Sí Àwọn Ará Gálátíà
3 Ẹ̀yin aláìnírònú ará Gálátíà! Ta ló tàn yín sínú ìwà ibi yìí,+ ẹ̀yin tó hàn sí kedere pé a kan Jésù Kristi mọ́gi?+ 2 Ohun kan tí mo fẹ́ bi yín* ni pé: Ṣé ipasẹ̀ àwọn iṣẹ́ òfin lẹ fi gba ẹ̀mí ni àbí nítorí pé ẹ nígbàgbọ́ nínú ohun tí ẹ gbọ́?+ 3 Ṣé bẹ́ẹ̀ lẹ ya aláìnírònú tó ni? Lẹ́yìn tí ẹ ti bẹ̀rẹ̀ ní ọ̀nà ti ẹ̀mí,* ṣé ẹ fẹ́ parí ní ọ̀nà ti ara ni?*+ 4 Ṣé lásán lẹ jẹ ìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ ni? Mi ò gbà pé lásán ni. 5 Nítorí náà, ṣé ẹni tó ń fún yín ní ẹ̀mí, tó sì ń ṣe àwọn iṣẹ́ agbára+ láàárín yín ń ṣe é torí àwọn iṣẹ́ òfin ni àbí nítorí ìgbàgbọ́ tí ẹ ní nínú ohun tí ẹ gbọ́? 6 Gẹ́gẹ́ bí Ábúráhámù ṣe “ní ìgbàgbọ́ nínú Jèhófà,* tí a sì kà á sí òdodo fún un.”+
7 Ẹ kúkú mọ̀ pé àwọn tó rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ni ọmọ Ábúráhámù.+ 8 Bí ìwé mímọ́ ṣe rí i ṣáájú pé Ọlọ́run máa pe àwọn èèyàn àwọn orílẹ̀-èdè ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́, ó kéde ìhìn rere náà fún Ábúráhámù ṣáájú pé: “Ipasẹ̀ rẹ ni gbogbo orílẹ̀-èdè yóò fi rí ìbùkún gbà.”+ 9 Nítorí náà, àwọn tó ń rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ ń rí ìbùkún gbà pẹ̀lú Ábúráhámù tó ní ìgbàgbọ́.+
10 Gbogbo àwọn tó gbára lé àwọn iṣẹ́ òfin wà lábẹ́ ègún, nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Ègún ni fún gbogbo ẹni tí kò bá dúró nínú gbogbo ohun tó wà lákọsílẹ̀ nínú àkájọ ìwé Òfin láti pa wọ́n mọ́.”+ 11 Yàtọ̀ síyẹn, ó ṣe kedere pé kò sí ẹnì kankan tí a pè ní olódodo lọ́dọ̀ Ọlọ́run nípasẹ̀ òfin,+ nítorí “ìgbàgbọ́ yóò mú kí olódodo wà láàyè.”+ 12 Òfin kò dá lórí ìgbàgbọ́. Àmọ́, “yóò mú kí ẹni tó bá ń pa àwọn ohun tó sọ mọ́ wà láàyè.”+ 13 Kristi rà wá,+ ó tú wa sílẹ̀+ lábẹ́ ègún Òfin bó ṣe di ẹni ègún dípò wa, nítorí ó wà lákọsílẹ̀ pé: “Ẹni ègún ni ẹni tí a gbé kọ́ sórí òpó igi.”+ 14 Èyí jẹ́ nítorí kí ìbùkún Ábúráhámù lè dé ọ̀dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè nípasẹ̀ Kristi Jésù,+ kí a lè rí ẹ̀mí tí Ọlọ́run ṣèlérí+ gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ wa.
15 Ẹ̀yin ará, mo fẹ́ fi ohun kan tí àwa èèyàn máa ń ṣe ṣàpèjúwe fún yín: Tí a bá ti fìdí májẹ̀mú kan múlẹ̀, kódà kó jẹ́ látọwọ́ ẹnì kan, kò sí ẹni tó lè fagi lé e tàbí kó fi kún un. 16 Àwọn ìlérí náà la sọ fún Ábúráhámù àti fún ọmọ* rẹ̀.+ Kò sọ pé, “àti fún àwọn ọmọ* rẹ,” bíi pé wọ́n pọ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé, “àti fún ọmọ* rẹ,” ìyẹn ẹnì kan ṣoṣo, tó jẹ́ Kristi.+ 17 Síwájú sí i, mo sọ èyí pé: Òfin tó dé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé ọgbọ̀n (430) ọdún lẹ́yìn náà+ kò fagi lé májẹ̀mú tí Ọlọ́run ti dá, tó fi máa fòpin sí ìlérí náà. 18 Torí tí ogún náà bá dá lórí òfin, kò dá lórí ìlérí mọ́ nìyẹn; àmọ́ Ọlọ́run ti fún Ábúráhámù ní ogún náà nípasẹ̀ ìlérí nítorí inú rere òun fúnra rẹ̀.+
19 Ti Òfin ti wá jẹ́? A fi kún un láti mú kí àwọn àṣìṣe fara hàn kedere,+ títí ọmọ* tí a ṣe ìlérí náà fún á fi dé;+ a sì fi í rán àwọn áńgẹ́lì + nípasẹ̀ alárinà kan.+ 20 Kì í sí alárinà níbi tó bá ti jẹ́ pé ẹnì kan ṣoṣo ni ọ̀rọ̀ kàn, ẹnì kan ṣoṣo sì ni Ọlọ́run. 21 Ṣé Òfin wá ta ko àwọn ìlérí Ọlọ́run ni? Kò rí bẹ́ẹ̀ rárá! Torí ká ní òfin tí a fún wa lè fúnni ní ìyè ni, òdodo ì bá ti wá nípasẹ̀ òfin. 22 Àmọ́ Ìwé Mímọ́ fi ohun gbogbo sínú àhámọ́ ẹ̀ṣẹ̀, kí àwọn tó ní ìgbàgbọ́ lè gba ìlérí tó ń wá látinú ìgbàgbọ́ nínú Jésù Kristi.
23 Àmọ́ ṣá o, kí ìgbàgbọ́ náà tó dé, à ń ṣọ́ wa lábẹ́ òfin, à ń fi wá sínú àhámọ́, a sì ń retí ìgbàgbọ́ tí Ọlọ́run máa tó ṣí payá.+ 24 Nítorí náà, Òfin di olùtọ́* wa tó ń sinni lọ sọ́dọ̀ Kristi,+ kí a lè pè wá ní olódodo nípasẹ̀ ìgbàgbọ́.+ 25 Àmọ́ ní báyìí tí ìgbàgbọ́ ti dé,+ a ò sí lábẹ́ olùtọ́* kankan mọ́.+
26 Ní tòótọ́, ọmọ Ọlọ́run ni gbogbo yín+ nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ yín nínú Kristi Jésù.+ 27 Nítorí gbogbo ẹ̀yin tí a ti batisí sínú Kristi ti gbé Kristi wọ̀.+ 28 Kò tún sí pé ẹnì kan jẹ́ Júù tàbí Gíríìkì,+ ẹrú tàbí òmìnira,+ ọkùnrin tàbí obìnrin,+ nítorí ọ̀kan ṣoṣo ni gbogbo yín nínú Kristi Jésù.+ 29 Yàtọ̀ síyẹn, bí ẹ bá jẹ́ ti Kristi, ẹ jẹ́ ọmọ* Ábúráhámù lóòótọ́,+ ajogún+ nípasẹ̀ ìlérí.+