Nehemáyà
4 Nígbà tí Sáńbálátì+ gbọ́ pé a ti ń tún ògiri náà mọ, ó bínú, ó fara ya,* ó sì ń fi àwọn Júù ṣe yẹ̀yẹ́. 2 Ó wá sọ níṣojú àwọn arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ ogun Samáríà pé: “Kí ni àwọn Júù aláìlera yìí ń ṣe? Ṣé wọ́n lè dá a ṣe ni? Ṣé wọ́n fẹ́ máa rúbọ ni? Ṣé wọ́n lè parí rẹ̀ lọ́jọ́ kan ni? Ṣé wọ́n lè mú kí àwọn òkúta jíjóná tó wà nínú àwọn òkìtì àwókù di èyí tó ṣeé lò ni?”+
3 Lásìkò náà, Tòbáyà+ ọmọ Ámónì+ tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀ sọ pé: “Kódà tí kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ bá gun ohun tí wọ́n ń kọ́, ó máa wó ògiri olókùúta wọn lulẹ̀.”
4 Gbọ́, ìwọ Ọlọ́run wa, nítorí wọ́n ń kàn wá lábùkù,+ dá ẹ̀gàn wọn pa dà sórí wọn,+ jẹ́ kí wọ́n dà bí ẹrù ogun, kí wọ́n sì di ẹrú ní ilẹ̀ àjèjì. 5 Má ṣe bo àṣìṣe wọn mọ́lẹ̀ tàbí kí o jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn pa rẹ́ níwájú rẹ,+ nítorí wọ́n ti sọ̀rọ̀ burúkú sí àwọn tó ń mọ ògiri náà.
6 Torí náà, à ń mọ ògiri náà lọ, a sì mọ gbogbo rẹ̀ kan ara wọn, títí ó fi dé ìdajì gíga rẹ̀, àwọn èèyàn náà sì fọkàn sí iṣẹ́ náà.
7 Nígbà tí Sáńbálátì, Tòbáyà,+ àwọn ọmọ ilẹ̀ Arébíà+ àti àwọn ọmọ Ámónì pẹ̀lú àwọn ará Áṣídódì+ gbọ́ pé àtúnṣe ògiri Jerúsálẹ́mù ń lọ déédéé àti pé a ti ń dí àwọn àlàfo rẹ̀, inú bí wọn gidigidi. 8 Wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti dojú ìjà kọ Jerúsálẹ́mù, kí wọ́n sì dá rúkèrúdò sílẹ̀. 9 Àmọ́, a gbàdúrà sí Ọlọ́run wa, a sì yan ẹ̀ṣọ́ láti máa ṣọ́ wa tọ̀sántòru nítorí wọn.
10 Síbẹ̀, àwọn èèyàn Júdà ń sọ pé: “Àwọn lébìrà* ò lágbára mọ́, àwókù tó wà nílẹ̀ sì pọ̀ gan-an; a ò lè mọ ògiri náà láé.”
11 Àwọn ọ̀tá wa sì ń sọ pé: “Kí wọ́n tó mọ̀ tàbí kí wọ́n tó rí wa, a ó wọ àárín wọn, a ó pa wọ́n, a ó sì dá iṣẹ́ náà dúró.”
12 Ìgbàkígbà tí àwọn Júù tó ń gbé nítòsí wọn bá wá, wọ́n máa ń sọ fún wa léraléra* pé: “Kò síbi tí wọn ò ní gbà yọ sí wa.”
13 Torí náà, mo fi àwọn ọkùnrin kan sí apá ìsàlẹ̀ pátápátá níbi gbayawu tó wà lẹ́yìn ògiri náà, mo sì yàn wọ́n ní ìdílé-ìdílé, wọ́n mú idà wọn, aṣóró wọn àti ọfà* wọn lọ́wọ́. 14 Nígbà tí mo rí i pé ẹ̀rù ń bà wọ́n, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo dìde, mo sì sọ fún àwọn èèyàn pàtàkì+ àti àwọn alábòójútó pẹ̀lú àwọn èèyàn yòókù pé: “Ẹ má bẹ̀rù wọn.+ Ẹ rántí Jèhófà, ẹni gíga tó yẹ ká máa bẹ̀rù;+ ẹ jà fún àwọn arákùnrin yín, àwọn ọmọkùnrin yín àti àwọn ọmọbìnrin yín pẹ̀lú àwọn ìyàwó yín àti ilé yín.”
15 Lẹ́yìn tí àwọn ọ̀tá wa gbọ́ pé a ti mọ ohun tí wọ́n ń ṣe àti pé Ọlọ́run tòótọ́ ti sọ èrò wọn dasán, gbogbo wa pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ògiri náà. 16 Látọjọ́ yẹn lọ, ìdajì àwọn ọkùnrin mi ló ń ṣe iṣẹ́ náà,+ ìdajì yòókù á mú aṣóró, apata àti ọfà* dání, wọ́n á sì wọ ẹ̀wù irin. Bákan náà, àwọn olórí+ wà lẹ́yìn gbogbo èèyàn ilé Júdà 17 tí wọ́n ń mọ ògiri náà. Àwọn tó ń ru ẹrù ń fi ọwọ́ kan ṣiṣẹ́, wọ́n á sì fi ọwọ́ kejì di ohun ìjà* mú. 18 Kọ́lékọ́lé kọ̀ọ̀kan de idà mọ́ ìbàdí rẹ̀ bó ṣe ń mọlé, ẹni tó sì máa fun ìwo+ dúró lẹ́gbẹ̀ẹ́ mi.
19 Mo wá sọ fún àwọn èèyàn pàtàkì àti àwọn alábòójútó pẹ̀lú àwọn èèyàn yòókù pé: “Iṣẹ́ náà pọ̀, ó sì gbòòrò, a wà lórí ògiri náà káàkiri, a sì jìnnà sí ara wa. 20 Tí ẹ bá ti gbọ́ ìró ìwo, kí ẹ kóra jọ sọ́dọ̀ wa. Ọlọ́run wa yóò jà fún wa.”+
21 Torí náà, à ń bá iṣẹ́ lọ, àwọn ìdajì yòókù sì di aṣóró mú, látìgbà tí ilẹ̀ bá ti mọ́ títí ìràwọ̀ á fi yọ. 22 Lákòókò yẹn, mo sọ fún àwọn èèyàn náà pé: “Kí ọkùnrin kọ̀ọ̀kan pẹ̀lú ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró sí Jerúsálẹ́mù mọ́jú, wọ́n á máa ṣọ́ wa ní òru, wọ́n á sì máa ṣiṣẹ́ lọ́sàn-án.” 23 Torí náà, nínú èmi àti àwọn arákùnrin mi pẹ̀lú àwọn ìránṣẹ́ mi+ àti àwọn ẹ̀ṣọ́ tó tẹ̀ lé mi, kò sẹ́ni tó bọ́ ẹ̀wù rẹ̀ sílẹ̀, ohun ìjà kò sì kúrò lọ́wọ́ ọ̀tún kálukú wa.