Sáàmù
Sí olùdarí. Ti àwọn ọmọ Kórà.+ Másíkílì.*
44 Ọlọ́run, a ti fi etí wa gbọ́,
Àwọn baba ńlá wa ti ròyìn fún wa,+
Àwọn ohun tí o ṣe nígbà ayé wọn,
Ní àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́.
O fọ́ àwọn orílẹ̀-èdè, o sì lé wọn jáde.+
7 Ìwọ lo gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa,+
Ìwọ lo sì kó ìtìjú bá àwọn tó kórìíra wa.
8 A ó máa yin Ọlọ́run láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,
A ó sì máa fi ọpẹ́ fún orúkọ rẹ títí láé. (Sélà)
9 Àmọ́ ní báyìí, o ti ta wá nù, o ti kó ìtìjú bá wa,
O ò sì bá àwọn ọmọ ogun wa jáde.
10 Ò ń mú kí a sá pa dà níwájú àwọn ọ̀tá wa;+
Àwọn tó kórìíra wa ń kó ohun tí wọ́n fẹ́.
11 O fi wá lé wọn lọ́wọ́ kí wọ́n lè pa wá jẹ bí àgùntàn;
O ti tú wa ká sáàárín àwọn orílẹ̀-èdè.+
13 O sọ wá di ẹni ẹ̀gàn lójú àwọn aládùúgbò wa,
Ẹni ẹ̀sín àti ẹni yẹ̀yẹ́ lójú àwọn tó yí wa ká.
15 Ẹ̀tẹ́ bá mi láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,
Ìtìjú mi sì ti bò mí mọ́lẹ̀,
16 Torí ẹ̀sín tí wọ́n ń fi mí ṣe àti èébú wọn,
Nítorí pé ọ̀tá wa ń gbẹ̀san lára wa.
17 Gbogbo èyí ti ṣẹlẹ̀ sí wa, síbẹ̀ a kò gbàgbé rẹ,
A kò sì da májẹ̀mú rẹ.+
18 Ọkàn wa kò kúrò lọ́dọ̀ rẹ;
Ẹsẹ̀ wa kò yà kúrò ní ọ̀nà rẹ.
20 Ká ní a ti gbàgbé orúkọ Ọlọ́run wa
Tàbí tí a tẹ́wọ́ àdúrà sí ọlọ́run àjèjì,
21 Ṣé Ọlọ́run kò ní mọ̀ ni?
Ó mọ àwọn àṣírí tó wà nínú ọkàn.+
22 Torí rẹ ni wọ́n ṣe ń pa wá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀;
Wọ́n ti kà wá sí àgùntàn tó wà fún pípa.+
23 Dìde. Kí ló dé tí o ṣì fi ń sùn, Jèhófà?+
Jí! Má ṣe ta wá nù títí láé.+
24 Kí ló dé tí o fi fojú rẹ pa mọ́?
Kí ló dé tí o fi gbàgbé ìyà tó ń jẹ wá àti ìnira tó bá wa?
26 Dìde nítorí ìwọ ni olùrànlọ́wọ́ wa!+