Jèhófà Dáhùn Àdúrà Àtọkànwá Tí Ìránṣẹ́ Rẹ̀ Kan Gbà
“Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—SM. 83:18.
1, 2. Báwo ló ṣe máa ń rí lára ọ̀pọ̀ èèyàn nígbà tí wọ́n bá mọ orúkọ Ọlọ́run, àwọn ìbéèrè wo la sì lè béèrè?
LỌ́DÚN bíi mélòó kan sẹ́yìn, ìdààmú ọkàn bá obìnrin kan nítorí jàǹbá kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò rẹ̀. Nítorí pé inú ìdílé ẹlẹ́sìn Kátólíìkì ni wọ́n bí i sí, ó lọ sọ́dọ̀ àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì wọn, ó sì sọ fún un pé kó ran òun lọ́wọ́. Àmọ́ àlùfáà náà ò tiẹ̀ fẹ́ bá a sọ̀rọ̀ rárá débi táá wá ràn án lọ́wọ́. Ni obìnrin náà bá gbàdúrà sí Ọlọ́run pé: “Ọlọ́run, èmi ò mọ̀ ẹ́ o . . . , àmọ́ mo mọ̀ pé o wà lọ́run. Jọ̀ọ́, jẹ́ kí n mọ̀ ẹ́!” Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi wá sílé rẹ̀. Wọ́n tù ú nínú, wọ́n sì kọ́ ọ ní ọ̀pọ̀ nǹkan. Lára ohun tí wọ́n kọ́ ọ ni pé, Ọlọ́run ní orúkọ, Jèhófà sì ni orúkọ rẹ̀. Ohun tí obìnrin yìí kọ́ wọ̀ ọ́ lọ́kàn gan-an ni. Ó wá sọ pé: “Àbẹ́ ẹ̀ rí nǹkan? Ọlọ́run tí mo ti fẹ́ mọ̀ látìgbà tí mo wà lọ́mọdé ni mo wá mọ̀ wẹ́rẹ́ yìí!”
2 Bíi ti obìnrin yẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ni inú wọn máa ń dùn gan-an nígbà tí wọ́n bá mọ orúkọ Ọlọ́run. Lọ́pọ̀ ìgbà, ibi tí wọ́n ti máa ń kọ́kọ́ rí orúkọ Ọlọ́run nínú Bíbélì ni, Sáàmù 83:18. Nínú Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun, ẹsẹ yẹn kà pé: “Kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.” Ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti ronú nípa ìdí tí Sáàmù 83 fi wà lákọọ́lẹ̀ nínú Bíbélì? Kí ló máa ṣẹlẹ̀ tó máa mú kí gbogbo èèyàn gbà tipátipá pé Jèhófà nìkan ni Ọlọ́run tòótọ́? Ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú sáàmù yìí lóde òní? A óò dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí nínú àpilẹ̀kọ yìí.a
Wọ́n Gbìmọ̀ Pọ̀ Láti Pa Àwọn Èèyàn Jèhófà Run
3, 4. Ta ló kọ Sáàmù 83, kí sì ni àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì gbìmọ̀ pọ̀ láti ṣe?
3 Àkọlé Sáàmù 83 jẹ́ ká mọ̀ pé sáàmù yìí jẹ́ “orin atunilára ti Ásáfù.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àtọmọdọ́mọ ọ̀kan lára àwọn ọmọ Léfì tó ń jẹ́ Ásáfù ló kọ sáàmù yìí, gbajúmọ̀ olórin sì ni Ásáfù jẹ́ nígbà tí Dáfídì Ọba wà lórí ìtẹ́. Nínú sáàmù yẹn, Ásáfù bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Jèhófà ni ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run, kó sì jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Rẹ̀. Ó jọ pé lẹ́yìn ikú Sólómọ́nì Ọba ni Ásáfù kọ sáàmù yìí. Kí nìdí tá a fi lè sọ bẹ́ẹ̀? Ìdí ni pé nígbà tí Dáfídì àti Sólómọ́nì wà lórí ìtẹ́, kò síjà rárá láàárín ọba Tírè àti orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Àmọ́, nígbà tó fi máa dìgbà tí Ásáfù kọ sáàmù yẹn, àwọn olùgbé Tírè ti kẹ̀yìn sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì, wọ́n sì ti lẹ̀dí àpò pọ̀ pẹ̀lú àwọn ọ̀tá orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì.
4 Ásáfù sọ orúkọ àwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wàá tí wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́. Àyíká orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì làwọn orílẹ̀-èdè mẹ́wẹ̀ẹ̀wá yìí wà. Orúkọ wọn rèé: “Àwọn àgọ́ Édómù àti ti àwọn ọmọ Íṣímáẹ́lì, Móábù àti ti àwọn ọmọ Hágárì, Gébálì àti Ámónì àti Ámálékì, Filísíà pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn olùgbé Tírè. Pẹ̀lúpẹ̀lù, Ásíríà alára ti dara pọ̀ mọ́ wọn.” (Sm. 83:6-8) Ìṣẹ̀lẹ̀ tó gbàfiyèsí wo ni sáàmù yìí ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀? Àwọn kan sọ pé sáàmù yìí ń sọ nípa ìgbà tí Ámónì àti Móábù àtàwọn olùgbé Òkè Séírì gbìmọ̀ pọ̀ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà ayé Jèhóṣáfátì. (2 Kíró. 20:1-26) Àwọn mìíràn gbà pé sáàmù yẹn ń sọ nípa gbogbo ìgbà táwọn orílẹ̀-èdè tó yí Ísírẹ́lì ká fi gbógun tì wọ́n.
5. Ọ̀nà wo ni Sáàmù 83 gbà ṣàǹfààní fáwa Kristẹni lóde òní?
5 Ìgbà yòówù kí sáàmù yìí máa sọ nípa rẹ̀, ó hàn gbangba pé ìgbà tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì wà nínú ewu ni Jèhófà Ọlọ́run mí sí Ásáfù láti kọ sáàmù yìí. Lónìí, sáàmù yìí tún jẹ́ ìṣírí fáwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run, tó jẹ́ pé jálẹ̀ ìgbésí ayé wọn làwọn ọ̀tá gbógun tì wọ́n, láti pa wọ́n rẹ́. Bákan náà ló tún máa fún wa lókun lọ́jọ́ iwájú nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá kó àwọn èèyàn rẹ̀ jọ, láti ja ìjà àjàkẹ́yìn tó fẹ́ fi pa àwọn tó ń sin Ọlọ́run ní ẹ̀mí àti òtítọ́ run.—Ka Ìsíkíẹ́lì 38:2, 8, 9, 16.
Ohun Tó Jẹ Ásáfù Lógún Jù
6, 7. (a) Kí ni Ásáfù béèrè ní ìbẹ̀rẹ̀ àdúrà rẹ̀ ní Sáàmù 83? (b) Kí ló jẹ Ásáfù lógún jù?
6 Fetí sílẹ̀, kó o gbọ́ bí Ásáfù ṣe sọ bọ́rọ̀ ṣe rí lára rẹ̀ nínú àdúrà tó gbà. Ó ní: “Ọlọ́run, má ṣe jẹ́ kí ìdákẹ́jẹ́ẹ́ wà níhà ọ̀dọ̀ rẹ; má ṣe máa bá a nìṣó ní ṣíṣàìsọ̀rọ̀, má sì dúró jẹ́ẹ́, Olú Ọ̀run. Nítorí, wò ó! àní àwọn ọ̀tá rẹ wà nínú ìrọ́kẹ̀kẹ̀; àní àwọn tí ó kórìíra rẹ lọ́nà gbígbóná janjan ti gbé orí wọn sókè. Wọ́n ń bá ọ̀rọ̀ àṣírí wọn lọ lọ́nà àlùmọ̀kọ́rọ́yí lòdì sí àwọn ènìyàn rẹ . . . Nítorí pé wọ́n ti fi ọkàn-àyà gbìmọ̀ pọ̀ ní ìsopọ̀ṣọ̀kan; àní wọ́n tẹ̀ síwájú láti dá májẹ̀mú lòdì sí ọ.”—Sm. 83:1-3, 5.
7 Kí ló jẹ Ásáfù lógún jù? Kò sí àní-àní pé ó ṣàníyàn gidigidi nípa ààbò òun àti ìdílé rẹ̀. Àmọ́, ohun tí àdúrà rẹ̀ dá lé ni ẹ̀gàn táwọn èèyàn mú bá orúkọ Jèhófà àti bí wọ́n ṣe ń gbógun ti àwọn èèyàn Jèhófà. Ẹ jẹ́ kí ohun tó jẹ́ Ásáfù lógún yẹn jẹ àwa náà lógún bá a ṣe ń fara da àkókò lílekoko ti àwọn ọjọ́ ìkẹyìn tó ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin yìí.—Ka Mátíù 6:9, 10.
8. Kí nìdí táwọn orílẹ̀-èdè fi gbìmọ̀ pọ̀ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì?
8 Ásáfù sọ ohun táwọn ọ̀tá Ísírẹ́lì sọ, ó ní: “Ẹ wá, ẹ sì jẹ́ kí a pa wọ́n rẹ́ kúrò ní jíjẹ́ orílẹ̀-èdè, kí a má bàa rántí orúkọ Ísírẹ́lì mọ́.” (Sm. 83:4) Àwọn ọ̀tá wọ̀nyẹn mà kórìíra àwọn èèyàn Ọlọ́run gan-an o! Àmọ́, ìdí mìíràn tún wà tí wọ́n fi gbìmọ̀ pọ̀ láti gbéjà ko orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Ìdí náà ni pé ilẹ̀ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ̀ wọ́n lójú, wọ́n wá sọ pé: “Ẹ jẹ́ kí a gba àwọn ibi gbígbé Ọlọ́run fún ara wa.” (Sm. 83:12) Ǹjẹ́ ohun tó fara jọ ìyẹn ń ṣẹlẹ̀ lónìí? Bẹ́ẹ̀ ni, ó kúkú ń ṣẹlẹ̀!
“Ibi Gbígbé Rẹ Mímọ́”
9, 10. (a) Nígbà àtijọ́, kí ni ibùgbé Ọlọ́run tó jẹ́ mímọ́? (b) Ìbùkún wo ni ìyókù àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn “àgùntàn mìíràn” ń gbádùn lóde òní?
9 Nígbà àtijọ́, ibùgbé mímọ́ Ọlọ́run ni wọ́n ń pe Ilẹ̀ Ìlérí. Ẹ rántí pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kọ orín ìṣẹ́gun kan nígbà tí Jèhófà dá wọn nídè kúrò ní Íjíbítì. Orin náà sọ pé: “Nínú inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́, ìwọ ti ṣamọ̀nà àwọn ènìyàn tí ìwọ gbà sílẹ̀; ìwọ nínú okun rẹ yóò darí wọn lọ sí ibi gbígbé rẹ mímọ́ dájúdájú.” (Ẹ́kís. 15:13) Nígbà tó yá, wọ́n kọ́ tẹ́ńpìlì kan sí “ibi gbígbé” yẹn táwọn àlùfáà wà níbẹ̀, tí Jerúsálẹ́mù sì jẹ́ olú-ìlú rẹ̀. Àwọn ọba tó wá láti ìlà ìdílé Dáfídì sì wà níbẹ̀, tí wọ́n ń jókòó sórí ìtẹ́ Jèhófà. (1 Kíró. 29:23) Abájọ tí Jésù fi pe Jerúsálẹ́mù ní “Ìlú ńlá ti Ọba ńlá náà.”—Mát. 5:35.
10 Lóde òní ńkọ́? Lọ́dún 33 Sànmánì Kristẹni, a bí orílẹ̀-èdè tuntun kan, ìyẹn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run.” (Gál. 6:16) Àwọn arákùnrin Jésù Kristi tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ló para pọ̀ di orílẹ̀-èdè tuntun yìí. Wọ́n sì ń ṣe iṣẹ́ tí orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kọ̀ láti ṣe, ìyẹn iṣẹ́ jíjẹ́rìí sí orúkọ Ọlọ́run. (Aísá. 43:10; 1 Pét. 2:9) Ìlérí tí Jèhófà ṣe fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì àtijọ́ ló ṣe fún orílẹ̀-èdè tuntun yìí náà. Ó sọ pé: “Èmi yóò sì jẹ́ Ọlọ́run wọn, wọn yóò sì jẹ́ ènìyàn mi.” (2 Kọ́r. 6:16; Léf. 26:12) Lọ́dún 1919, Jèhófà mú àṣẹ́kù àwọn “Ísírẹ́lì Ọlọ́run” wọnú àjọṣe àrà ọ̀tọ̀ kan pẹ̀lú rẹ̀. Nígbà yẹn, wọ́n gba “ilẹ̀” kan, níbi tí ìgbòkègbodò tẹ̀mí ti ń lọ ní pẹrẹu, tí wọ́n sì ń gbádùn Párádísè tẹ̀mí. (Aísá. 66:8) Láti àwọn ọdún 1930 ni àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn “àgùntàn mìíràn” sì ti ń dara pọ̀ mọ́ wọn. (Jòh. 10:16) Ayọ̀ àti aásìkí tẹ̀mí táwọn Kristẹni òde òní ní jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ ọba aláṣẹ láyé àtọ̀run. (Ka Sáàmù 91:1, 2.) Abájọ tínú fi ń bí Sátánì burúkú-burúkú!
11. Kí lohun tó wà lórí ẹ̀mí àwọn ọ̀tá Ọlọ́run?
11 Látìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọjọ́ ìkẹyìn yìí ni Sátánì ti ń kó sí àwọn tó ń ṣèfẹ́ rẹ̀ nínú láti gbéjà ko ìyókù àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn àgùntàn mìíràn tí wọ́n jẹ́ alábàákẹ́gbẹ́ wọn. Wọ́n dojú kọ irú àtakò yìí ní Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù lábẹ́ ìjọba Násì àti ní Ìlà Oòrùn Yúróòpù lábẹ́ ìjọba Kọ́múníìsì ti Ìjọba Soviet. Bákan náà, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ tún ṣẹlẹ̀ láwọn ilẹ̀ mìíràn. Kò sì tíì parí o, irú ẹ̀ ṣì tún máa ṣẹlẹ̀, pàápàá jù lọ nígbà tí Gọ́ọ̀gù ti ilẹ̀ Mágọ́gù bá máa gbógun àjàkẹ́yìn ja àwọn èèyàn Jèhófà. Nígbà tí àtakò yẹn bá máa ṣẹlẹ̀, àwọn ọ̀tá lè fi ìwàǹwára gba àwọn nǹkan ìní àwọn èèyàn Jèhófà, gẹ́gẹ́ báwọn ọ̀tá ti ṣe nígbà kan. Ohun tó wà lórí ẹ̀mí Sátánì ni pé kó tú àwa èèyàn Ọlọ́run ká, kí orúkọ tí Ọlọ́run fún wa, ìyẹn “Ẹlẹ́rìí Jèhófà” bàa lè di ohun ìgbàgbé. Kí ni Jèhófà máa ṣe sí àtakò tí Sátánì ń gbé dìde sí i pé kò lẹ́tọ̀ọ́ láti jẹ́ Ọba Aláṣẹ láyé àtọ̀run yìí? Ẹ jẹ́ ká tún ṣàgbéyẹ̀wò Sáàmù 83 yẹn.
Àpẹẹrẹ Kan Tó Fi Hàn Pé Aṣẹ́gun Ni Jèhófà
12-14. Ìṣẹ́gun méjì tó gbàfiyèsí wo ló wáyé nílùú Mẹ́gídò tí Ásáfù ṣàkọsílẹ̀ rẹ̀?
12 Kíyè sí i pé Ásáfù nígbàgbọ́ tó lágbára pé Jèhófà lè sọ ìmọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó lẹ̀dí àpò pọ̀ láti gbéjà ko àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dòfo. Ó sọ nípa ìgbà méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá lọ́nà tó kàmàmà nítòsí ìlú Mẹ́gídò ayé ọjọ́un, tó wà ní àfonífojì kan tó ń jẹ́ Mẹ́gídò. Nígbà ẹ̀ẹ̀rùn, èèyàn lè rí ìsàlẹ̀ Odò Kíṣónì tó lọ́ kọ́lọkọ̀lọ gba àfonífojì náà. Tí òjò bá rọ̀ nígbà òtútù, odò náà máa ń ya lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Mẹ́gídò. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìdí nìyẹn tí wọ́n tún fi ń pe odò yẹn ní “omi Mẹ́gídò.”—Oníd. 4:13; 5:19.
13 Nǹkan bíi kìlómítà mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí àfonífojì Mẹ́gídò ni òkè Mórè wà. Nígbà ayé Gídíónì Onídàájọ́, òkè yìí ni ẹgbẹ́ ọmọ ogun Mídíánì, Ámálékì àtàwọn Ará Ìlà Oòrùn kóra jọ pọ̀ sí láti bá àwọn èèyàn Jèhófà jagun. (Oníd. 7:1, 12) Nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ Jèhófà, àwọn ọmọ ogun Gídíónì tó jẹ́ ọ̀ọ́dúnrún péré ṣẹ́gun àgbo ọmọ ogun ọ̀tá tí wọ́n pọ̀ gan-an. Kí ló mú kí wọ́n borí? Wọ́n tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tí Ọlọ́run fún wọn. Wọ́n yí ibùdó àwọn ọ̀tá ká ní òru, wọ́n mú ìṣà dání, wọ́n sì fi àwọn ògùṣọ̀ oníná pa mọ́ sínú àwọn ìṣà náà. Nígbà tí Gídíónì fọwọ́ ṣe àmì sáwọn ọmọ ogun rẹ̀, wọ́n fọ́ àwọn ìṣà náà, àwọn ògùṣọ̀ oníná tó wà nínú àwọn ìṣà náà sì mọ́lẹ̀ yòò. Lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n fun ìwo wọn, wọ́n sì pariwo pé: “Idà Jèhófà àti ti Gídíónì!” Ohun tí wọ́n ṣe yẹn mú kí ṣìbáṣìbo bá àwọn ọ̀tá náà, bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í pa ara wọn nìyẹn. Àwọn tí kò kú lára àwọn ọ̀tá náà sì sá lọ sí òdìkejì Odò Jọ́dánì. Láàárín àkókò náà, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mìíràn tún dara pọ̀ láti gbá tọ àwọn ọmọ ogun ọ̀tá náà. Lápapọ̀, àwọn ọmọ ogun ọ̀tá tí iye wọn jẹ́ ọ̀kẹ́ mẹ́fà [120,000] ni wọ́n pa.—Oníd. 7:19-25; 8:10.
14 Téèyàn bá gbéra láti Mẹ́gídò tó ń lọ sí òkè Mórè, nǹkan bíi kìlómítà mẹ́fà ní ìkọjá òkè Mórè ni Òkè Tábórì wà. Ibẹ̀ ni Bárákì Onídàájọ́ kó àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí wọ́n jẹ́ ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá jọ sí nígbà kan rí, láti bá àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun Jábínì jà, ìyẹn ọba Hásórì tó jẹ́ ọmọ Kénáánì, tí ọ̀gágun rẹ̀ ń jẹ́ Sísérà. Àwọn ọmọ ogun Kénáánì yẹn ní ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án kẹ̀kẹ́ ẹṣin onídòjé irin tó lè ṣekú pani. Nígbà táwọn ọmọ ogun Sísérà rí àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì tí wọn ò fi bẹ́ẹ̀ dira ogun tí wọ́n pé jọ sórí Òkè Tábórì, èyí mú kí wọ́n sọ̀ kalẹ̀ lọ sínú àfonífojì náà láti gòkè lọ bá àwọn ọmọ ogun Ísírẹ́lì. Lẹ́yìn náà, “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí . . . kó Sísérà àti gbogbo kẹ̀kẹ́ ẹṣin ogun rẹ̀ àti gbogbo ibùdó náà sínú ìdàrúdàpọ̀.” Lójijì ni òjò tún wá bẹ̀rẹ̀ sí í rọ̀, èyí tó mú káwọn kẹ̀kẹ́ ẹṣin àwọn ọmọ ogun Kénáánì rì sínú ẹrẹ̀, nítorí pé Odò Kíṣónì ti kún àkúnya. Báwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe pa gbogbo àwọn ọmọ ogun Sísérà pátá nìyẹn.—Oníd. 4:13-16; 5:19-21.
15. (a) Kí ni Ásáfù gbàdúrà pé kí Jèhófà ṣe? (b) Kí ni orúkọ ogun àjàkẹ́yìn tí Jèhófà máa bá ayé Sátánì jà rán wa létí rẹ̀?
15 Ásáfù wá bẹ Jèhófà pé kó ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀ fáwọn ọ̀tá tó ń halẹ̀ mọ́ orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì nígbà ayé rẹ̀. Ó gbàdúrà pé: “Ṣe wọ́n bí ti Mídíánì, bí ti Sísérà, bí ti Jábínì ní àfonífojì olójú ọ̀gbàrá ti Kíṣónì. A pa wọ́n rẹ́ ráúráú ní Ẹ́ń-dórì; wọ́n di ajílẹ̀ fún ilẹ̀.” (Sm. 83:9, 10) Ó gbàfiyèsí pé Bíbélì pe ogun àjàkẹ́yìn tí Ọlọrun máa bá ayé Sátánì jà ní Ha–Mágẹ́dọ́nì (èyí tó túmọ̀ sí “Òkè Mẹ́gídò), tàbí Amágẹ́dọ́nì. Orúkọ yẹn rán wa létí àwọn ogun pípabanbarì tó wáyé nítòsí Mẹ́gídò. Bí Jèhófà ṣe ṣẹ́gun nígbà àwọn ogun àtijọ́ yẹn mú kó dá wa lójú pé Jèhófà yóò borí nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì.—Ìṣí. 16:13-16.
Máa Gbàdúrà fún Ìdáláre Jèhófà Gẹ́gẹ́ Bí Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run
16. Báwo làwọn ọ̀tá ṣe ń kan “àbùkù” lóde òní?
16 Látìbẹ̀rẹ̀ “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” tá a wà yìí ni Jèhófà ti ń sọ gbogbo ìsapá àwọn ọ̀tá di asán, pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe ń sapá tó láti pa àwọn èèyàn rẹ̀ run. (2 Tím. 3:1) Àbùkù ni èyí sì máa ń yọrí sí fáwọn ọ̀tá. Sáàmù 83:16 sọ nípa èyí, ó ní: “Fi àbùkù kún ojú wọn, kí àwọn ènìyàn lè máa wá orúkọ rẹ, Jèhófà.” Ní gbogbo orílẹ̀-èdè ni àwọn ọ̀tá tó ń sapá láti pa àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́nu mọ́ ti ǹ pòfo. Láwọn orílẹ̀-èdè yẹn, dídúró táwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà dúró láìyẹsẹ̀ àti ìfaradà tí wọ́n ní ti jẹ́rìí fáwọn olóòótọ́ ọkàn, ọ̀pọ̀ lára wọn sì ti ‘wá orúkọ Jèhófà.’ Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà rí màbo nígbà kan rí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn èèyàn ló ń fayọ̀ yin Jèhófà níbẹ̀ báyìí. Ẹ ò rí i pé Jèhófà ti ṣẹ́gun lóòótọ́! Àbùkù gbáà lèyí sì jẹ́ fáwọn ọ̀tá rẹ̀!—Ka Jeremáyà 1:19.
17. Àǹfààní wo ni kò ní pẹ́ dópin, àdúrà wo la sì máa rántí láìpẹ́?
17 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àtakò táwọn ọ̀tá ń ṣe sí wa kò tíì parí, síbẹ̀ náà, à ń bá a nìṣó láti máa wàásù, àní fáwọn ọ̀tá pàápàá. (Mát. 24:14, 21) Àmọ́ ṣá o, àǹfààní táwọn ọ̀tá náà ní láti ronú pìwà dà kí wọ́n lè rí ìgbàlà, kò ní pẹ́ dópin, nítorí pé sísọ orúkọ Jèhófà di mímọ́ ṣe pàtàkì gan-an ju ìgbàlà àwọn èèyàn. (Ka Ìsíkíẹ́lì 38:23.) Nígbà tí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé bá kóra wọn jọ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run rẹ́, gẹ́gẹ́ bí Bíbélì ti sọ, a óò rántí àdúrà tí Ásáfù gbà pé: “Kí ojú tì wọ́n, kí a sì yọ wọ́n lẹ́nu ní ìgbà gbogbo, kí wọ́n sì tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé.”—Sm. 83:17.
18, 19. (a) Kí ló máa gbẹ̀yìn àwọn olóríkunkun tó ń ta ko Jèhófà, ọba aláṣẹ ayé àtọ̀run? (b) Níwọ̀n bí a ó ti dá Jèhófà láre gẹ́gẹ́ bí Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run láìpẹ́, kí ló yẹ kí o máa ṣe?
18 Ẹ̀tẹ́ ló máa gbẹ̀yìn àwọn olóríkunkun tó ń ta ko Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run jẹ́ ká mọ̀ pé “ìparun àìnípẹ̀kun” ló máa jẹ́ ti àwọn tí “kò ṣègbọràn sí ìhìn rere,” tí wọ́n sì wá tipa bẹ́ẹ̀ pa rún ní ogun Amágẹ́dọ́nì. (2 Tẹs. 1:7-9) Bó ṣe jẹ́ pé Jèhófà máa pa àwọn wọ̀nyí run, tó sì máa gba àwọn tó ń fòtítọ́ sìn ín là, jẹ́ ẹ̀rí tó lágbára pé Jèhófà ni Ọlọrun tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Nínú ayé tuntun, títí láé la ó máa rántí ìṣẹ́gun ńlá yẹn! Àwọn tó bá pa dà wá sí ìyè nígbà “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo” yóò gbọ́ nípa iṣẹ́ àrà Jèhófà. (Ìṣe 24:15) Nínú ayé tuntun, wọn yóò rí ẹ̀rí tó lágbára pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ láti wà lábẹ́ Jèhófà, Ọba Aláṣẹ ayé àtọ̀run. Àwọn tó sì jẹ́ ọlọ́kàn tútù nínú wọn yóò tètè gbà pé Jèhófà ni Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà.
19 Ẹ ò rí i pé ohun àgbàyanu gbáà ni Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ti pèsè sílẹ̀ fáwọn tó ń fòótọ́ sìn ín! Láìsí àní-àní, ó yẹ kí èyí sún wa láti máa gbàdúrà pé kí Jèhófà tètè dáhùn àdúrà tí Ásáfù gbà, pé: “Kí ojú tì wọ́n, kí a sì yọ wọ́n lẹ́nu ní ìgbà gbogbo, kí wọ́n sì tẹ́, kí wọ́n sì ṣègbé; kí àwọn ènìyàn lè mọ̀ pé ìwọ, ẹni tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Jèhófà, ìwọ nìkan ṣoṣo ni Ẹni Gíga Jù Lọ lórí gbogbo ilẹ̀ ayé.”—Sm. 83:17, 18.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá kọ́kọ́ ka Sáàmù 83 kó o tó máa ka àpilẹ̀kọ yìí lọ, èyí á ṣe ọ́ láǹfààní, nítorí pé yóò jẹ́ kó o mọ ohun tó wà nínú àwọn ẹsẹ yẹn dáadáa.
Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?
• Ipò wo làwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nígbà tí Ásáfù kọ Sáàmù 83?
• Kí ló jẹ ẹni tó kọ Sáàmù 83 lógún jù?
• Àwọn wo ni Sátánì ń gbógun tì lóde òní?
• Báwo ni Jèhófà yóò ṣe dáhùn àdúrà tó wà ní Sáàmù 83:18 níkẹyìn?
[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Báwo làwọn ogun tí wọ́n jà nítòsí ìlú Mẹ́gídò láyé ọjọ́un ṣe kan ọjọ́ ọ̀la wa?
Odò Kíṣónì
Háróṣétì
Òkè Kámẹ́lì
Àfonífojì Jésíréélì
Mẹ́gídò
Táánákì
Òkè Gíbóà
Kànga Háródù
Mórè
Ẹ́ń-dórì
Òkè Tábórì
Òkun Gálílì
Odò Jọ́dánì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Kí ló mú kí ọ̀kan lára àwọn tó kọ ìwé Sáàmù ṣàkọsílẹ̀ àdúrà àtọkànwá kan?