Orin. Orin Ásáfù.+
83 Ọlọ́run, má ṣe dákẹ́;+
Má ṣàìsọ̀rọ̀, má sì dúró jẹ́ẹ́, ìwọ Olú Ọ̀run.
2 Wò ó! àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú rúkèrúdò;+
Àwọn tó kórìíra rẹ ń hùwà ìgbéraga.
3 Wọ́n fi ọgbọ́nkọ́gbọ́n gbìmọ̀ pọ̀ nítorí àwọn èèyàn rẹ;
Wọ́n sì lẹ̀dí àpò pọ̀ nítorí àwọn àyànfẹ́ rẹ.
4 Wọ́n sọ pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa wọ́n run kí wọ́n má ṣe jẹ́ orílẹ̀-èdè mọ́,+
Kí a má sì rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.”
5 Wọ́n fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n máa ṣe;
Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti bá ọ jà,+
6 Àgọ́ Édómù àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù+ àti àwọn ọmọ Hágárì,+
7 Gébálì àti Ámónì+ àti Ámálékì,
Filísíà+ pẹ̀lú àwọn tó ń gbé ní Tírè.+
8 Ásíríà+ pẹ̀lú ti dara pọ̀ mọ́ wọn;
Wọ́n ran àwọn ọmọ Lọ́ọ̀tì+ lọ́wọ́. (Sélà)
9 Kí o ṣe wọ́n bí o ti ṣe Mídíánì,+
Bí o ti ṣe Sísérà àti Jábínì ní odò Kíṣónì.+
10 Wọ́n pa run ní Ẹ́ń-dórì;+
Wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀.
11 Ṣe àwọn èèyàn pàtàkì wọn bí Órébù àti Séébù,+
Kí o sì ṣe àwọn olórí wọn bíi Séébà àti Sálímúnà,+
12 Nítorí wọ́n sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba ilẹ̀ tí Ọlọ́run ń gbé.”
13 Ìwọ Ọlọ́run mi, ṣe wọ́n bí ẹ̀gún tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ yípo yípo,+
Bí àgékù pòròpórò tí afẹ́fẹ́ ń fẹ́ kiri.
14 Bí iná tó ń jó igbó
Àti bí ọwọ́ iná tó ń jó àwọn òkè,+
15 Bẹ́ẹ̀ ni kí o fi ìjì líle rẹ lépa wọn,+
Kí o sì fi ẹ̀fúùfù rẹ kó jìnnìjìnnì bá wọn.+
16 Fi àbùkù bò wọ́n lójú,
Kí wọ́n lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.
17 Kí ojú tì wọ́n, kí jìnnìjìnnì sì bá wọn títí láé;
Kí wọ́n tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé;
18 Kí àwọn èèyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà,+
Ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ayé.+