Jẹ́nẹ́sísì
14 Nígbà ayé Ámúráfélì ọba Ṣínárì,+ Áríókù ọba Élásárì, Kedoláómà+ ọba Élámù+ àti Tídálì ọba Góíímù, 2 àwọn ọba yìí bá Bérà ọba Sódómù+ jagun àti Bíṣà ọba Gòmórà,+ Ṣínábù ọba Ádímà, Ṣémébà ọba Sébóíímù+ àti ọba Bélà, ìyẹn Sóárì. 3 Gbogbo ọmọ ogun wọn para pọ̀ ní Àfonífojì* Sídímù,+ ìyẹn Òkun Iyọ̀.*+
4 Wọ́n ti fi ọdún méjìlá (12) sin Kedoláómà, àmọ́ wọ́n ṣọ̀tẹ̀ ní ọdún kẹtàlá. 5 Torí náà, ní ọdún kẹrìnlá, Kedoláómà àti àwọn ọba tó wà pẹ̀lú rẹ̀ wá, wọ́n sì ṣẹ́gun Réfáímù ní Aṣiteroti-kánáímù, wọ́n ṣẹ́gun Súsímù ní Hámù, Émímù+ ní Ṣafe-kíríátáímù, 6 àwọn Hórì+ ní òkè Séírì+ tó jẹ́ tiwọn, títí dé Eli-páránì, tó wà ní aginjù. 7 Wọ́n wá pa dà, wọ́n sì wá sí Ẹn-míṣípátì, ìyẹn Kádéṣì,+ wọ́n sì ṣẹ́gun gbogbo agbègbè àwọn ọmọ Ámálékì+ àti àwọn Ámórì+ tí wọ́n ń gbé ní Hasasoni-támárì.+
8 Ìgbà náà ni ọba Sódómù gbéra, ọba Gòmórà náà gbéra àti ọba Ádímà, ọba Sébóíímù àti ọba Bélà, ìyẹn Sóárì, wọ́n sì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti gbógun jà wọ́n ní Àfonífojì* Sídímù, 9 wọ́n gbógun ja Kedoláómà ọba Élámù, Tídálì ọba Góíímù, Ámúráfélì ọba Ṣínárì àti Áríókù ọba Élásárì,+ ọba mẹ́rin dojú kọ ọba márùn-ún. 10 Kòtò tó ní ọ̀dà bítúmẹ́nì ló kún Àfonífojì* Sídímù. Nígbà tí àwọn ọba Sódómù àti Gòmórà fẹ́ sá lọ, wọ́n kó sínú àwọn kòtò náà, àwọn tó ṣẹ́ kù sì sá lọ sí agbègbè olókè. 11 Àwọn tó ṣẹ́gun kó gbogbo ẹrù Sódómù àti Gòmórà àti gbogbo oúnjẹ wọn, wọ́n sì lọ.+ 12 Wọ́n tún mú Lọ́ọ̀tì, ọmọ arákùnrin Ábúrámù, tó ń gbé ní Sódómù,+ wọ́n kó ẹrù rẹ̀, wọ́n sì bá tiwọn lọ.
13 Lẹ́yìn náà, ọkùnrin kan tó sá àsálà wá sọ fún Ábúrámù tó jẹ́ Hébérù. Nígbà yẹn, ó ń gbé* láàárín àwọn igi ńlá Mámúrè ọmọ Ámórì,+ arákùnrin Éṣíkólì àti Ánérì.+ Àwọn ọkùnrin yìí máa ń ran Ábúrámù lọ́wọ́. 14 Bí Ábúrámù ṣe gbọ́ pé wọ́n ti mú mọ̀lẹ́bí*+ òun lẹ́rú, ó kó àwọn ọkùnrin tó ti kọ́ ní ogun jíjà, àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́ta ó lé méjìdínlógún (318) ìránṣẹ́ tí wọ́n bí sínú agbo ilé rẹ̀, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí í lé wọn títí dé Dánì.+ 15 Ní òru, ó pín àwọn ọmọ ogun rẹ̀, òun àti àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lọ gbógun jà wọ́n, wọ́n sì ṣẹ́gun wọn. Ó lé wọn dé Hóbà, tó wà ní àríwá Damásíkù. 16 Ó gba gbogbo ẹrù náà pa dà, ó sì tún gba Lọ́ọ̀tì mọ̀lẹ́bí rẹ̀ àti àwọn ẹrù rẹ̀ pa dà pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn èèyàn míì.
17 Nígbà tí Ábúrámù ń pa dà bọ̀ lẹ́yìn tó ṣẹ́gun Kedoláómà àti àwọn ọba tó wà pẹ̀lú rẹ̀, ọba Sódómù jáde lọ pàdé Ábúrámù ní Àfonífojì* Ṣáfè, ìyẹn Àfonífojì Ọba.+ 18 Melikisédékì+ ọba Sálẹ́mù+ sì gbé búrẹ́dì àti wáìnì jáde wá; òun ni àlùfáà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ.+
19 Lẹ́yìn náà, ó súre fún un, ó sì sọ pé:
“Kí Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé
Bù kún Ábúrámù;
20 Ìyìn yẹ Ọlọ́run Gíga Jù Lọ,
Ẹni tó mú kí ọwọ́ rẹ tẹ àwọn tó ń ni ọ́ lára!”
Ábúrámù sì fún un ní ìdá mẹ́wàá gbogbo nǹkan.+
21 Lẹ́yìn náà, ọba Sódómù sọ fún Ábúrámù pé: “Fún mi ní àwọn èèyàn* náà, àmọ́ kí ìwọ kó àwọn ẹrù náà.” 22 Àmọ́ Ábúrámù sọ fún ọba Sódómù pé: “Mo gbé ọwọ́ mi sókè, mo sì búra sí Jèhófà Ọlọ́run Gíga Jù Lọ, Ẹni tó dá ọ̀run àti ayé, 23 pé mi ò ní mú ohunkóhun tó jẹ́ tìrẹ, látorí fọ́nrán òwú dórí okùn bàtà, kí o má bàa sọ pé, ‘Èmi ni mo sọ Ábúrámù di ọlọ́rọ̀.’ 24 Mi ò ní mú ohunkóhun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin ti jẹ. Àmọ́ ní ti àwọn ọkùnrin tó bá mi lọ, Ánérì, Éṣíkólì àti Mámúrè,+ jẹ́ kí wọ́n mú ìpín tiwọn.”