Jẹ́nẹ́sísì
19 Àwọn áńgẹ́lì méjì náà dé Sódómù ní alẹ́, Lọ́ọ̀tì sì jókòó sí ẹnubodè Sódómù. Nígbà tí Lọ́ọ̀tì rí wọn, ó dìde lọ pàdé wọn, ó sì tẹrí ba mọ́lẹ̀.+ 2 Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ̀yin olúwa mi, ẹ jọ̀ọ́ ẹ yà sí ilé ìránṣẹ́ yín, kí ẹ sùn mọ́jú, ká sì fọ ẹsẹ̀ yín. Ẹ lè dìde ní ìdájí, kí ẹ sì máa lọ.” Wọ́n fèsì pé: “Rárá, ojúde ìlú la máa sùn mọ́jú.” 3 Àmọ́ kò fi wọ́n lọ́rùn sílẹ̀, títí wọ́n fi tẹ̀ lé e lọ sílé rẹ̀. Ó se àsè fún wọn, ó yan búrẹ́dì aláìwú, wọ́n sì jẹun.
4 Kí wọ́n tó dùbúlẹ̀ láti sùn, àwọn ọkùnrin ìlú náà, ìyẹn àwọn ọkùnrin Sódómù kóra jọ bíi jàǹdùkú yí ilé náà ká, gbogbo wọn látorí ọmọdé dórí àgbàlagbà. 5 Wọ́n ń pe Lọ́ọ̀tì, wọ́n sì ń sọ fún un pé: “Àwọn ọkùnrin tó wá sọ́dọ̀ rẹ ní alẹ́ yìí dà? Mú wọn jáde ká lè bá wọn lò pọ̀.”+
6 Lọ́ọ̀tì jáde lọ bá wọn ní ẹnu ọ̀nà, ó sì ti ilẹ̀kùn lẹ́yìn tó jáde. 7 Ó sọ pé: “Ẹ jọ̀ọ́, ẹ̀yin èèyàn mi, ẹ má hùwà ìkà. 8 Ẹ jọ̀ọ́, mo ní ọmọbìnrin méjì tí kò tíì bá ọkùnrin lò pọ̀ rí. Ẹ jọ̀ọ́, ẹ jẹ́ kí n mú wọn wá fún yín kí ẹ lè ṣe ohun tó wù yín sí wọn. Àmọ́ ẹ má fọwọ́ kan àwọn ọkùnrin yìí, torí abẹ́ òrùlé*+ mi ni wọ́n wá.” 9 Ni wọ́n bá sọ pé: “Kúrò lọ́nà!” Wọ́n tún sọ pé: “Ẹ wo ọkùnrin àjèjì yìí, tó wá gbé nílẹ̀ wa, ó tún láyà láti dá wa lẹ́jọ́. Wò ó, ohun tí a máa ṣe sí ọ yóò burú ju èyí tí a máa ṣe sí wọn.” Bí wọ́n ṣe ya bo* Lọ́ọ̀tì nìyẹn, wọ́n sì sún mọ́ ilẹ̀kùn kí wọ́n lè fọ́ ọ wọlé. 10 Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà nawọ́ mú Lọ́ọ̀tì wọlé sọ́dọ̀ wọn, wọ́n sì ti ilẹ̀kùn. 11 Ṣùgbọ́n wọ́n bu ìfọ́jú lu àwọn ọkùnrin tó wà ní ẹnu ọ̀nà ilé náà, látorí ẹni tó kéré jù dórí ẹni tó dàgbà jù, tó fi jẹ́ pé ó rẹ̀ wọ́n bí wọ́n ṣe ń wá ibi tí ẹnu ọ̀nà wà.
12 Ni àwọn ọkùnrin náà bá sọ fún Lọ́ọ̀tì pé: “Ṣé èèyàn rẹ kankan ṣì kù níbí? Mú ọkọ àwọn ọmọ rẹ, àwọn ọmọkùnrin rẹ, àwọn ọmọbìnrin rẹ àti gbogbo èèyàn rẹ tó bá wà nínú ìlú yìí kúrò! 13 A máa pa ìlú yìí run, torí igbe àwọn tó ń ráhùn nípa wọn ti pọ̀ gan-an* níwájú Jèhófà, ìdí nìyẹn tí Jèhófà+ fi rán wa láti pa ìlú yìí run.” 14 Lọ́ọ̀tì bá jáde lọ, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn ọkùnrin tí wọ́n fẹ́ fi àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣaya sọ̀rọ̀, ó ń sọ pé: “Ẹ dìde! Ẹ jáde kúrò níbí, torí Jèhófà máa pa ìlú yìí run!” Àmọ́ àwọn ọkùnrin náà rò pé ó kàn ń ṣàwàdà+ ni.
15 Bí ilẹ̀ ṣe ń mọ́, àwọn áńgẹ́lì náà bẹ̀rẹ̀ sí í kán Lọ́ọ̀tì lójú, wọ́n ń sọ pé: “Dìde! Mú ìyàwó rẹ àti àwọn ọmọ rẹ méjèèjì tó wà níbí pẹ̀lú rẹ, kí ẹ má bàa pa run nígbà tí ìlú+ náà bá ń jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀!” 16 Àmọ́ nígbà tó ń lọ́ra ṣáá, àwọn ọkùnrin náà gbá ọwọ́ rẹ̀ mú àti ọwọ́ ìyàwó rẹ̀ àti ọwọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì, torí Jèhófà yọ́nú sí i,+ wọ́n mú un jáde, wọ́n sì mú un wá sí ìta ìlú náà.+ 17 Bí wọ́n ṣe mú wọn dé ẹ̀yìn odi, ó sọ pé: “Ẹ sá àsálà fún ẹ̀mí* yín! Ẹ má wo ẹ̀yìn,+ ẹ má sì dúró níbikíbi ní agbègbè yìí!+ Ẹ sá lọ sí agbègbè olókè kí ẹ má bàa pa run!”
18 Torí náà, Lọ́ọ̀tì sọ fún wọn pé: “Jèhófà jọ̀ọ́, má ṣe jẹ́ kí n lọ síbẹ̀ yẹn! 19 Jọ̀ọ́, ní báyìí, ìránṣẹ́ rẹ ti rí ojúure rẹ, o sì ti ṣe inúure tó pọ̀* sí mi torí o dá ẹ̀mí* mi sí,+ àmọ́ mi ò lè sá lọ sí agbègbè olókè torí ẹ̀rù ń bà mí pé àjálù lè dé bá mi, kí n sì kú.+ 20 Jọ̀ọ́, ìlú kékeré yìí wà nítòsí, mo sì lè sá lọ síbẹ̀. Jọ̀ọ́, ṣé kí n sá lọ síbẹ̀? Ìlú kékeré ni. Mi* ò sì ní kú.” 21 Ló bá sọ fún un pé: “Ó dáa, màá tún ro tìẹ,+ mi ò sì ní run ìlú tí o sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí.+ 22 Tètè sá lọ síbẹ̀! Torí mi ò lè ṣe nǹkan kan títí wàá fi dé ibẹ̀!”+ Ìdí nìyẹn tó fi pe orúkọ ìlú náà ní Sóárì.*+
23 Oòrùn ti yọ ní ilẹ̀ náà nígbà tí Lọ́ọ̀tì dé Sóárì. 24 Jèhófà wá rọ òjò imí ọjọ́ àti iná lé Sódómù àti Gòmórà lórí, ó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, láti ọ̀run.+ 25 Ó run àwọn ìlú yìí, àní, gbogbo agbègbè náà, títí kan àwọn tó ń gbé àwọn ìlú náà àti àwọn ewéko ilẹ̀.+ 26 Àmọ́ ìyàwó Lọ́ọ̀tì tó wà lẹ́yìn rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wo ẹ̀yìn, ó sì di ọwọ̀n* iyọ̀.+
27 Ábúráhámù jí ní àárọ̀ kùtù, ó sì lọ síbi tó ti dúró níwájú Jèhófà.+ 28 Nígbà tó wo apá ibi tí Sódómù àti Gòmórà wà àti gbogbo ilẹ̀ agbègbè náà, ó rí ohun tó ṣẹlẹ̀. Ó rí èéfín tó ṣú dùdù tó ń lọ sókè ní ilẹ̀ náà, ó sì dà bí èéfín tó máa ń jáde látinú iná ìléru!+ 29 Nígbà tí Ọlọ́run pa àwọn ìlú agbègbè náà run, Ọlọ́run fi Ábúráhámù sọ́kàn nítorí ó mú Lọ́ọ̀tì kúrò nínú àwọn ìlú tó pa run, àwọn ìlú tí Lọ́ọ̀tì ń gbé.+
30 Nígbà tó yá, Lọ́ọ̀tì àti àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ méjèèjì kúrò ní Sóárì, wọ́n sì lọ ń gbé ní agbègbè olókè,+ torí ẹ̀rù ń bà á láti máa gbé ní Sóárì.+ Ó wá lọ ń gbé inú ihò, pẹ̀lú àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì. 31 Èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò rẹ̀ pé: “Bàbá wa ti darúgbó, kò sì sí ọkùnrin kankan ní ilẹ̀ yìí tó máa bá wa lò pọ̀ bí ìṣe gbogbo ayé. 32 Wá, jẹ́ ká fún bàbá wa ní wáìnì mu, ká sì sùn tì í, ká lè ní ọmọ nípasẹ̀ bàbá wa.”
33 Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n ń fún bàbá wọn ní wáìnì mu; èyí àkọ́bí wọlé, ó sì sùn ti bàbá rẹ̀, àmọ́ bàbá rẹ̀ kò mọ ìgbà tó sùn ti òun àti ìgbà tó dìde. 34 Ní ọjọ́ kejì, èyí àkọ́bí sọ fún àbúrò rẹ̀ pé: “Mo sùn ti bàbá mi lálẹ́ àná. Jẹ́ ká tún fún un ní wáìnì mu lálẹ́ òní. Kí o wọlé, kí o sì sùn tì í, ká lè ní ọmọ nípasẹ̀ bàbá wa.” 35 Torí náà, ní alẹ́ ọjọ́ yẹn, wọ́n tún fún bàbá wọn ní wáìnì mu léraléra; èyí àbúrò wá lọ sùn tì í, àmọ́ bàbá rẹ̀ kò mọ ìgbà tó sùn ti òun àti ìgbà tó dìde. 36 Àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì méjèèjì lóyún nípasẹ̀ bàbá wọn. 37 Èyí àkọ́bí bí ọmọkùnrin kan, ó pe orúkọ rẹ̀ ní Móábù.+ Òun ló wá di bàbá àwọn ọmọ Móábù.+ 38 Èyí àbúrò náà bí ọmọkùnrin kan, ó sì pe orúkọ rẹ̀ ní Bẹni-ámì. Òun ló wá di bàbá àwọn ọmọ Ámónì.+