Ìṣe Àwọn Àpọ́sítélì
14 Ní Íkóníónì, wọ́n jọ wọ sínágọ́gù àwọn Júù, wọ́n sì sọ̀rọ̀ lọ́nà tó mú kí ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn Júù àti Gíríìkì di onígbàgbọ́. 2 Àmọ́ àwọn Júù tí kò gbà gbọ́ ru àwọn èèyàn* orílẹ̀-èdè sókè, wọ́n sì sún wọn láti kórìíra àwọn arákùnrin.+ 3 Nítorí náà, wọ́n lo ọ̀pọ̀ àkókò láti fi ìgboyà sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ àṣẹ Jèhófà,* ẹni tí ó jẹ́rìí sí ọ̀rọ̀ inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí rẹ̀ bí ó ṣe jẹ́ kí wọ́n ṣe àwọn iṣẹ́ àmì àti àwọn iṣẹ́ ìyanu.*+ 4 Síbẹ̀, àwọn èrò inú ìlú náà pín sí méjì; àwọn kan wà lẹ́yìn àwọn Júù, àwọn míì sì wà lẹ́yìn àwọn àpọ́sítélì. 5 Nígbà tí àwọn èèyàn orílẹ̀-èdè àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn alákòóso wọn gbìyànjú láti dójú tì wọ́n, kí wọ́n sì sọ wọ́n lókùúta,+ 6 wọ́n gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n sì sá lọ sí àwọn ìlú Likaóníà, Lísírà àti Déébè àti àwọn abúlé tó wà ní àyíká.+ 7 Wọ́n ń kéde ìhìn rere níbẹ̀.
8 Ní Lísírà, ọkùnrin kan wà ní ìjókòó tí ẹsẹ̀ rẹ̀ rọ. Àtìgbà tí wọ́n ti bí i ló ti yarọ, kò sì rìn rí. 9 Ọkùnrin yìí ń fetí sí Pọ́ọ̀lù bó ṣe ń sọ̀rọ̀. Bí Pọ́ọ̀lù ṣe tẹjú mọ́ ọn, tó sì rí i pé ó ní ìgbàgbọ́ pé òun lè rí ìwòsàn,+ 10 ó gbóhùn sókè pé: “Dìde lórí ẹsẹ̀ rẹ.” Ọkùnrin náà fò sókè, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í rìn.+ 11 Nígbà tí ọ̀pọ̀ èèyàn rí ohun tí Pọ́ọ̀lù ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè, wọ́n sì fi èdè Likaóníà sọ pé: “Àwọn ọlọ́run ti gbé àwọ̀ èèyàn wọ̀, wọ́n sì ti sọ̀ kalẹ̀ wá bá wa!”+ 12 Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í pe Bánábà ní Súúsì, wọ́n sì ń pe Pọ́ọ̀lù ní Hẹ́mísì, torí òun ló máa ń sọ̀rọ̀ jù. 13 Àlùfáà Súúsì tí tẹ́ńpìlì rẹ̀ wà ní àbáwọlé ìlú náà mú àwọn akọ màlúù àti òdòdó ẹ̀yẹ* wá sí ẹnubodè, òun àti ọ̀pọ̀ èèyàn tó wà níbẹ̀ sì fẹ́ rúbọ.
14 Àmọ́, nígbà tí Bánábà àti Pọ́ọ̀lù, tí wọ́n jẹ́ àpọ́sítélì gbọ́ nípa rẹ̀, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bẹ́ sáàárín èrò náà, wọ́n sì ké jáde pé: 15 “Ẹ̀yin èèyàn, kí ló dé tí ẹ̀ ń ṣe àwọn nǹkan yìí? Èèyàn bíi tiyín ni wá, àwa náà ní àwọn àìlera tí ẹ ní.+ Ìhìn rere ni à ń kéde fún yín, kí ẹ lè yí pa dà kúrò nínú àwọn ohun asán yìí sọ́dọ̀ Ọlọ́run alààyè, ẹni tó dá ọ̀run àti ayé àti òkun pẹ̀lú gbogbo ohun tó wà nínú wọn.+ 16 Ní àwọn ìran tó ti kọjá, ó gba gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè láyè láti máa ṣe bó ṣe wù wọ́n,+ 17 bó tilẹ̀ jẹ́ pé, kò ṣàìfi ẹ̀rí irú ẹni tí òun jẹ́ hàn+ ní ti pé ó ń ṣe rere, ó ń rọ òjò fún yín láti ọ̀run, ó sì ń fún yín ní àwọn àsìkò tí irè oko ń jáde,+ ó ń fi oúnjẹ bọ́ yín, ó sì ń fi ayọ̀ kún ọkàn yín.”+ 18 Pẹ̀lú gbogbo ohun tí wọ́n sọ yìí, wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ má lè dá àwọn èrò náà dúró pé kí wọ́n má ṣe rúbọ sí àwọn.
19 Àmọ́ àwọn Júù dé láti Áńtíókù àti Íkóníónì, wọ́n sì yí àwọn èrò náà lọ́kàn pa dà,+ wọ́n bá sọ Pọ́ọ̀lù lókùúta, wọ́n sì wọ́ ọ sẹ́yìn òde ìlú, wọ́n rò pé ó ti kú.+ 20 Àmọ́ nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn yí i ká, ó dìde, ó sì wọ ìlú náà. Ní ọjọ́ kejì, òun àti Bánábà lọ sí Déébè.+ 21 Lẹ́yìn tí wọ́n kéde ìhìn rere fún ìlú yẹn, tí wọ́n sì sọ àwọn díẹ̀ di ọmọ ẹ̀yìn, wọ́n pa dà sí Lísírà, Íkóníónì àti Áńtíókù. 22 Nígbà tí wọ́n débẹ̀, wọ́n fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn* lókun,+ wọ́n fún wọn ní ìṣírí láti má ṣe kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì sọ pé: “A gbọ́dọ̀ ti inú ọ̀pọ̀ ìpọ́njú wọ Ìjọba Ọlọ́run.”+ 23 Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n yan àwọn alàgbà fún wọn nínú ìjọ kọ̀ọ̀kan,+ wọ́n gbàdúrà pẹ̀lú ààwẹ̀,+ wọ́n sì fà wọ́n lé Jèhófà* lọ́wọ́, ẹni tí wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀.
24 Lẹ́yìn náà, wọ́n gba Písídíà kọjá, wọ́n sì wá sí Panfílíà,+ 25 lẹ́yìn tí wọ́n kéde ọ̀rọ̀ náà ní Pẹ́gà, wọ́n lọ sí Atalíà. 26 Láti ibẹ̀, wọ́n wọkọ̀ òkun lọ sí Áńtíókù, níbi tí àwọn ará ti fi wọ́n lé Ọlọ́run lọ́wọ́ pé kó fi inú rere àìlẹ́tọ̀ọ́sí hàn sí wọn kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ tí wọ́n ti wá parí báyìí.+
27 Nígbà tí wọ́n dé, tí wọ́n sì kó ìjọ jọ, wọ́n ròyìn ọ̀pọ̀ ohun tí Ọlọ́run ti ṣe nípasẹ̀ wọn àti pé ó ti ṣí ilẹ̀kùn fún àwọn orílẹ̀-èdè láti di onígbàgbọ́.+ 28 Nítorí náà, wọ́n lo àkókò tó pọ̀ díẹ̀ pẹ̀lú àwọn ọmọ ẹ̀yìn.