Dáníẹ́lì
3 Ọba Nebukadinésárì ṣe ère wúrà kan, gíga rẹ̀ jẹ́ ọgọ́ta (60) ìgbọ̀nwọ́,* fífẹ̀ rẹ̀ sì jẹ́ ìgbọ̀nwọ́ mẹ́fà.* Ó gbé e kalẹ̀ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà ní ìpínlẹ̀* Bábílónì. 2 Ọba Nebukadinésárì wá ránṣẹ́ sí àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn adájọ́, àwọn agbófinró àti gbogbo àwọn alábòójútó ìpínlẹ̀* pé kí wọ́n kóra jọ, kí wọ́n wá síbi ayẹyẹ tí wọ́n fẹ́ fi ṣí ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
3 Torí náà, àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà, àwọn agbani-nímọ̀ràn, àwọn olùtọ́jú ìṣúra, àwọn adájọ́, àwọn agbófinró àti gbogbo àwọn alábòójútó ìpínlẹ̀* kóra jọ síbi ayẹyẹ tí wọ́n fẹ́ fi ṣí ère tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. Wọ́n sì dúró síwájú ère tí Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. 4 Ẹni tó ń kéde wá kígbe pé: “A pàṣẹ fún ẹ̀yin èèyàn, ẹ̀yin orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà, 5 pé nígbà tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, kí ẹ wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀. 6 Ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kó sì jọ́sìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ la máa jù ú sínú iná ìléru tó ń jó.”+ 7 Torí náà, nígbà tí gbogbo èèyàn gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín àti gbogbo ohun ìkọrin míì, gbogbo èèyàn, orílẹ̀-èdè àti ẹ̀yà wólẹ̀, wọ́n sì jọ́sìn ère wúrà tí Ọba Nebukadinésárì gbé kalẹ̀.
8 Ìgbà yẹn ni àwọn ará Kálídíà kan wá síwájú, wọ́n sì fẹ̀sùn* kan àwọn Júù. 9 Wọ́n sọ fún Ọba Nebukadinésárì pé: “Kí ẹ̀mí ọba gùn títí láé. 10 Ìwọ ọba lo pàṣẹ pé tí gbogbo èèyàn bá ti gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, kí wọ́n wólẹ̀, kí wọ́n sì jọ́sìn ère wúrà náà; 11 àti pé ẹnikẹ́ni tí kò bá wólẹ̀, kó sì jọ́sìn, a máa jù ú sínú iná ìléru tó ń jó.+ 12 Àmọ́ àwọn Júù kan wà tí o yàn pé kí wọ́n máa bójú tó ìpínlẹ̀* Bábílónì, ìyẹn Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò.+ Àwọn ọkùnrin yìí ò kà ọ́ sí rárá, ọba. Wọn ò sin àwọn ọlọ́run rẹ, wọ́n sì kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”
13 Inú wá bí Nebukadinésárì gidigidi, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò wá. Torí náà, wọ́n mú àwọn ọkùnrin yìí wá síwájú ọba. 14 Nebukadinésárì sọ fún wọn pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣé òótọ́ ni pé ẹ ò sin àwọn ọlọ́run mi,+ ẹ sì kọ̀ láti jọ́sìn ère wúrà tí mo gbé kalẹ̀? 15 Ní báyìí, tí ẹ bá gbọ́ ìró ìwo, fèrè ape, ọpọ́n orin olókùn púpọ̀, háàpù onígun mẹ́ta, ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín, fèrè alápò awọ àti gbogbo ohun ìkọrin míì, ohun tó máa dáa ni pé kí ẹ ṣe tán láti wólẹ̀, kí ẹ sì jọ́sìn ère tí mo ṣe. Àmọ́ tí ẹ bá kọ̀ láti jọ́sìn, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni wọ́n máa jù yín sínú iná ìléru tó ń jó. Ta sì ni ọlọ́run tó lè gbà yín sílẹ̀ lọ́wọ́ mi?”+
16 Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò dá ọba lóhùn pé: “Nebukadinésárì, kò sídìí láti ṣàlàyé ohunkóhun fún ọ lórí ọ̀rọ̀ yìí. 17 Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ìwọ ọba, Ọlọ́run wa tí à ń sìn lè gbà wá sílẹ̀ kúrò nínú iná ìléru tó ń jó, ó sì lè gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ rẹ.+ 18 Àmọ́ tí kò bá tiẹ̀ gbà wá, a fẹ́ kí ìwọ ọba mọ̀ pé a ò ní sin àwọn ọlọ́run rẹ, a ò sì ní jọ́sìn ère wúrà tí o gbé kalẹ̀.”+
19 Inú wá bí Nebukadinésárì gan-an sí Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò débi pé ojú rẹ̀ yí pa dà sí wọn,* ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n mú kí iná ìléru náà gbóná ní ìlọ́po méje ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. 20 Ó sọ fún àwọn kan lára àwọn alágbára ọkùnrin tó wà nínú àwọn ọmọ ogun rẹ̀ pé kí wọ́n de Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, kí wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru tó ń jó.
21 Wọ́n wá de àwọn ọkùnrin yìí tàwọn ti aṣọ ìlékè tí wọ́n wọ̀, ẹ̀wù, fìlà àti gbogbo aṣọ ọrùn wọn, wọ́n sì jù wọ́n sínú iná ìléru tó ń jó. 22 Torí pé àṣẹ ọba le gan-an, iná ìléru náà sì gbóná kọjá ààlà, ọwọ́ iná náà pa àwọn ọkùnrin tó mú Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò lọ. 23 Àmọ́ àwọn ọkùnrin mẹ́ta yìí, Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣubú sínú iná ìléru tó ń jó náà ní dídè.
24 Jìnnìjìnnì wá bo Ọba Nebukadinésárì, ó yára dìde, ó sì sọ fún àwọn ìjòyè rẹ̀ pé: “Ṣebí ọkùnrin mẹ́ta la dè, tí a sì jù sínú iná?” Wọ́n dá ọba lóhùn pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ọba.” 25 Ó sọ pé: “Ẹ wò ó! Ọkùnrin mẹ́rin ni mò ń rí tí wọ́n ń rìn fàlàlà ní àárín iná náà, ohunkóhun ò ṣe wọ́n, ẹni kẹrin sì rí bí ọmọ àwọn ọlọ́run.”
26 Nebukadinésárì wá sún mọ́ ilẹ̀kùn iná ìléru tó ń jó náà, ó sì sọ pé: “Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,+ ẹ jáde, kí ẹ sì máa bọ̀!” Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò sì jáde láti àárín iná náà. 27 Àwọn baálẹ̀, àwọn aṣíwájú, àwọn gómìnà àti àwọn ìjòyè ọba tí wọ́n pé jọ síbẹ̀+ rí i pé iná náà ò pa àwọn ọkùnrin yìí lára* rárá;+ iná ò ra ẹyọ kan lára irun orí wọn, aṣọ ìlékè wọn ò yí pa dà, wọn ò tiẹ̀ gbóòórùn iná lára wọn.
28 Nebukadinésárì wá kéde pé: “Ẹ yin Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò,+ tó rán áńgẹ́lì rẹ̀, tó sì gba àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé e, wọ́n sì kọ̀ láti tẹ̀ lé àṣẹ ọba, wọ́n ṣe tán láti kú* dípò kí wọ́n sin ọlọ́run míì yàtọ̀ sí Ọlọ́run wọn tàbí kí wọ́n jọ́sìn rẹ̀.+ 29 Torí náà, mo pa á láṣẹ pé èèyàn èyíkéyìí, orílẹ̀-èdè tàbí ẹ̀yà tó bá sọ ohunkóhun tí kò dáa sí Ọlọ́run Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò, ṣe la máa gé e sí wẹ́wẹ́, a sì máa sọ ilé rẹ̀ di ilé ìyàgbẹ́ gbogbo èèyàn;* torí kò sí ọlọ́run míì tó lè gbani là bí èyí.”+
30 Ọba wá gbé Ṣádírákì, Méṣákì àti Àbẹ́dínígò ga* ní ìpínlẹ̀* Bábílónì.+