Jóṣúà
24 Jóṣúà wá kó gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì jọ sí Ṣékémù, ó pe àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì, àwọn olórí wọn, àwọn onídàájọ́ àti àwọn aṣojú,+ wọ́n sì dúró síwájú Ọlọ́run tòótọ́. 2 Jóṣúà sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ohun tí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì sọ nìyí, ‘Òdìkejì Odò* ni àwọn baba ńlá yín+ gbé ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn,+ ìyẹn Térà bàbá Ábúráhámù àti bàbá Náhórì, àwọn ọlọ́run míì ni wọ́n sì jọ́sìn.+
3 “‘Nígbà tó yá, mo mú Ábúráhámù + baba ńlá yín láti òdìkejì Odò,* mo mú kó rin gbogbo ilẹ̀ Kénáánì já, mo sì sọ àwọn ọmọ* rẹ̀ di púpọ̀.+ Mo fún un ní Ísákì;+ 4 mo sì fún Ísákì ní Jékọ́bù àti Ísọ̀.+ Lẹ́yìn náà, mo fún Ísọ̀ ní Òkè Séírì pé kó di tirẹ̀;+ Jékọ́bù àti àwọn ọmọ rẹ̀ sì lọ sí Íjíbítì.+ 5 Nígbà tó yá, mo rán Mósè àti Áárónì,+ mo sì fi ohun tí mo ṣe láàárín wọn mú ìyọnu bá Íjíbítì,+ mo sì mú yín jáde. 6 Nígbà tí mo mú àwọn bàbá yín kúrò ní Íjíbítì,+ tí ẹ sì dé òkun, àwọn ará Íjíbítì ń fi àwọn kẹ̀kẹ́ ogun àti àwọn agẹṣin lé àwọn bàbá yín títí dé Òkun Pupa.+ 7 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ké pe Jèhófà,+ ó wá fi òkùnkùn sáàárín ẹ̀yin àti àwọn ará Íjíbítì, ó mú kí òkun ya wá sórí wọn, ó bò wọ́n mọ́lẹ̀,+ ẹ sì fi ojú ara yín rí ohun tí mo ṣe ní Íjíbítì.+ Ọ̀pọ̀ ọdún* lẹ fi wà ní aginjù.+
8 “‘Mo mú yín wá sí ilẹ̀ àwọn Ámórì tí wọ́n ń gbé ní òdìkejì* Jọ́dánì, wọ́n sì bá yín jà.+ Àmọ́ mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́, kí ẹ lè gba ilẹ̀ wọn, mo sì pa wọ́n run kúrò níwájú yín.+ 9 Bálákì ọmọ Sípórì, ọba Móábù sì dìde, ó bá Ísírẹ́lì jà. Torí náà, ó ránṣẹ́ pe Báláámù ọmọ Béórì pé kó wá gégùn-ún fún yín.+ 10 Àmọ́ mi ò fetí sí Báláámù.+ Torí náà, ó súre fún yín léraléra,+ mo sì gbà yín lọ́wọ́ rẹ̀.+
11 “‘Lẹ́yìn náà, ẹ sọdá Jọ́dánì,+ ẹ sì dé Jẹ́ríkò.+ Àwọn olórí* ìlú Jẹ́ríkò, àwọn Ámórì, àwọn Pérísì, àwọn ọmọ Kénáánì, àwọn ọmọ Hétì, àwọn Gẹ́gáṣì, àwọn Hífì àti àwọn ará Jébúsì bá yín jà, àmọ́ mo fi wọ́n lé yín lọ́wọ́.+ 12 Torí náà, mo mú kí àwọn èèyàn rẹ̀wẹ̀sì* kí ẹ tó dé ọ̀dọ̀ wọn, ìyẹn sì mú kí wọ́n sá kúrò níwájú yín,+ ìyẹn ọba Ámórì méjèèjì. Kì í ṣe idà yín tàbí ọfà yín ló ṣe èyí.+ 13 Mo wá fún yín ní ilẹ̀ tí ẹ ò ṣiṣẹ́ fún àti àwọn ìlú tí ẹ ò kọ́,+ ẹ sì ń gbé inú wọn. Ẹ tún ń jẹ àwọn èso ọgbà àjàrà àti àwọn èso igi ólífì tí ẹ ò gbìn.’+
14 “Torí náà, ẹ bẹ̀rù Jèhófà, kí ẹ sì máa fi ìwà títọ́* àti òótọ́ inú* sìn ín,+ kí ẹ mú àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní òdìkejì Odò* àti ní Íjíbítì kúrò,+ kí ẹ sì máa sin Jèhófà. 15 Àmọ́ tó bá dà bíi pé ó burú lójú yín láti máa sin Jèhófà, ẹ fúnra yín yan ẹni tí ẹ fẹ́ máa sìn lónìí,+ bóyá àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín sìn ní òdìkejì Odò*+ tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì tí ẹ̀ ń gbé ní ilẹ̀ wọn.+ Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.”
16 Àwọn èèyàn náà dáhùn pé: “Kò ṣeé gbọ́ pé a fi Jèhófà sílẹ̀, a wá lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì. 17 Jèhófà Ọlọ́run wa ló mú àwa àti àwọn bàbá wa kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì,+ kúrò ní ilé ẹrú,+ òun ló ṣe àwọn iṣẹ́ àmì tó kàmàmà yìí níṣojú wa,+ tó sì ń ṣọ́ wa ní gbogbo ọ̀nà tí a rìn àti lọ́dọ̀ gbogbo àwọn èèyàn tí a gba àárín wọn kọjá.+ 18 Jèhófà lé gbogbo àwọn èèyàn náà kúrò, títí kan àwọn Ámórì, tí wọ́n ń gbé ilẹ̀ náà ṣáájú wa. Torí náà, Jèhófà ni àwa náà máa sìn, torí òun ni Ọlọ́run wa.”
19 Jóṣúà wá sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ ò lè sin Jèhófà, torí pé Ọlọ́run mímọ́ ni;+ Ọlọ́run tó fẹ́ kí a máa jọ́sìn òun nìkan ṣoṣo ni.+ Kò ní dárí àwọn ìṣìnà* àtàwọn ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín.+ 20 Tí ẹ bá fi Jèhófà sílẹ̀, tí ẹ sì ń sin àwọn ọlọ́run àjèjì, òun náà máa kẹ̀yìn sí yín, ó sì máa pa yín run lẹ́yìn tó ti ṣe ohun rere fún yín.”+
21 Àmọ́ àwọn èèyàn náà sọ fún Jóṣúà pé: “Rárá o, Jèhófà la máa sìn!”+ 22 Torí náà, Jóṣúà sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ̀yin ni ẹlẹ́rìí lòdì sí ara yín pé, ẹ̀yin fúnra yín lẹ pinnu pé Jèhófà lẹ máa sìn.”+ Wọ́n fèsì pé: “Àwa ni ẹlẹ́rìí.”
23 “Torí náà, ẹ mú àwọn ọlọ́run àjèjì tó wà láàárín yín kúrò, kí ẹ sì yí ọkàn yín sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì.” 24 Àwọn èèyàn náà sọ fún Jóṣúà pé: “Jèhófà Ọlọ́run wa la máa sìn, ohùn rẹ̀ la ó sì máa fetí sí!”
25 Jóṣúà wá bá àwọn èèyàn náà dá májẹ̀mú ní ọjọ́ yẹn, ó sì fi ìlànà àti òfin lélẹ̀ fún wọn ní Ṣékémù. 26 Jóṣúà wá kọ ọ̀rọ̀ yìí sínú ìwé Òfin Ọlọ́run,+ ó gbé òkúta ńlá kan,+ ó sì gbé e kalẹ̀ sábẹ́ igi ńlá tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi mímọ́ Jèhófà.
27 Jóṣúà sì sọ fún gbogbo àwọn èèyàn náà pé: “Ẹ wò ó! Òkúta yìí máa jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí wa,+ torí ó ti gbọ́ gbogbo ohun tí Jèhófà bá wa sọ, ó sì máa jẹ́ ẹ̀rí lòdì sí yín, kí ẹ má bàa sẹ́ Ọlọ́run yín.” 28 Ni Jóṣúà bá ní kí àwọn èèyàn náà máa lọ, kí kálukú pa dà síbi ogún rẹ̀.+
29 Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Jóṣúà ọmọ Núnì, ìránṣẹ́ Jèhófà, kú lẹ́ni àádọ́fà (110) ọdún.+ 30 Wọ́n sin ín sí ilẹ̀ tó jogún ní Timunati-sírà,+ èyí tó wà ní agbègbè olókè Éfúrémù, ní àríwá Òkè Gááṣì. 31 Ísírẹ́lì ṣì ń sin Jèhófà ní gbogbo ọjọ́ ayé Jóṣúà àti ní gbogbo ọjọ́ ayé àwọn àgbààgbà tí wọ́n ṣẹ́ kù lẹ́yìn tí Jóṣúà kú, tí wọ́n sì ti mọ gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe nítorí Ísírẹ́lì.+
32 Wọ́n sin àwọn egungun Jósẹ́fù,+ èyí tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó kúrò ní Íjíbítì sí Ṣékémù lórí ilẹ̀ tí Jékọ́bù fi ọgọ́rùn-ún (100) ẹyọ owó+ rà lọ́wọ́ àwọn ọmọ Hámórì,+ bàbá Ṣékémù; ó sì di ogún àwọn ọmọ Jósẹ́fù.+
33 Bákan náà, Élíásárì ọmọ Áárónì kú.+ Wọ́n sì sin ín sí Òkè Fíníhásì ọmọ rẹ̀,+ èyí tí wọ́n fún un ní agbègbè olókè Éfúrémù.