Diutarónómì
21 “Tí wọ́n bá pa ẹnì kan sínú oko ní ilẹ̀ tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ fẹ́ fún ọ pé kó di tìrẹ, tí o ò sì mọ ẹni tó pa á, 2 kí àwọn àgbààgbà àti àwọn adájọ́+ rẹ jáde lọ wọn ibi tí òkú náà wà sí àwọn ìlú tó yí i ká. 3 Kí àwọn àgbààgbà ìlú tó sún mọ́ òkú náà jù mú ọmọ màlúù kan látinú agbo ẹran, èyí tí kò tíì ṣiṣẹ́ rí, tí kò sì fa àjàgà rí. 4 Kí àwọn àgbààgbà ìlú yẹn wá mú ọmọ màlúù náà lọ sí àfonífojì tí omi ti ń ṣàn, lórí ilẹ̀ tí wọn ò tíì ro, tí wọn ò sì tíì gbin nǹkan sí, kí wọ́n sì ṣẹ́ ọrùn ọmọ màlúù náà ní àfonífojì yẹn.+
5 “Kí àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì sì wá, torí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ti yàn wọ́n pé kí wọ́n máa ṣe ìránṣẹ́ fún òun,+ kí wọ́n sì máa súre ní orúkọ Jèhófà.+ Wọ́n á sọ bí wọ́n á ṣe máa yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tó bá jẹ mọ́ ìwà ipá.+ 6 Kí gbogbo àgbààgbà ìlú tó sún mọ́ òkú náà jù wá fọ ọwọ́ wọn+ sórí ọmọ màlúù náà, èyí tí wọ́n ṣẹ́ ọrùn rẹ̀ ní àfonífojì, 7 kí wọ́n sì kéde pé, ‘Ọwọ́ wa kọ́ ló ta ẹ̀jẹ̀ yìí sílẹ̀, ojú wa ò sì rí i nígbà tí wọ́n ta á sílẹ̀. 8 Jèhófà, má ṣe kà á sí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì lọ́rùn, àwọn tí o rà pa dà,+ má sì jẹ́ kí àwọn èèyàn rẹ Ísírẹ́lì jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀.’+ A ò sì ní ka ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ náà sí wọn lọ́rùn. 9 Èyí lo fi máa mú ẹ̀bi ẹ̀jẹ̀ ẹni tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ kúrò ní àárín rẹ, torí pé o ṣe ohun tó tọ́ lójú Jèhófà.
10 “Tí o bá lọ bá àwọn ọ̀tá rẹ jagun, tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ bá ọ ṣẹ́gun wọn, tí o sì kó wọn lẹ́rú,+ 11 tí o wá rí obìnrin tó rẹwà láàárín àwọn tí o kó lẹ́rú, tó wù ọ́, tí o sì fẹ́ fi ṣaya, 12 kí o mú un wá sínú ilé rẹ. Kó sì fá orí rẹ̀, kó tọ́jú àwọn èékánná rẹ̀, 13 kó sì bọ́ aṣọ tó wọ̀ nígbà tó ṣì jẹ́ ẹrú, kó wá máa gbé ilé rẹ. Kó fi odindi oṣù kan sunkún torí bàbá àti ìyá rẹ̀,+ lẹ́yìn náà, o lè bá a lò pọ̀; wàá di ọkọ rẹ̀, á sì di ìyàwó rẹ. 14 Àmọ́ tí o ò bá fẹ́ràn rẹ̀, jẹ́ kó máa lọ+ ibikíbi tó bá wù ú.* Àmọ́ o ò gbọ́dọ̀ tà á gbowó, o ò sì gbọ́dọ̀ fìyà jẹ ẹ́, torí o ti dójú tì í.
15 “Tí ọkùnrin kan bá ní ìyàwó méjì, tó nífẹ̀ẹ́ ọ̀kan ju ìkejì lọ,* tí àwọn méjèèjì ti bímọ ọkùnrin fún un, tó sì jẹ́ pé ìyàwó tí kò fẹ́ràn yẹn ló bí àkọ́bí ọkùnrin,+ 16 lọ́jọ́ tó bá pín ogún fún àwọn ọmọ rẹ̀, kò ní sáyè fún un láti fi ọmọ ìyàwó tó fẹ́ràn ṣe àkọ́bí dípò ọmọ ìyàwó tí kò fẹ́ràn, èyí tó jẹ́ àkọ́bí gangan. 17 Kó gbà pé ọmọ ìyàwó tí òun kò fẹ́ràn ni àkọ́bí, kó fún un ní ìpín méjì nínú gbogbo ohun tó ní, torí òun ni ìbẹ̀rẹ̀ agbára ìbímọ rẹ̀. Òun ló ní ẹ̀tọ́ láti jẹ́ àkọ́bí.+
18 “Tí ọkùnrin kan bá ní ọmọ kan tó jẹ́ alágídí àti ọlọ̀tẹ̀, tí kì í gbọ́ràn sí bàbá àti ìyá rẹ̀ lẹ́nu,+ tí wọ́n sì ti gbìyànjú títí láti tọ́ ọ sọ́nà, àmọ́ tó kọ̀ tí ò gbọ́ tiwọn,+ 19 kí bàbá àti ìyá rẹ̀ mú un lọ sọ́dọ̀ àwọn àgbààgbà ní ẹnubodè ìlú rẹ̀, 20 kí wọ́n sì sọ fún àwọn àgbààgbà ìlú rẹ̀ pé, ‘Alágídí àti ọlọ̀tẹ̀ ni ọmọ wa yìí, kì í gbọ́ tiwa. Alájẹkì+ àti ọ̀mùtípara+ sì ni.’ 21 Kí gbogbo ọkùnrin ìlú rẹ̀ sọ ọ́ ní òkúta pa. Kí o mú ohun tó burú kúrò láàárín rẹ, tí gbogbo Ísírẹ́lì bá sì gbọ́, ẹ̀rù á bà wọ́n.+
22 “Tí ẹnì kan bá dẹ́ṣẹ̀, tó sì jẹ́ pé ikú ni ìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, tí ẹ ti pa á,+ tí ẹ sì ti gbé e kọ́ sórí òpó igi,+ 23 ẹ má fi òkú rẹ̀ sílẹ̀ lórí òpó igi náà di ọjọ́ kejì.+ Kàkà bẹ́ẹ̀, kí ẹ rí i pé ẹ sin ín lọ́jọ́ yẹn, torí ẹni ègún ni ẹni tí a gbé kọ́ jẹ́ lójú Ọlọ́run,+ ẹ ò sì gbọ́dọ̀ sọ ilẹ̀ yín di aláìmọ́, èyí tí Jèhófà Ọlọ́run yín fẹ́ fún yín pé kí ẹ jogún.+