Diutarónómì
29 Èyí ni àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí Jèhófà pa láṣẹ fún Mósè pé kó bá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dá ní ilẹ̀ Móábù, yàtọ̀ sí májẹ̀mú tó bá wọn dá ní Hórébù.+
2 Mósè pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ, ó sì sọ fún wọn pé: “Ẹ ti rí gbogbo ohun tí Jèhófà ṣe níṣojú yín ní ilẹ̀ Íjíbítì sí Fáráò àti gbogbo ìránṣẹ́ rẹ̀ àti gbogbo ilẹ̀ rẹ̀,+ 3 àwọn ìdájọ́* tó rinlẹ̀ tí ẹ fojú rí, àwọn iṣẹ́ àmì àti iṣẹ́ ìyanu ńlá yẹn.+ 4 Àmọ́ títí di òní yìí, Jèhófà kò tíì fún yín ní ọkàn láti lóyè, ojú láti rí àti etí láti gbọ́.+ 5 ‘Bí mo ṣe darí yín jálẹ̀ ogójì (40) ọdún nínú aginjù,+ aṣọ yín ò gbó mọ́ yín lára, bàtà yín ò sì gbó mọ́ yín lẹ́sẹ̀.+ 6 Ẹ ò jẹ búrẹ́dì, ẹ ò sì mu wáìnì tàbí ohunkóhun míì tó ní ọtí, kí ẹ lè mọ̀ pé èmi ni Jèhófà Ọlọ́run yín.’ 7 Nígbà tí ẹ wá dé ibí yìí, Síhónì ọba Hẹ́ṣíbónì+ àti Ógù ọba Báṣánì+ jáde wá bá wa jagun, àmọ́ a ṣẹ́gun wọn.+ 8 Lẹ́yìn náà, a gba ilẹ̀ wọn, a sì fún àwọn ọmọ Rúbẹ́nì, àwọn ọmọ Gádì àti ààbọ̀ ẹ̀yà àwọn ọmọ Mánásè+ pé kó jẹ́ ogún tiwọn. 9 Torí náà, ẹ máa pa àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú yìí mọ́, kí ẹ sì máa tẹ̀ lé wọn, kí gbogbo ohun tí ẹ bá ń ṣe lè yọrí sí rere.+
10 “Gbogbo yín lẹ dúró níwájú Jèhófà Ọlọ́run yín lónìí, àwọn olórí ẹ̀yà yín, àwọn àgbààgbà yín, àwọn aṣojú yín, gbogbo ọkùnrin Ísírẹ́lì, 11 àwọn ọmọ yín, àwọn ìyàwó yín,+ àwọn àjèjì tó wà nínú ibùdó yín,+ látorí ẹni tó ń bá yín ṣẹ́gi dórí ẹni tó ń bá yín fa omi. 12 Torí kí ẹ lè wọnú májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run yín àti ìbúra rẹ̀, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run yín ń bá yín dá lónìí lẹ ṣe wà níbí,+ 13 kó bàa lè fìdí rẹ̀ múlẹ̀ lónìí pé èèyàn òun lẹ jẹ́,+ kó sì jẹ́ Ọlọ́run yín,+ bó ṣe ṣèlérí fún yín gẹ́lẹ́, bó sì ṣe búra fún àwọn baba ńlá yín, Ábúráhámù,+ Ísákì+ àti Jékọ́bù.+
14 “Ẹ̀yin nìkan kọ́ ni mò ń bá dá májẹ̀mú yìí, tí mo sì ń búra fún, 15 àmọ́ ó tún kan àwọn tó dúró síbí pẹ̀lú wa lónìí, níwájú Jèhófà Ọlọ́run wa àti àwọn tí kò sí níbí pẹ̀lú wa lónìí. 16 (Torí ẹ mọ̀ dáadáa bí a ṣe gbé ní ilẹ̀ Íjíbítì àti bí a ṣe gba àárín oríṣiríṣi orílẹ̀-èdè kọjá lẹ́nu ìrìn àjò wa.+ 17 Ẹ sì máa ń rí àwọn ohun ìríra wọn àti àwọn òrìṣà ẹ̀gbin*+ wọn, tí wọ́n fi igi, òkúta, fàdákà àti wúrà ṣe, tó wà láàárín wọn.) 18 Ẹ ṣọ́ra, kó má bàa sí ọkùnrin tàbí obìnrin kankan, ìdílé tàbí ẹ̀yà kan láàárín yín lónìí tí ọkàn rẹ̀ máa yí pa dà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà Ọlọ́run wa láti lọ sin àwọn ọlọ́run àwọn orílẹ̀-èdè yẹn,+ kó má bàa sí gbòǹgbò kankan láàárín yín tó ń so èso tó ní májèlé àti iwọ.*+
19 “Àmọ́ tí ẹnì kan bá gbọ́ ọ̀rọ̀ ìbúra yìí, tó sì ń fọ́nnu lọ́kàn ara rẹ̀ pé, ‘Tí mo bá tiẹ̀ fi àáké kọ́rí, tí mò ń ṣe ohun tí ọkàn mi fẹ́, màá ní àlàáfíà,’ gbogbo ohun* tó wà lọ́nà rẹ̀ ló máa pa run, 20 Jèhófà ò ní ṣe tán láti dárí jì í.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, Jèhófà máa bínú gidigidi sí ẹni náà, ó dájú pé gbogbo ègún tí wọ́n sì kọ sínú ìwé yìí máa wá sórí rẹ̀,+ ó sì dájú pé Jèhófà máa pa orúkọ rẹ̀ rẹ́ kúrò lábẹ́ ọ̀run. 21 Jèhófà máa wá yọ òun nìkan kúrò nínú gbogbo ẹ̀yà Ísírẹ́lì kí àjálù lè dé bá a, bó ṣe wà nínú gbogbo ègún májẹ̀mú tí wọ́n kọ sínú ìwé Òfin yìí.
22 “Tí ìran àwọn ọmọ yín lọ́jọ́ iwájú àti àwọn àjèjì tó wá láti ọ̀nà jíjìn bá rí àwọn àjálù tó bá ilẹ̀ náà, àwọn ìyọnu tí Jèhófà mú wá sórí rẹ̀, 23 ìyẹn, imí ọjọ́, iyọ̀ àti iná, kí wọ́n má bàa fúnrúgbìn kankan sí gbogbo ilẹ̀ rẹ̀ tàbí kí irúgbìn hù níbẹ̀, kí ewéko kankan má sì hù níbẹ̀, bí ìparun Sódómù àti Gòmórà,+ Ádímà àti Sébóímù,+ tí Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú rẹ̀ pa run, 24 àwọn àti gbogbo orílẹ̀-èdè máa sọ pé, ‘Kí nìdí tí Jèhófà fi ṣe báyìí sí ilẹ̀ yìí?+ Kí ló fa ìbínú tó le, tó kàmàmà yìí?’ 25 Wọ́n á wá sọ pé, ‘Torí pé wọ́n pa májẹ̀mú Jèhófà+ Ọlọ́run àwọn baba ńlá wọn tì ni, èyí tó bá wọn dá nígbà tó mú wọn kúrò ní ilẹ̀ Íjíbítì.+ 26 Wọ́n lọ ń sin àwọn ọlọ́run míì, wọ́n sì ń forí balẹ̀ fún wọn, àwọn ọlọ́run tí wọn ò mọ̀, tí kò sì gbà pé kí wọ́n máa jọ́sìn.*+ 27 Jèhófà wá bínú gidigidi sí ilẹ̀ náà, ó sì mú gbogbo ègún tí wọ́n kọ sínú ìwé yìí wá sórí rẹ̀.+ 28 Torí náà, Jèhófà fi ìbínú àti ìrunú àti ìkannú ńlá fà wọ́n tu kúrò ní ilẹ̀ wọn,+ ó sì kó wọn lọ sí ilẹ̀ míì níbi tí wọ́n wà lónìí.’+
29 “Àwọn ohun tó wà ní ìpamọ́ jẹ́ ti Jèhófà Ọlọ́run wa,+ àmọ́ àwọn ohun tí a ṣí payá jẹ́ tiwa àti àwọn àtọmọdọ́mọ wa títí láé, ká lè máa tẹ̀ lé gbogbo ọ̀rọ̀ Òfin yìí.+