Sáàmù
Ti Dáfídì. Másíkílì.*
32 Aláyọ̀ ni ẹni tí a dárí àṣìṣe rẹ̀ jì, tí a sì bo ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ mọ́lẹ̀.*+
3 Nígbà tí mo dákẹ́, egungun mi ń ṣàárẹ̀ torí mò ń kérora láti àárọ̀ ṣúlẹ̀.+
4 Tọ̀sántòru ni ọwọ́* rẹ le lára mi.+
Okun mi ti gbẹ* bí omi ṣe ń gbẹ nígbà ẹ̀ẹ̀rùn. (Sélà)
Mo sọ pé: “Màá jẹ́wọ́ àwọn ẹ̀ṣẹ̀ mi fún Jèhófà.”+
O sì dárí àṣìṣe àti ẹ̀ṣẹ̀ mi jì mí.+ (Sélà)
Kódà nígbà náà, àkúnya omi kò ní dé ọ̀dọ̀ wọn.
Wàá fi igbe ayọ̀ ìgbàlà yí mi ká.+ (Sélà)
8 “Màá fún ọ ní ìjìnlẹ̀ òye, màá sì kọ́ ọ ní ọ̀nà tó yẹ kí o máa rìn.+
Màá fún ọ ní ìmọ̀ràn pẹ̀lú ojú mi lára rẹ.+
9 Ẹ má dà bí ẹṣin tàbí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́* tí kò ní òye,+
Tó jẹ́ pé ìjánu tàbí okùn la fi ń kì í wọ̀ tó bá ń ta pọ́n-ún pọ́n-ún
Kó tó lè sún mọ́ni.”
11 Ẹ máa yọ̀ nínú Jèhófà, kí inú yín sì máa dùn, ẹ̀yin olódodo;
Ẹ kígbe ayọ̀, gbogbo ẹ̀yin tí ọkàn yín dúró ṣinṣin.