Émọ́sì
7 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Ó kó ọ̀wọ́ eéṣú jọ ní ìgbà tí irúgbìn àgbìnkẹ́yìn* bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Èyí ni irúgbìn àgbìnkẹ́yìn lẹ́yìn tí wọ́n ti gé koríko ọba. 2 Nígbà tí àwọn eéṣú náà jẹ ohun ọ̀gbìn ilẹ̀ náà tán, mo sọ pé: “Áà, Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, dárí jì wọ́n!+ Jékọ́bù kò ní okun!+ Báwo ló ṣe máa là á já?”*
3 Nítorí náà, Jèhófà pa èrò rẹ̀ dà.*+ “Kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà wí.
4 Ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ fi hàn mí nìyí: Wò ó! Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ lo iná láti fìyà jẹ àwọn èèyàn rẹ̀. Iná náà lá alagbalúgbú omi gbẹ, ó sì jẹ apá kan ilẹ̀ náà run. 5 Mo sì sọ pé: “Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, jọ̀wọ́, má ṣe bẹ́ẹ̀.+ Jékọ́bù kò ní okun!+ Báwo ló ṣe máa là á já?”*
6 Nítorí náà, Jèhófà pa èrò rẹ̀ dà.*+ “Èyí náà kò ní ṣẹlẹ̀,” ni Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ wí.
7 Ohun tó fi hàn mí nìyí: Wò ó! Jèhófà dúró lórí ògiri kan tí wọ́n fi okùn ìwọ̀n mú tọ́ nígbà tí wọ́n kọ́ ọ, okùn ìwọ̀n kan sì wà ní ọwọ́ rẹ̀. 8 Ìgbà náà ni Jèhófà sọ fún mi pé: “Kí lo rí, Émọ́sì?” Torí náà, mo sọ pé: “Okùn ìwọ̀n.” Jèhófà sì sọ pé: “Wò ó, màá fi okùn ìwọ̀n wọn àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì. Mi ò sì ní forí jì wọ́n mọ́.+ 9 Àwọn ibi gíga Ísákì+ máa di ahoro, àwọn ibùjọsìn Ísírẹ́lì á sì pa run;+ màá fi idà kọ lu ilé Jèróbóámù.”+
10 Amasááyà àlùfáà Bẹ́tẹ́lì+ ránṣẹ́ sí Jèróbóámù+ ọba Ísírẹ́lì pé: “Émọ́sì ń dìtẹ̀ sí ọ láàárín ilé Ísírẹ́lì.+ Àwọn èèyàn ilẹ̀ náà kò lè rí ara gba gbogbo ọ̀rọ̀ rẹ̀.+ 11 Nítorí ohun tí Émọ́sì sọ nìyí, ‘Idà ni yóò pa Jèróbóámù, ó sì dájú pé Ísírẹ́lì máa lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀.’”+
12 Ìgbà náà ni Amasááyà sọ fún Émọ́sì pé: “Ìwọ aríran, máa lọ, sá lọ sí ilẹ̀ Júdà, ibẹ̀ ni kí o ti máa wá bí wàá ṣe jẹun,* ibẹ̀ sì ni o ti lè sọ tẹ́lẹ̀.+ 13 Ṣùgbọ́n ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ ní Bẹ́tẹ́lì mọ́,+ nítorí pé ibùjọsìn ọba ni,+ ilé ìjọba sì ni.”
14 Ìgbà náà ni Émọ́sì dá Amasááyà lóhùn pé: “Wòlíì kọ́ ni mí tẹ́lẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì í ṣe ọmọ wòlíì; olùṣọ́ agbo ẹran ni mí,+ mo sì máa ń tọ́jú igi ọ̀pọ̀tọ́ síkámórè.* 15 Àmọ́ Jèhófà sọ fún mi pé kí n má ṣe da agbo ẹran mọ́, Jèhófà sì sọ fún mi pé, ‘Lọ, sọ tẹ́lẹ̀ fún àwọn èèyàn mi Ísírẹ́lì.’+ 16 Torí náà, gbọ́ ọ̀rọ̀ Jèhófà: ‘Ìwọ ń sọ pé, “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sí Ísírẹ́lì,+ ìwọ kò sì gbọ́dọ̀ kéde ìkìlọ̀+ fún ilé Ísákì.” 17 Nítorí náà, ohun tí Jèhófà sọ nìyí: “Aya rẹ máa di aṣẹ́wó ní ìlú yìí, idà ni yóò pa àwọn ọmọkùnrin rẹ àti àwọn ọmọbìnrin rẹ. Okùn ìdíwọ̀n ni wọ́n á fi pín ilẹ̀ rẹ, orí ilẹ̀ àìmọ́ ni wàá sì kú sí; ó sì dájú pé Ísírẹ́lì máa lọ sí ìgbèkùn láti ilẹ̀ rẹ̀.”’”+