Sefanáyà
1 Ọ̀rọ̀ Jèhófà sí Sefanáyà* ọmọ Kúúṣì, ọmọ Gẹdaláyà, ọmọ Amaráyà, ọmọ Hẹsikáyà nígbà ayé Jòsáyà+ ọmọ Ámọ́nì+ ọba Júdà:
2 “Màá pa ohun gbogbo rẹ́ ráúráú kúrò lórí ilẹ̀,” ni Jèhófà wí.+
3 “Màá pa èèyàn àti ẹranko rẹ́.
Màá pa ẹyẹ ojú ọ̀run àti àwọn ẹja inú òkun rẹ́+
Àti àwọn ohun ìkọ̀sẹ̀*+ pẹ̀lú àwọn èèyàn burúkú;
Màá sì mú àwọn èèyàn kúrò lórí ilẹ̀,” ni Jèhófà wí.
4 “Màá na ọwọ́ mi sórí Júdà
Àti sórí gbogbo àwọn tó ń gbé Jerúsálẹ́mù,
Gbogbo àwọn tó ṣẹ́ kù lára àwọn tó ń sin* Báálì+ ní ibí yìí ni màá sì pa rẹ́,
Àti orúkọ àwọn àlùfáà ọlọ́run àjèjì pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn àlùfáà míì,+
5 Àti àwọn tó ń forí balẹ̀ lórí òrùlé fún àwọn ọmọ ogun ọ̀run+
Àti àwọn tó ń forí balẹ̀, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Jèhófà+ làwọn ń ṣe
Lẹ́sẹ̀ kan náà, tí wọ́n ń jẹ́jẹ̀ẹ́ pé ti Málíkámù làwọn ń ṣe;+
6 Àti àwọn tó pa dà lẹ́yìn Jèhófà+
Àti àwọn tí kò wá Jèhófà tàbí àwọn tí kò wádìí nípa rẹ̀.”+
7 Dákẹ́ jẹ́ẹ́ níwájú Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ, nítorí ọjọ́ Jèhófà sún mọ́lé.+
Jèhófà ti pèsè ẹbọ sílẹ̀, ó sì ti ya àwọn tí ó pè sí mímọ́.
8 “Ní ọjọ́ tí Jèhófà pèsè ẹbọ, màá pe àwọn ìjòyè wá jíhìn,
Àwọn ọmọ ọba+ àti gbogbo àwọn tó ń wọ aṣọ ilẹ̀ òkèèrè.
9 Màá sì pe gbogbo ẹni tó ń gun pèpéle* wá jíhìn ní ọjọ́ yẹn,
Àwọn tó ń mú kí ìwà ipá àti ẹ̀tàn gbilẹ̀ ní ilé ọ̀gá wọn.
10 Ní ọjọ́ yẹn,” ni Jèhófà wí,
“Igbe ẹkún máa wá láti Ẹnubodè Ẹja+
Àti ìpohùnréré ẹkún láti Apá Kejì ìlú náà+
Àti ìfọ́yángá láti àwọn òkè.
11 Ẹ pohùn réré ẹkún, ẹ̀yin tó ń gbé Mákítẹ́ṣì,*
Torí pé gbogbo àwọn oníṣòwò* ni wọ́n ti pa rẹ́;*
Gbogbo àwọn tó ń wọn fàdákà ni wọ́n sì ti pa run.
12 Ní àkókò yẹn, màá fi fìtílà wá inú Jerúsálẹ́mù fínnífínní,
Màá sì pe àwọn tó dẹra nù* wá jíhìn, àwọn tó ń sọ nínú ọkàn wọn pé,
‘Jèhófà kò ní ṣe rere, kò sì ní ṣe búburú.’+
13 Wọ́n á kó ọrọ̀ wọn lọ, wọ́n á sì pa ilé wọn run.+
Wọ́n á kọ́ ilé, ṣùgbọ́n wọn kò ní gbé inú rẹ̀;
Wọ́n á gbin ọgbà àjàrà, ṣùgbọ́n wọn kò ní mu wáìnì rẹ̀.+
14 Ọjọ́ ńlá Jèhófà sún mọ́lé!+
Ó sún mọ́lé, ó sì ń yára bọ̀ kánkán!*+
Ìró ọjọ́ Jèhófà korò.+
Akíkanjú ológun máa figbe ta níbẹ̀.+