Ìsíkíẹ́lì
17 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 2 “Ọmọ èèyàn, pa àlọ́, kí o sì pa òwe nípa ilé Ísírẹ́lì.+ 3 Kí o sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ẹyẹ idì ńlá+ kan wá sí Lẹ́bánónì,+ apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ gùn, ìyẹ́ náà kún ara rẹ̀, ó sì ní àwọ̀ aláràbarà. Idì náà sì ṣẹ́ téńté orí igi kédárì.+ 4 Ó já ọ̀mùnú rẹ̀ tó wà lókè pátápátá, ó mú un wá sí ilẹ̀ àwọn oníṣòwò,* ó sì gbìn ín sí ìlú àwọn oníṣòwò.+ 5 Ó wá mú lára irúgbìn ilẹ̀ náà,+ ó sì fi sínú ilẹ̀ tó lọ́ràá. Ó gbìn ín bí igi wílò lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi. 6 Ó rú jáde, ó sì di àjàrà tí kò ga, tó bolẹ̀,+ tí ewé rẹ̀ kò nà jáde, tí gbòǹgbò rẹ̀ sì ń hù lábẹ́ rẹ̀. Ó wá di àjàrà, ó yọ ọ̀mùnú, ó sì pẹ̀ka.+
7 “‘“Ẹyẹ idì ńlá mìíràn tún wá,+ apá rẹ̀ tóbi, ìyẹ́ rẹ̀ sì fẹ̀.+ Àjàrà yìí yára na gbòǹgbò rẹ̀ kúrò nínú ọgbà tí wọ́n gbìn ín sí lọ sọ́dọ̀ ẹyẹ idì náà, ó sì na àwọn ewé rẹ̀ sọ́dọ̀ ẹyẹ náà kó lè bomi rin ín.+ 8 Inú oko tó dára, lẹ́gbẹ̀ẹ́ alagbalúgbú omi ni wọ́n gbìn ín sí, kó lè yọ ẹ̀ka, kó lè so èso, kó sì di àjàrà ńlá.”’+
9 “Sọ pé, ‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Ǹjẹ́ ó máa gbèrú? Ṣé ẹnì kan ò ní fa gbòǹgbò rẹ̀ tu+ tàbí kó mú kí èso rẹ̀ jẹrà, kó sì mú kí ọ̀mùnú rẹ̀ rọ?+ Yóò gbẹ débi pé kò ní nílò ọwọ́ tó lágbára tàbí ọ̀pọ̀ èèyàn kí wọ́n tó lè fà á tu tegbòtegbò. 10 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n tún un gbìn, ǹjẹ́ ó máa gbèrú? Ṣé kò ní gbẹ dà nù nígbà tí atẹ́gùn ìlà oòrùn bá fẹ́ lù ú? Yóò gbẹ dà nù lórí ebè tó hù sí.”’”
11 Jèhófà tún bá mi sọ̀rọ̀, ó ní: 12 “Jọ̀ọ́ sọ fún ọlọ̀tẹ̀ ilé náà pé, ‘Ṣé ẹ ò mọ ohun tí nǹkan wọ̀nyí túmọ̀ sí ni?’ Sọ pé, ‘Wò ó! Ọba Bábílónì wá sí Jerúsálẹ́mù, ó mú ọba rẹ̀ àti àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì mú wọn pa dà wá sí Bábílónì.+ 13 Ó tún mú ọ̀kan lára àwọn ọmọ* ọba,+ ó bá a dá májẹ̀mú, ó sì mú kó búra.+ Ó wá kó àwọn tó gbajúmọ̀ ní ilẹ̀ náà lọ,+ 14 kó lè rẹ ìjọba náà wálẹ̀, kó má lè dìde, kó lè jẹ́ pé tó bá ń pa májẹ̀mú rẹ̀ mọ́ nìkan ni ìjọba náà á fi lè máa wà nìṣó.+ 15 Àmọ́ níkẹyìn, ọba náà ṣọ̀tẹ̀ sí i,+ ó rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ sí Íjíbítì, kí wọ́n lè fún un ní àwọn ẹṣin+ àti ọmọ ogun púpọ̀.+ Ṣé ó máa ṣàṣeyọrí? Ǹjẹ́ ẹni tó ń ṣe nǹkan wọ̀nyí á bọ́ lọ́wọ́ ìyà? Ṣé ó lè da májẹ̀mú kó sì mú un jẹ?’+
16 “‘“Bí mo ti wà láàyè,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí, “Bábílónì ni yóò kú sí, níbi tí ọba* tó fi í* jọba ń gbé, ẹni tí òun kò ka ìbúra rẹ̀ sí, tó sì da májẹ̀mú rẹ̀.+ 17 Ẹgbẹ́ ogun Fáráò àti àwọn ọmọ ogun wọn kò ní lè ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà ogun,+ nígbà tí wọ́n bá mọ òkìtì láti dó tì í, tí wọ́n sì mọ odi kí wọ́n lè gbẹ̀mí ọ̀pọ̀ èèyàn.* 18 Ó ti fojú kéré ìbúra, ó sì ti da májẹ̀mú. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣèlérí,* ó ti ṣe gbogbo nǹkan yìí, kò sì ní yè bọ́.”’
19 “‘Torí náà, ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Bí mo ti wà láàyè, èmi yóò fìyà ohun tó ṣe jẹ ẹ́, bó ṣe fojú kéré ìbúra mi+ tó sì da májẹ̀mú mi. 20 Èmi yóò ju àwọ̀n mi sí i láti fi mú un.+ Èmi yóò mú un wá sí Bábílónì, màá sì dá a lẹ́jọ́ níbẹ̀ torí ìwà àìṣòótọ́ tó hù sí mi.+ 21 Idà ni yóò pa gbogbo àwọn tó bá sá lára àwọn ọmọ ogun rẹ̀, àwọn yòókù á sì fọ́n ká síbi gbogbo.*+ Ẹ ó sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀.”’+
22 “‘Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí: “Èmi yóò mú ọ̀mùnú ní téńté orí igi kédárì tó ga fíofío,+ màá sì gbìn ín, láti orí ẹ̀ka igi rẹ̀ ni èmi yóò ti já ọ̀mùnú múlọ́múlọ́,+ màá sì gbìn ín sórí òkè tó ga fíofío.+ 23 Èmi yóò gbìn ín sórí òkè tó ga ní Ísírẹ́lì; yóò yọ ẹ̀ka, yóò so èso, yóò sì di igi kédárì ńlá. Oríṣiríṣi ẹyẹ yóò máa gbé lábẹ́ rẹ̀, wọ́n á sì fi òjìji àwọn ewé rẹ̀ ṣe ibùgbé wọn. 24 Gbogbo igi oko yóò sì wá mọ̀ pé èmi Jèhófà ti rẹ igi ńlá wálẹ̀, mo sì ti gbé igi tó rẹlẹ̀ ga;+ mo ti sọ igi tútù di gbígbẹ, mo sì ti mú kí igi tó gbẹ rúwé.+ Èmi Jèhófà ti sọ̀rọ̀, mo sì ti ṣe é.”’”