Àìsáyà
51 “Ẹ fetí sí mi, ẹ̀yin tí ẹ̀ ń lépa òdodo,
Ẹ̀yin tí ẹ̀ ń wá Jèhófà.
Ẹ yíjú sí àpáta tí a ti gbẹ́ yín jáde
Àti ibi tí wọ́n ti ń wa òkúta, tí a ti wà yín jáde.
2 Ẹ yíjú sí Ábúráhámù bàbá yín
3 Torí Jèhófà máa tu Síónì nínú.+
Ó máa tu gbogbo àwókù rẹ̀ nínú,+
Ó máa mú kí aginjù rẹ̀ rí bí Édẹ́nì,+
Ó sì máa mú kí aṣálẹ̀ rẹ̀ tó tẹ́jú rí bí ọgbà Jèhófà.+
Ìdùnnú àti ayọ̀ máa wà níbẹ̀,
Ìdúpẹ́ àti orin tó dùn.+
Torí òfin kan máa jáde látọ̀dọ̀ mi,+
Màá sì mú kí ìdájọ́ òdodo mi fìdí múlẹ̀ bí ìmọ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn.+
6 Ẹ gbé ojú yín sókè sí ọ̀run,
Kí ẹ sì wo ayé nísàlẹ̀.
Torí pé ọ̀run máa fẹ́ lọ bí èéfín;
Ayé máa gbó bí aṣọ,
Àwọn tó ń gbé ibẹ̀ sì máa kú bíi kòkòrò abìyẹ́ tó ń mùjẹ̀.
Ẹ má bẹ̀rù bí àwọn ẹni kíkú ṣe ń pẹ̀gàn yín,
Ẹ má sì jẹ́ kí èébú wọn kó jìnnìjìnnì bá yín.
Àmọ́ òdodo mi máa wà títí láé,
Ìgbàlà mi sì máa wà jálẹ̀ gbogbo ìran.”+
Jí, bíi ti àwọn ọjọ́ tó ti pẹ́, bíi ti àwọn ìran tó ti kọjá.
10 Ṣebí ìwọ lo mú kí òkun gbẹ, alagbalúgbú omi inú ibú?+
Ṣebí ìwọ lo sọ ibú òkun di ọ̀nà, tí àwọn tí a tún rà gbà sọdá?+
11 Àwọn tí Jèhófà rà pa dà máa pa dà.+
Ìdùnnú àti ayọ̀ máa jẹ́ tiwọn,
Ẹ̀dùn ọkàn àti ìbànújẹ́ sì máa fò lọ.+
12 “Èmi fúnra mi ni Ẹni tó ń tù yín nínú.+
Ṣé ó wá yẹ kí ẹ máa bẹ̀rù ẹni kíkú tó máa kú+
Àti ọmọ aráyé tó máa rọ bíi koríko tútù?
Ò ń bẹ̀rù ìbínú aninilára* ṣáá láti àárọ̀ ṣúlẹ̀,
Àfi bíi pé ó láṣẹ láti pa ọ́ run.
Ibo wá ni ìbínú aninilára wà?
14 Wọ́n máa tó dá ẹni tí wọ́n fi ẹ̀wọ̀n dè, tó sì tẹ̀ ba sílẹ̀;+
Kò ní kú, kò sì ní lọ sínú kòtò,
Oúnjẹ ò sì ní wọ́n ọn.
15 Àmọ́ èmi ni Jèhófà Ọlọ́run rẹ,
Ẹni tó ń ru òkun sókè, tó sì ń mú kí ìgbì rẹ̀ máa pariwo;+
Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ni orúkọ rẹ̀.+
16 Màá fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ,
Màá sì fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́,+
Kí n lè gbé ọ̀run kalẹ̀, kí n sì fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀,+
Kí n sì sọ fún Síónì pé, ‘Èèyàn mi ni ọ́.’+
O ti mu látinú aago náà;
O ti mu ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ gbẹ.+
18 Ìkankan nínú gbogbo ọmọ tó bí kò sí níbẹ̀ láti darí rẹ̀,
Kò sì sí ìkankan nínú gbogbo ọmọ tó tọ́ dàgbà tó di ọwọ́ rẹ̀ mú.
19 Ohun méjì yìí ti dé bá ọ.
Ta ló máa bá ọ kẹ́dùn?
Ìparun àti ìsọdahoro, ebi àti idà!+
Ta ló máa tù ọ́ nínú?+
Wọ́n dùbúlẹ̀ sí gbogbo oríta* ojú ọ̀nà
Bí àgùntàn igbó tó wà nínú àwọ̀n.
Ìbínú Jèhófà kún inú wọn, ìbáwí Ọlọ́run rẹ.”
21 Torí náà, jọ̀ọ́, fetí sí èyí,
Ìwọ obìnrin tí ìyà ń jẹ, tó sì ti yó, àmọ́ tí kì í ṣe wáìnì ló mu.
22 Ohun tí Olúwa rẹ, Jèhófà sọ nìyí, Ọlọ́run rẹ, tó ń gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀:
“Wò ó! Màá gba ife tó ń múni ta gọ̀ọ́gọ̀ọ́ kúrò lọ́wọ́ rẹ,+
Aago náà, ife ìbínú mi;
O ò ní mu ún mọ́ láé.+
O wá sọ ẹ̀yìn rẹ di ilẹ̀,
Bí ojú ọ̀nà tí wọ́n máa rìn kọjá.”