Ẹ́sírà
10 Bí Ẹ́sírà ṣe ń gbàdúrà,+ tó sì ń jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ lọ́wọ́, tó ń sunkún, tó sì dojú bolẹ̀ níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lọ́kùnrin, lóbìnrin àti àwọn ọmọdé ní Ísírẹ́lì kóra jọ sọ́dọ̀ rẹ̀, àwọn èèyàn náà sì ń sunkún pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀. 2 Ni Ṣẹkanáyà ọmọ Jéhíélì+ látinú àwọn ọmọ Élámù+ bá sọ fún Ẹ́sírà pé: “A ti hùwà àìṣòótọ́ sí Ọlọ́run wa, bí a ṣe fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì* láàárín àwọn èèyàn ilẹ̀ tó yí wa ká.+ Síbẹ̀ náà, ìrètí ṣì wà fún Ísírẹ́lì. 3 Ní báyìí, jẹ́ ká bá Ọlọ́run wa dá májẹ̀mú+ pé a máa lé gbogbo àwọn aya náà lọ àti àwọn ọmọ tí wọ́n bí, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ tí Jèhófà pa àti ohun tí àwọn tó ní ọ̀wọ̀* fún àṣẹ Ọlọ́run wa sọ.+ Ká ṣe ohun tí Òfin sọ. 4 Dìde, torí ìwọ lo ni iṣẹ́ yìí, a sì wà pẹ̀lú rẹ. Jẹ́ onígboyà, kí o sì gbé ìgbésẹ̀.”
5 Ni Ẹ́sírà bá dìde, ó sì ní kí àwọn tó jẹ́ olórí láàárín àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì àti gbogbo Ísírẹ́lì búra láti ṣe ohun tí wọ́n sọ.+ Torí náà, wọ́n búra. 6 Ẹ́sírà wá dìde kúrò níwájú ilé Ọlọ́run tòótọ́, ó sì lọ sínú yàrá* Jèhóhánánì ọmọ Élíáṣíbù nínú tẹ́ńpìlì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó lọ síbẹ̀, kò jẹun, kò sì mu omi, torí ó ń ṣọ̀fọ̀ lórí ìwà àìṣòótọ́ àwọn tó dé láti ìgbèkùn.+
7 Lẹ́yìn náà, wọ́n kéde káàkiri Júdà àti Jerúsálẹ́mù pé kí gbogbo àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù; 8 ẹnikẹ́ni tí kò bá sì wá láàárín ọjọ́ mẹ́ta, a ó gba* gbogbo ẹrù rẹ̀, a ó sì lé e kúrò ní àwùjọ àwọn tó dé láti ìgbèkùn, gẹ́gẹ́ bí ìpinnu tí àwọn olórí àti àwọn àgbààgbà ṣe.+ 9 Nítorí náà, gbogbo àwọn èèyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì kóra jọ sí Jerúsálẹ́mù láàárín ọjọ́ mẹ́ta, ìyẹn ní oṣù kẹsàn-án, ní ogúnjọ́ oṣù náà. Gbogbo àwọn èèyàn náà jókòó sí àgbàlá ilé Ọlọ́run tòótọ́, wọ́n ń gbọ̀n nítorí ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ àti nítorí òjò ńlá tó ń rọ̀.
10 Nígbà náà, àlùfáà Ẹ́sírà dìde, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti hùwà àìṣòótọ́ bí ẹ ṣe lọ ń fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì,+ ẹ sì ti dá kún ẹ̀ṣẹ̀ Ísírẹ́lì. 11 Ní báyìí, ẹ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ yín fún Jèhófà Ọlọ́run àwọn baba ńlá yín, kí ẹ sì ṣe ohun tí ó fẹ́. Ẹ ya ara yín sọ́tọ̀ kúrò nínú àwọn èèyàn ilẹ̀ náà àti kúrò lọ́dọ̀ àwọn aya àjèjì.”+ 12 Gbogbo ìjọ náà wá dáhùn ní ohùn tó ròkè pé: “Ojúṣe wa ni láti ṣe ohun tí o sọ. 13 Àmọ́, àwọn èèyàn náà pọ̀, àsìkò òjò sì ni. Èèyàn ò lè dúró níta, ọ̀rọ̀ náà kì í sì í ṣe ohun tí a lè parí lọ́jọ́ kan tàbí méjì, nítorí a ti ṣọ̀tẹ̀ gan-an nínú ọ̀ràn yìí. 14 Ní báyìí, jọ̀wọ́, jẹ́ kí àwọn olórí wa ṣojú fún gbogbo ìjọ yìí;+ kí gbogbo àwọn tó wà nínú àwọn ìlú wa tí wọ́n ti fẹ́ àwọn aya àjèjì sì jáde wá ní àkókò tí a dá pẹ̀lú àwọn àgbààgbà àti àwọn onídàájọ́ ìlú kọ̀ọ̀kan, títí a ó fi yí ìbínú Ọlọ́run wa tó ń jó bí iná kúrò lórí wa, nítorí ọ̀ràn yìí.”
15 Àmọ́, Jónátánì ọmọ Ásáhélì àti Jaseáyà ọmọ Tíkífà ta ko ọ̀rọ̀ yìí, Méṣúlámù àti Ṣábétáì+ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Léfì sì tì wọ́n lẹ́yìn. 16 Ṣùgbọ́n àwọn tó wà nígbèkùn tẹ́lẹ̀ ṣe ohun tí wọ́n fẹnu kò sí; àlùfáà Ẹ́sírà àti àwọn olórí ìdílé nínú àwọn agbo ilé bàbá wọn, tí orúkọ wọn wà lákọsílẹ̀, kóra jọ lọ́tọ̀ ní ọjọ́ kìíní oṣù kẹwàá láti bójú tó ọ̀rọ̀ náà; 17 nígbà tó di ọjọ́ kìíní oṣù kìíní, wọ́n yanjú ọ̀rọ̀ gbogbo àwọn ọkùnrin tó fẹ́ àwọn obìnrin àjèjì. 18 A sì wá rí i pé lára àwọn ọmọ àlùfáà ti fẹ́ àwọn aya àjèjì,+ àwọn ni: látinú àwọn ọmọ Jéṣúà+ ọmọ Jèhósádákì àti àwọn arákùnrin rẹ̀, Maaseáyà, Élíésérì, Járíbù àti Gẹdaláyà. 19 Àmọ́, wọ́n ṣèlérí* pé àwọn máa lé àwọn aya wọn lọ, bákan náà, torí pé wọ́n jẹ̀bi, wọ́n máa fi àgbò kan látinú agbo ẹran rúbọ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ wọn.+
20 Látinú àwọn ọmọ Ímérì,+ Hánáánì àti Sebadáyà; 21 látinú àwọn ọmọ Hárímù,+ Maaseáyà, Èlíjà, Ṣemáyà, Jéhíélì àti Ùsáyà; 22 látinú àwọn ọmọ Páṣúrì,+ Élíóénáì, Maaseáyà, Íṣímáẹ́lì, Nétánélì, Jósábádì àti Éléásà. 23 Látinú àwọn ọmọ Léfì, Jósábádì, Ṣíméì, Keláyà (ìyẹn, Kélítà), Petaháyà, Júdà àti Élíésérì; 24 látinú àwọn akọrin, Élíáṣíbù; látinú àwọn aṣọ́bodè, Ṣálúmù, Télémù àti Úráì.
25 Látinú Ísírẹ́lì, nínú àwọn ọmọ Páróṣì,+ Ramáyà, Isáyà, Málíkíjà, Míjámínì, Élíásárì, Málíkíjà àti Bẹnáyà; 26 látinú àwọn ọmọ Élámù,+ Matanáyà, Sekaráyà, Jéhíélì,+ Ábídì, Jérémótì àti Èlíjà; 27 látinú àwọn ọmọ Sátù,+ Élíóénáì, Élíáṣíbù, Matanáyà, Jérémótì, Sábádì àti Ásísà; 28 látinú àwọn ọmọ Bébáì,+ Jèhóhánánì, Hananáyà, Sábáì àti Átíláì; 29 látinú àwọn ọmọ Bánì, Méṣúlámù, Málúkù, Ádáyà, Jáṣúbù, Ṣéálì àti Jérémótì; 30 látinú àwọn ọmọ Pahati-móábù,+ Ádúnà, Kélálì, Bẹnáyà, Maaseáyà, Matanáyà, Bẹ́sálẹ́lì, Bínúì àti Mánásè; 31 látinú àwọn ọmọ Hárímù,+ Élíésérì, Isiṣíjà, Málíkíjà,+ Ṣemáyà, Ṣíméónì, 32 Bẹ́ńjámínì, Málúkù àti Ṣemaráyà; 33 látinú àwọn ọmọ Háṣúmù,+ Máténáì, Mátáátà, Sábádì, Élífélétì, Jérémáì, Mánásè àti Ṣíméì; 34 látinú àwọn ọmọ Bánì, Máádáì, Ámúrámù, Yúẹ́lì, 35 Bẹnáyà, Bedeáyà, Kélúhì, 36 Fanáyà, Mérémótì, Élíáṣíbù, 37 Matanáyà, Máténáì àti Jáásù; 38 látinú àwọn ọmọ Bínúì, Ṣíméì, 39 Ṣelemáyà, Nátánì, Ádáyà, 40 Makinádébáì, Ṣáṣáì, Ṣáráì, 41 Ásárẹ́lì, Ṣelemáyà, Ṣemaráyà, 42 Ṣálúmù, Amaráyà àti Jósẹ́fù; 43 látinú àwọn ọmọ Nébò, Jéélì, Matitáyà, Sábádì, Sébínà, Jádáì, Jóẹ́lì àti Bẹnáyà. 44 Gbogbo àwọn yìí ni wọ́n fẹ́ àwọn aya àjèjì,+ wọ́n sì lé àwọn aya wọn lọ pẹ̀lú àwọn ọmọ wọn.+