Diutarónómì
30 “Tí gbogbo ọ̀rọ̀ yìí bá ṣẹ sí ọ lára, ìbùkún àti ègún tí mo fi síwájú rẹ,+ tí o sì rántí wọn*+ ní gbogbo orílẹ̀-èdè tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí, 2 tí o wá pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí o fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ fetí sí ohùn rẹ̀, ìwọ àti àwọn ọmọ rẹ, gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí mò ń pa láṣẹ fún ọ lónìí, 3 nígbà náà, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú àwọn èèyàn rẹ tí wọ́n kó lẹ́rú+ pa dà wá, ó máa ṣàánú+ rẹ, ó sì máa kó ọ jọ látọ̀dọ̀ gbogbo èèyàn tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ tú ọ+ ká sí. 4 Ì báà jẹ́ ìpẹ̀kun ọ̀run ni àwọn èèyàn rẹ tú ká sí, Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa kó ọ jọ, á sì mú ọ pa dà wá + láti ibẹ̀. 5 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú ọ wá sí ilẹ̀ tí àwọn bàbá rẹ gbà, ó sì máa di tìẹ; á mú kí nǹkan máa lọ dáadáa fún ọ, á sì mú kí o pọ̀ ju àwọn bàbá+ rẹ. 6 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa wẹ ọkàn rẹ mọ́* àti ọkàn ọmọ+ rẹ, kí o lè fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara* rẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, kí o sì máa wà láàyè.+ 7 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa mú gbogbo ègún yìí wá sórí àwọn ọ̀tá rẹ, tí wọ́n kórìíra rẹ tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí ọ.+
8 “Nígbà náà, wàá pa dà, wàá fetí sí ohùn Jèhófà, wàá sì pa gbogbo àṣẹ rẹ̀ tí mò ń pa fún ọ lónìí mọ́. 9 Jèhófà Ọlọ́run rẹ máa bù kún gbogbo iṣẹ́ ọwọ́+ rẹ lọ́pọ̀lọpọ̀, ó máa mú kí àwọn ọmọ rẹ, àwọn ẹran ọ̀sìn rẹ àti èso ilẹ̀ rẹ di púpọ̀, torí pé lẹ́ẹ̀kan sí i inú Jèhófà máa dùn láti mú kí nǹkan lọ dáadáa fún ọ bí inú rẹ̀ ṣe dùn sí àwọn baba ńlá+ rẹ. 10 Nígbà yẹn, wàá fetí sí ohùn Jèhófà Ọlọ́run rẹ, wàá sì pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ tí wọ́n kọ sínú ìwé Òfin yìí, wàá sì fi gbogbo ọkàn rẹ àti gbogbo ara*+ rẹ pa dà sọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run rẹ.
11 “Àṣẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí yìí kò nira jù fún ọ, kì í sì í ṣe ohun tí kò sí lárọ̀ọ́wọ́tó+ rẹ.* 12 Kò sí ní ọ̀run, débi tí wàá fi sọ pé, ‘Ta ló máa lọ bá wa mú un wá ní ọ̀run, ká lè gbọ́ ọ, ká sì máa tẹ̀ lé e?’+ 13 Bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní òdìkejì òkun, débi tí wàá fi sọ pé, ‘Ta ló máa sọdá lọ sí òdìkejì òkun kó lè bá wa mú un wá, ká lè gbọ́ ọ, ká sì máa tẹ̀ lé e?’ 14 Àmọ́ tòsí rẹ gan-an ni ọ̀rọ̀ náà wà, ní ẹnu rẹ àti ní ọkàn+ rẹ, kí o lè máa ṣe é.+
15 “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, ikú àti ibi+ sí iwájú rẹ lónìí. 16 Tí o bá fetí sí àṣẹ Jèhófà Ọlọ́run rẹ tí mò ń pa fún ọ lónìí, tí ò ń nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, tí ò ń rìn ní àwọn ọ̀nà rẹ̀, tí o sì ń pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́ àti àwọn òfin rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìdájọ́ rẹ̀, wàá máa wà láàyè,+ wàá sì máa pọ̀ sí i, Jèhófà Ọlọ́run rẹ sì máa bù kún ọ ní ilẹ̀ tí o fẹ́ lọ gbà.+
17 “Àmọ́ tí ọkàn yín bá yí pa dà,+ tí ẹ ò fetí sílẹ̀, tí ẹ sì jẹ́ kí ọkàn yín fà sí àwọn ọlọ́run míì, tí ẹ wá ń forí balẹ̀ fún wọn, tí ẹ sì ń sìn wọ́n,+ 18 mò ń sọ fún yín lónìí pé ó dájú pé ẹ máa ṣègbé.+ Ẹ̀mí yín ò sì ní gùn lórí ilẹ̀ tí ẹ̀ ń sọdá Jọ́dánì lọ gbà. 19 Mò ń fi ọ̀run àti ayé ṣe ẹlẹ́rìí lòdì sí ọ lónìí, pé mo ti fi ìyè àti ikú sí iwájú rẹ, ìbùkún àti ègún;+ yan ìyè, kí o lè máa wà láàyè,+ ìwọ àti àwọn àtọmọdọ́mọ+ rẹ, 20 nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run+ rẹ, kí o máa fetí sí ohùn rẹ̀, kí o sì rọ̀ mọ́ ọn,+ torí òun ni ìyè rẹ, òun ló sì máa mú kí o pẹ́ lórí ilẹ̀ tí Jèhófà búra pé òun máa fún àwọn baba ńlá rẹ Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù.”+