìn náà, ó ka gbogbo àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì, wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún méje (7,000). 16 Wọ́n jáde lọ ní ọ̀sán gangan nígbà tí Bẹni-hádádì ti rọ ara rẹ̀ yó nínú àwọn àgọ́* pẹ̀lú àwọn ọba méjìlélọ́gbọ̀n (32) tó ń ràn án lọ́wọ́. 17 Nígbà tí àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ kọ́kọ́ jáde, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Bẹni-hádádì rán àwọn òjíṣẹ́ rẹ̀, wọ́n sì pa dà wá ròyìn fún un pé: “Àwọn ọkùnrin kan ti wá láti Samáríà.” 18 Ni ó bá sọ pé: “Tó bá jẹ́ àlàáfíà ni wọ́n bá wá, ẹ mú wọn láàyè; tó bá sì jẹ́ pé ogun ni wọ́n bá wá, ẹ mú wọn láàyè.” 19 Àmọ́ nígbà tí àwọn yìí jáde wá láti inú ìlú, ìyẹn àwọn ìránṣẹ́ àwọn olórí tó wà ní àwọn ìpínlẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun tó ń tẹ̀ lé wọn, 20 kálukú pa ẹni tó dojú kọ ọ́. Ni àwọn ará Síríà bá fẹsẹ̀ fẹ,+ Ísírẹ́lì sì gbá tẹ̀ lé wọn, àmọ́ Bẹni-hádádì ọba Síríà gun ẹṣin sá lọ pẹ̀lú àwọn kan lára àwọn agẹṣin. 21 Àmọ́ ọba Ísírẹ́lì jáde lọ, ó ń ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá tó ń gun ẹṣin àti àwọn tó wà lórí kẹ̀kẹ́ ẹṣin, ó sì ṣẹ́gun àwọn ará Síríà lọ́nà tó kàmàmà.*
22 Nígbà tó yá, wòlíì náà+ wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, ó sọ fún un pé: “Lọ gbára dì, kí o sì ro ohun tí o máa ṣe,+ torí ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún* tó ń bọ̀, ọba Síríà máa wá gbéjà kò ọ́.”+
23 Nígbà náà, àwọn ìránṣẹ́ ọba Síríà sọ fún un pé: “Ọlọ́run wọn jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè. Ìdí nìyẹn tí wọ́n fi borí wa. Àmọ́, tí a bá bá wọn jà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, a ó borí wọn. 24 Ohun tí o tún máa ṣe ni pé: Yọ àwọn ọba kúrò+ ní ipò wọn, kí o sì fi àwọn gómìnà rọ́pò wọn. 25 Lẹ́yìn náà, kó* àwọn ọmọ ogun tí iye wọn jẹ́ iye ọmọ ogun tí o pàdánù jọ àti àwọn ẹṣin pẹ̀lú àwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin tí iye wọn jẹ́ iye tí o ti pàdánù. Jẹ́ kí a bá wọn jà lórí ilẹ̀ tó tẹ́jú, ó dájú pé a máa borí wọn.” Torí náà, ó gba ìmọ̀ràn tí wọ́n fún un, ó sì ṣe ohun tí wọ́n sọ.
26 Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún,* Bẹni-hádádì kó àwọn ará Síríà jọ, ó sì lọ sí Áfékì+ láti bá Ísírẹ́lì jà. 27 Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì náà kóra jọ, a pèsè nǹkan fún wọn, wọ́n sì jáde lọ pàdé wọn. Nígbà tí àwọn èèyàn Ísírẹ́lì dó síwájú wọn, wọ́n dà bí agbo ewúrẹ́ méjì tó kéré, àmọ́ àwọn ará Síríà gba gbogbo ilẹ̀ kan.+ 28 Ìgbà náà ni èèyàn Ọlọ́run tòótọ́ sún mọ́ ọba Ísírẹ́lì, ó sọ pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Nítorí àwọn ará Síríà sọ pé: “Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run àwọn òkè, kì í ṣe Ọlọ́run pẹ̀tẹ́lẹ̀,” màá fi gbogbo èèyàn rẹpẹtẹ yìí lé ọ lọ́wọ́,+ wàá sì mọ̀ dájú pé èmi ni Jèhófà.’”+
29 Ọjọ́ méje ni wọ́n fi wà ní ibùdó, àwùjọ méjèèjì sì dojú kọra. Ní ọjọ́ keje, ìjà náà bẹ̀rẹ̀. Àwọn èèyàn Ísírẹ́lì pa ọ̀kẹ́ márùn-ún (100,000) àwọn ọmọ ogun Síríà tó ń fẹsẹ̀ rìn, ní ọjọ́ kan. 30 Àwọn tó ṣẹ́ kù sá lọ sí Áfékì,+ sínú ìlú náà. Àmọ́ ògiri wó lu ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n (27,000) ọkùnrin tó ṣẹ́ kù. Bẹni-hádádì náà fẹsẹ̀ fẹ, ó sì wá sínú ìlú náà, ó wá fara pa mọ́ sínú yàrá inú.
31 Nítorí náà, àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé: “Wò ó, a ti gbọ́ pé àwọn ọba ilé Ísírẹ́lì máa ń lójú àánú.* Jọ̀wọ́, jẹ́ ká sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìdí, kí a wé okùn mọ́ orí wa, kí a sì jáde lọ bá ọba Ísírẹ́lì. Bóyá ó máa dá ẹ̀mí* rẹ sí.”+ 32 Torí náà, wọ́n sán aṣọ ọ̀fọ̀* mọ́ ìdí, wọ́n wé okùn mọ́ orí, wọ́n sì wá sọ́dọ̀ ọba Ísírẹ́lì, wọ́n sọ pé: “Ìránṣẹ́ rẹ Bẹni-hádádì sọ pé, ‘Jọ̀wọ́, dá ẹ̀mí* mi sí.’” Ó fèsì pé: “Ṣé ó ṣì wà láàyè? Arákùnrin mi ni.” 33 Àwọn ọkùnrin náà kà á sí àmì, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n sì gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, torí náà wọ́n sọ pé: “Arákùnrin rẹ ni Bẹni-hádádì.” Ni ó bá sọ pé: “Ẹ lọ mú un wá.” Lẹ́yìn náà, Bẹni-hádádì jáde wá bá a, ó sì ní kí ó gòkè sínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin.
34 Bẹni-hádádì wá sọ fún un pé: “Màá dá àwọn ìlú tí bàbá mi gbà lọ́wọ́ bàbá rẹ pa dà, kí o lè kọ́ àwọn ilé ìtajà sí* Damásíkù, bí bàbá mi ti ṣe ní Samáríà.”
Áhábù fèsì pé: “Nítorí àdéhùn* yìí, màá jẹ́ kí o lọ.”
Lẹ́yìn náà, ó bá a ṣàdéhùn, ó sì jẹ́ kí ó lọ.
35 Jèhófà bá ọ̀kan lára àwọn ọmọ wòlíì* sọ̀rọ̀,+ ni ó bá sọ fún ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Àmọ́ ọkùnrin náà kọ̀, kò lù ú. 36 Nítorí náà, ó sọ fún un pé: “Torí pé o kò ṣègbọràn sí ohùn Jèhófà, gbàrà tí o bá ti kúrò lọ́dọ̀ mi, kìnnìún yóò pa ọ.”* Lẹ́yìn tí ó kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, kìnnìún kan yọ sí i, ó sì pa á.
37 Ó rí ọkùnrin míì, ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, lù mí.” Torí náà, ọkùnrin náà lù ú, ó sì ṣe é léṣe.
38 Wòlíì náà wá lọ dúró de ọba lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà, ó sì fi ọ̀já tí wọ́n fi ń di ọgbẹ́ bo ojú, kí wọ́n má bàa dá a mọ̀. 39 Bí ọba ṣe ń kọjá lọ, ó ké sí ọba pé: “Ìránṣẹ́ rẹ jáde lọ sí ibi tí ogun ti le, ọkùnrin kan ń jáde bọ̀ tó mú ọkùnrin mìíràn wá bá mi, ó sì sọ pé, ‘Máa ṣọ́ ọkùnrin yìí. Tí ó bá sá lọ, tálẹ́ńtì* fàdákà kan ni wàá san tàbí kí o fi ẹ̀mí rẹ dí ẹ̀mí rẹ̀.’*+ 40 Àmọ́ nígbà tí ọwọ́ èmi ìránṣẹ́ rẹ dí gan-an, kí n tó mọ̀, ọkùnrin náà ti lọ.” Ọba Ísírẹ́lì wá sọ fún un pé: “Bí ìdájọ́ rẹ ṣe máa rí náà nìyẹn; o ti fúnra rẹ ṣèdájọ́.” 41 Ni ó bá tètè yọ ọ̀já tí wọ́n fi ń di ọgbẹ́ kúrò lójú rẹ̀, ọba Ísírẹ́lì wá dá a mọ̀ pé ọ̀kan lára àwọn wòlíì ni.+ 42 Ó sọ fún un pé: “Ohun tí Jèhófà sọ nìyí, ‘Nítorí o jẹ́ kí ọkùnrin tí mo ní ikú tọ́ sí sá mọ́ ọ lọ́wọ́,+ ẹ̀mí rẹ ló máa dí ẹ̀mí rẹ̀,*+ àwọn èèyàn rẹ á sì dípò àwọn èèyàn rẹ̀.’”+ 43 Ni ọba Ísírẹ́lì bá lọ sí ilé rẹ̀ ní Samáríà,+ ó dì kunkun, ó sì dorí kodò.