Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé
Ọwọ́ wo ló yẹ káwọn Kristẹni fi mú ìfẹ́sọ́nà?
Níní àfẹ́sọ́nà jẹ́ nǹkan tó ń múnú ẹni dùn, ṣùgbọ́n ọ̀ràn pàtàkì ni. Kristẹni kan tó ti dàgbà dénú ò gbọdọ̀ fi ìfẹ́sọ́nà ṣe ọ̀ràn ṣeréṣeré, kó rò pé ìgbàkigbà lòun lè fòpin sí i láìnídìí tó ṣe gúnmọ́. Àkókò ìfẹ́sọ́nà tún jẹ́ àkókò tí àwọn tí ń fẹ́ra wọn sọ́nà lè lò láti mọ ara wọn dáadáa, kí wọ́n tó ṣègbéyàwó.
Nínú kókó táà ń jíròrò yìí, ó yẹ ká rántí pé àwọn àṣà ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà tó wé mọ́ ìgbéyàwó, àti àwọn ìgbésẹ̀ tó ń ṣáájú ìgbéyàwó, yàtọ̀ síra gidigidi láti àgbègbè kan sí ìkejì, àkókò tí à ń ṣe wọ́n sì yàtọ̀ pẹ̀lú. Bíbélì ṣàlàyé èyí.
Ó jọ pé àwọn ọkùnrin méjì kan wà ládùúgbò, tí wọ́n ń fẹ́ àwọn ọmọbìnrin Lọ́ọ̀tì, “tí wọn kò tíì ní ìbádàpọ̀ pẹ̀lú ọkùnrin,” sọ́nà. ‘Àwọn ọkọ ọmọ Lọ́ọ̀tì ni yóò mú àwọn ọmọbìnrin rẹ̀ ṣe aya’ síbẹ̀ Bíbélì kò sọ ohun tó pilẹ̀ ìfẹ́rasọ́nà náà, kò sì sọ bó ṣe bẹ̀rẹ̀. Ṣé àwọn ọmọbìnrin náà ti di ọmọge? Ǹjẹ́ wọ́n lẹ́nu ọ̀rọ̀ láti yan ẹni tí wọ́n fẹ́ fẹ́? Ṣé gbígbé àwọn ìgbésẹ̀ tó sọ ọ̀rọ̀ náà di ohun tí àwọn èèyàn mọ̀ nípa rẹ̀ ló jẹ́ kí fífẹ́ ara wọn sọ́nà fẹsẹ̀ múlẹ̀ ni? A ò mọ̀ o. (Jẹ́nẹ́sísì 19:8-14) Ohun táa mọ̀ ni pé Jékọ́bù bá baba Rákélì ṣèlérí láti fẹ́ Rákélì lẹ́yìn tó bá bá a ṣiṣẹ́ fún ọdún méje. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jékọ́bù pe Rákélì ni “aya mi,” wọn kò tí ì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbálòpọ̀ ní àwọn ọdún wọ̀nyẹn. (Jẹ́nẹ́sísì 29:18-21) Àpẹẹrẹ mìíràn nìyí, kó tó di pé Dáfídì fẹ́ ọmọ Sọ́ọ̀lù, ó ní láti ṣẹ́gun àwọn Filísínì. Ìgbà tí Dáfídì sì ṣe ohun tí Sọ́ọ̀lù fẹ́ kó ṣe tán, ló tó lè fẹ́ Míkálì, ọmọ rẹ̀. (1 Sámúẹ́lì 18:20-28) “Ìfẹ́sọ́nà” wọ̀nyẹn yàtọ̀ láti ibì kan sí ìkejì, ó sì yàtọ̀ sí ohun tó ń sábà ṣẹlẹ̀ ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ lónìí.
Òfin Mósè ní àwọn ìlànà tó kan ìgbéyàwó àti ìfẹ́sọ́nà. Fún àpẹẹrẹ, ọkùnrin kan lè ní ju aya kan lọ; ó lè jáwèé ìkọ̀sílẹ̀ lórí onírúurú ẹ̀sùn, ṣùgbọ́n aya kan kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. (Ẹ́kísódù 22:16, 17; Diutarónómì 24:1-4) Ọkùnrin kan tó bá wúńdíá kan tí kò tí ì ní àfẹ́sọ́nà lò pọ̀ gbọ́dọ̀ fẹ́ ẹ, ìyẹn bí baba rẹ̀ bá gbà bẹ́ẹ̀, kò sì gbọ́dọ̀ kọ̀ ọ́ sílẹ̀. (Diutarónómì 22:28, 29) Àwọn òfin mìíràn tún wà tó kan ìgbéyàwó, irú èyí tó sọ̀rọ̀ nípa àkókò yíyẹra fún ìbálòpọ̀. (Léfítíkù 12:2, 5; 15:24; 18:19) Àwọn òfin wo ló wà fún ìfẹ́sọ́nà?
Lábẹ́ òfin, ojú tí a fi ń wo ọmọbìnrin Ísírẹ́lì kan tó ti ní àfẹ́sọ́nà yàtọ̀ sí èyí táa fi ń wo obìnrin kan tí kò tí ì ní; láwọn ọ̀nà kan a ti ka ẹni tó ti ní àfẹ́sọ́nà sí ẹni tó ti ṣègbéyàwó. (Diutarónómì 22:23-29; Mátíù 1:18, 19) Àwọn ìbátan kan wà tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kò lè bá wọnú àdéhùn àtifẹ́ tàbí kí wọ́n bá ṣègbéyàwó. Lọ́pọ̀ ìgbà àwọn wọ̀nyí máa ń jẹ́ àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ mọ̀lẹ́bí, ṣùgbọ́n a fòfin de oríṣi ìfẹ́sọ́nà àti ìgbéyàwó kan nítorí ẹ̀tọ́ ogún. (Léfítíkù 18:6-20; wo Ilé Ìṣọ́ September 15, 1978, ojú ìwé 16.) Ó ṣe kedere pé kò yẹ kí àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run fojú kéré ọ̀ràn ìfẹ́sọ́nà.
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà lábẹ́ gbogbo irú Òfin bẹ́ẹ̀, ṣùgbọ́n àwọn Kristẹni kò sí lábẹ́ Òfin yẹn, títí kan ìlànà rẹ̀ nípa ìfẹ́sọ́nà tàbí ìgbéyàwó. (Róòmù 7:4, 6; Éfésù 2;15; Hébérù 8:6, 13) Àní, Jésù kọ́ni pé àwọn àṣà Kristẹni tó ní í ṣe pẹ̀lú ìgbéyàwó yàtọ̀ sí ti Òfin yẹn. (Mátíù 19:3-9) Síbẹ̀, kò fojú kékeré wo ọ̀ràn ìgbéyàwó, tàbí ìfẹ́sọ́nà. Nítorí náà, ti kókó táà ń gbé yẹ̀ wò ńkọ́, báwo ni ìfẹ́sọ́nà ṣe lágbára tó láàárín àwọn Kristẹni?
Ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀, olúkúlùkù ló ń yan ẹni tó bá wù ú láti fẹ́. Gbàrà tí ọkùnrin kan àti obìnrin bá ti jọ́hẹn láti fẹ́ra wọn, a ti gbà pé wọ́n ti wọnú àdéhùn nìyẹn. Lọ́pọ̀ ìgbà, a kì í béèrè ìgbésẹ̀ pàtó kan ká tó lè fìdí ìfẹ́sọ́nà múlẹ̀. Lóòótọ́, ní àwọn àgbègbè kan ó jẹ́ àṣà kí ọkùnrin náà fún àfẹ́sọ́nà rẹ̀ ní òrùka láti lè fi hàn pé àwọn ti wọnú àdéhùn. Ó sì tún jẹ́ àṣà láti sọ fún àwọn ìbátan àti ọ̀rẹ́ pé àwọn ń fẹ́ra àwọn sọ́nà, ó lè jẹ́ nígbà tí ìdílé bá ń jẹun tàbí ní àpéjọ kékeré mìíràn. Ọ̀ràn bó bá ṣe wuni lèyí, kì í ṣe pé Ìwé Mímọ́ ló ní ká ṣe bẹ́ẹ̀. Àdéhùn láàárín àwọn méjèèjì gan-an ló ń jẹ́ ìfẹ́sọ́nà.a
Kò yẹ kí Kristẹni kan kù gìrì wọnú ìfẹ́sọ́nà, tàbí ìgbéyàwó. A ti tẹ àwọn ọ̀rọ̀ tí a gbé ka Bíbélì jáde tó lè ran àwọn àpọ́n lọ́wọ́ láti pinnu bóyá ó bọ́gbọ́n mu láti bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́rasọ́nà tàbí kí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ tí yóò jálẹ̀ sí ìfẹ́sọ́nà tàbí ìgbéyàwó.b Kókó pàtàkì inú ìmọ̀ràn náà ni pé ìgbéyàwó Kristẹni, ìgbéyàwó gbére ni.—Jẹ́nẹ́sísì 2:24; Máàkù 10:6-9.
Àwọn Kristẹni méjì ní láti mọ ara wọn dáadáa ṣáájú kí wọ́n tó bẹ̀rẹ̀ sí ronú fífẹ́ ara wọn sọ́nà. Ẹnì kọ̀ọ̀kan wọn lè bi ara rẹ̀ pé, ‘Ǹjẹ́ ipò tẹ̀mí ẹni yìí àti ìfọkànsìn rẹ̀ sí Ọlọ́run dá mi lójú? Ǹjẹ́ mo rò pé èmi àti ẹni yìí lè jọ máa sin Ọlọ́run títí ayé? Ǹjẹ́ a ti mọ ìwà ara wa dáadáa? Ǹjẹ́ ó dá mi lójú pé a ó lè gbé papọ̀ títí gbére? Ǹjẹ́ a mọ̀ nípa ohun tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wa ti ṣe sẹ́yìn àti ipò ti ọ̀kọ̀ọ̀kan wa wà báyìí?’
Gbàrà tí Kristẹni méjì bá ti gbà pé àwọn yóò fẹ́ra wọn, ó tọ́ fún wọn àti fún àwọn ẹlòmíràn láti máa retí pé kí wọ́n ṣègbéyàwó. Jésù ṣíni létí pé: “Kí ọ̀rọ̀ yín Bẹ́ẹ̀ ni sáà túmọ̀ sí Bẹ́ẹ̀ ni, Bẹ́ẹ̀ kọ́ yín, Bẹ́ẹ̀ kọ́.” (Mátíù 5:37) Àwọn Kristẹni tí wọ́n bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà gbọ́dọ̀ mọ̀ pé kì í ṣe ọ̀ràn eré. Ṣùgbọ́n, nígbà mí-ìn, Kristẹni kan lè wá mọ̀ pé ohun pàtàkì kan wà tí àfẹ́sọ́nà òun kò tí ì mẹ́nu kàn tàbí pé ó fi ọ̀rọ̀ náà pa mọ́ títí tí àwọn fi gbà pé àwọn máa fẹ́ra. Ó lè jẹ́ ọ̀ràn pàtàkì kan tó ti ṣẹlẹ̀ sónítọ̀hún, ó tiẹ̀ lè jẹ́ ìwà ọ̀daràn tàbí ìṣekúṣe. Kristẹni tó bá wá mọ̀ nípa èyí ni yóò pinnu ohun tí òun yóò ṣe. Ó lè jẹ́ pé àwọn méjèèjì yóò jọ jíròrò ọ̀ràn náà kúnnákúnná, tí wọn yóò sì pinnu láti máa bá àdéhùn wọn lọ. Ó sì lè jẹ́ pé àwọn méjèèjì yóò fohùn ṣọ̀kan láti fòpin sí àdéhùn fífẹ́ra wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn fúnra wọn ni yóò pinnu èyí—kì í ṣe ọ̀ràn táwọn ẹlòmíràn yóò yọjúràn sí, tí wọn yóò máa sọ pé báyìí-ni-ẹ-ṣeé, tàbí tí wọn yóò máa dá wọn lẹ́jọ́—ìpinnu ńlá ní o. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, ẹni tí ẹnì kejì rẹ̀ sọ ọ̀ràn ńlá náà fún lè fúnra rẹ̀ rí i pé ó pọndandan fún òun láti fòpin sí àdéhùn tó wà láàárín àwọn méjèèjì, kódà bí ẹnì kejì bá ṣì fẹ́ kí wọ́n máa bá a lọ.—Wo “Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 1976.
Ó dáa púpọ̀ láti yanjú irú àwọn ọ̀rọ̀ bẹ́ẹ̀ ká tó wọnú ìgbéyàwó. Jésù wí pé kìkì ohun tí Ìwé Mímọ́ gbà pé ó lè fa ìkọ̀sílẹ̀ tó fàyè gba kí ẹnì kan gbé ẹlòmíràn níyàwó ni por·neiʹa, ìyẹn ni ìṣekúṣe tó lékenkà látọ̀dọ̀ ọ̀kan lára tọkọtaya. (Mátíù 5:32; 19:9) Kò sọ pé bí ẹnì kan bá gbọ́ nípa ìṣòro ńlá kan tàbí ìwà àìtọ́ tẹ́nì kan ti hù kó to ṣègbéyàwó, ó lè fòpin sí ìgbéyàwó táa ti ṣe lábẹ́ òfin.
Fún àpẹẹrẹ, nígbà ayé Jésù, ó ṣòro kí ẹnì kan tó lè kó àrùn ẹ̀tẹ̀. Bí ọkọ kan tó jẹ́ Júù bá gbọ́ pé aya òun jẹ́ adẹ́tẹ̀ nígbà to fẹ́ ẹ (ì báà jẹ́ pé ó jogún àrùn náà ni o, tàbí ó ṣàdédé kọ lù ú), ǹjẹ́ o lẹ́tọ̀ọ́ àtikọ̀ ọ́ sílẹ̀? Lábẹ́ Òfin, Júù kan lè kọ irú ẹni bẹ́ẹ̀ sílẹ̀, ṣùgbọ́n Jésù kò sọ pé èyí jẹ́ ohun tó yẹ kí àwọn ọmọlẹ́yìn òun ṣe. Gbé àwọn ipò òde òní kan yẹ̀ wò. Ọkùnrin kan tó lárùn rẹ́kórẹ́kó, ìléròrò ẹ̀yà ìbímọ, àrùn éèdì, tàbí àwọn àrùn mìíràn tó lè tètè ranni lè ṣègbéyàwó láìsọ ọ́ fẹ́ni tó ń fẹ́. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ó kó àrùn náà níbi ìṣekúṣe kó tó bẹ̀rẹ̀ ìfẹ́sọ́nà tàbí nígbà ìfẹ́sọ́nà. Gbígbọ́ tí aya náà wá gbọ́ nípa àrùn ọkọ rẹ̀ tàbí ìṣekúṣe tó ti ń ṣe kiri tẹ́lẹ̀ (kódà ká ní ṣe ló tiẹ̀ wá mọ̀ pé ọkọ náà kò lè bímọ tàbí pé akúra ni) kò fòpin sí ìgbéyàwó tí wọ́n ṣe. Àwọn ohun tí kò bára dé tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn ṣáájú ìgbéyàwó kì í ṣe ìdí tí ó bá Ìwé Mímọ́ mu fún fífòpin sí ìgbéyàwó, ì báà ti kó àwọn àrùn kan tàbí kó bo oyún tí ọkùnrin mìíràn ti fún un mọ́ra kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Wọ́n ti ṣègbéyàwó báyìí, wọ́n sì ti bá ara wọn jẹ́jẹ̀ẹ́.
Lóòótọ́, irú ipò bíbani nínú jẹ́ bẹ́ẹ̀ kò wọ́pọ̀, ṣùgbọ́n àwọn àpẹẹrẹ wọ̀nyí yẹ kí wọ́n túbọ̀ tẹnu mọ́ kókó pàtàkì náà pé: A ò gbọ́dọ̀ fọwọ́ dẹngbẹrẹ mú ìfẹ́rasọ́nà. Ṣáájú kí àwọn Kristẹni tó wọnú àdéhùn fífẹ́ra àti nígbà tí wọ́n bá ń fẹ́ra wọn sọ́nà, wọ́n gbọ́dọ̀ sapá láti mọ ara wọn dáadáa. Wọ́n gbọ́dọ̀ sòótọ́ tí ẹnì kejì wọ́n fẹ́ mọ̀ jáde tàbí tó lẹ́tọ̀ọ́ láti mọ̀. (Ní àwọn ilẹ̀ kan, òfin ń béèrè pé kí àwọn ẹni méjì tó ń fẹ́ra sọ́nà lọ ṣàyẹ̀wò ìṣègùn kí wọ́n tó ṣègbéyàwó. Àwọn mìíràn lè fẹ́ ṣe irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ fún ìsọfúnni ti ara wọn.) Bọ́ràn bá rí báyìí, ayọ̀ fífẹ́ra sọ́nà àti fífọwọ́ dan-in dan-in mú un yóò jẹ́ fún ète tí ó lọ́lá, bí àwọn méjèèjì ti ń bọ́ sínú ipò tí ó láyọ̀ sí i, tó sì túbọ̀ ṣe pàtàkì sí i, ìyẹn ni ipò ìgbéyàwó.—Òwe 5:18, 19; Éfésù 5:33.
[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ní àwọn àwùjọ kan, àwọn òbí ló ṣì ń ṣètò fún ẹni ti yóò fẹ́ ọmọ wọn tàbí tí ọmọ wọn yóò fẹ́. Wọ́n lè ṣe èyí nígbà tó bá kù díẹ̀ káwọn ọmọ méjèèjì ṣègbéyàwó. Láàárín àkókò yìí, a óò gbà pé wọ́n ti ń fẹ́ra wọn sọ́nà, tàbí wọ́n ti jọ́hẹn fúnra wọn, àmọ́ ṣá o, wọn kò tí ì ṣègbéyàwó.
b Wo Awọn Ìbéèrè Tí Awọn Ọ̀dọ́ Ń Béèrè, orí 28 sí 32, àti Àṣírí Ayọ̀ Ìdílé, orí 2, tí Watchtower Bible and Tract Society of New York, Inc., tẹ̀ jáde.