Sáàmù
Sí olùdarí; kí a kọ ọ́ pẹ̀lú àwọn ohun ìkọrin olókùn tín-ín-rín.+ Orin Ásáfù. Orin.
3 Ibẹ̀ ló ti ṣẹ́ àwọn ọfà oníná tó jáde látinú ọrun,
Títí kan apata àti idà pẹ̀lú àwọn nǹkan ìjà ogun míì.+ (Sélà)
5 Wọ́n ti kó ẹrù àwọn tó nígboyà.
6 Ọlọ́run Jékọ́bù, nípa ìbáwí rẹ,
Ẹṣin àti ẹni tó gun kẹ̀kẹ́ ẹṣin ti sùn lọ fọnfọn.+
7 Ìwọ nìkan ló yẹ lẹ́ni tí à ń bẹ̀rù.+
Ta ló lè dúró níwájú ìbínú gbígbóná rẹ?+
8 O kéde ìdájọ́ láti ọ̀run;+
Ẹ̀rù ba ayé, ó sì dákẹ́+
9 Nígbà tí Ọlọ́run dìde láti mú ìdájọ́ ṣẹ,
Láti gba gbogbo àwọn oníwà pẹ̀lẹ́ ayé là.+ (Sélà)
10 Nítorí pé ìrunú èèyàn yóò yọrí sí ìyìn rẹ;+
Èyí tó kù lára ìrunú wọn ni ìwọ yóò fi ṣe ara rẹ lọ́ṣọ̀ọ́.
11 Ẹ jẹ́jẹ̀ẹ́ fún Jèhófà Ọlọ́run yín, kí ẹ sì san án,+
Kí gbogbo àwọn tó wà lọ́dọ̀ rẹ̀ mú ẹ̀bùn wọn wá pẹ̀lú ìbẹ̀rù.+
12 Yóò rẹ ògo* àwọn aṣáájú wálẹ̀;
Ó ń mú kí ẹ̀rù ba àwọn ọba ayé.