Àwọn Ọba Kìíní
2 Nígbà tí ikú Dáfídì ń sún mọ́lé, ó sọ àwọn nǹkan tí Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ máa ṣe fún un, ó ní: 2 “Mi ò ní pẹ́ kú.* Torí náà, jẹ́ alágbára,+ kí o sì ṣe bí ọkùnrin.+ 3 Máa ṣe ohun tí Jèhófà Ọlọ́run rẹ ní kí o ṣe, kí o máa rìn ní ọ̀nà rẹ̀, kí o máa pa àwọn òfin rẹ̀ mọ́ àti àwọn àṣẹ rẹ̀, àwọn ìdájọ́ rẹ̀ pẹ̀lú àwọn ìránnilétí rẹ̀, bí wọ́n ṣe wà lákọsílẹ̀ nínú Òfin Mósè;+ ìgbà náà ni wàá ṣàṣeyọrí* nínú gbogbo ohun tí o bá ń ṣe àti níbikíbi tí o bá yíjú sí. 4 Jèhófà á sì mú ìlérí tó ṣe nípa mi ṣẹ, pé: ‘Bí àwọn ọmọ rẹ bá fiyè sí ọ̀nà wọn, láti fi òtítọ́ rìn níwájú mi pẹ̀lú gbogbo ọkàn wọn àti gbogbo ara* wọn,+ kò ní ṣàìsí ọkùnrin kan láti ìlà ìdílé rẹ* tí yóò máa jókòó sórí ìtẹ́ Ísírẹ́lì.’+
5 “Ìwọ náà mọ ohun tí Jóábù ọmọ Seruáyà ṣe sí mi dáadáa, ohun tó ṣe sí àwọn olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì méjì, ìyẹn Ábínérì+ ọmọ Nérì àti Ámásà+ ọmọ Jétà. Ó pa wọ́n nígbà tí kì í ṣe pé ogun ń jà, ó mú kí ẹ̀jẹ̀+ ogun ta sára àmùrè tó sán mọ́ ìbàdí rẹ̀ àti sára bàtà ẹsẹ̀ rẹ̀. 6 Ṣe ohun tó yẹ gẹ́gẹ́ bí ọlọ́gbọ́n, má sì jẹ́ kó fọwọ́ rọrí kú.*+
7 “Àmọ́ kí o fi ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ hàn sí àwọn ọmọ Básíláì+ ọmọ Gílíádì, kí wọ́n sì wà lára àwọn tí á máa jẹun lórí tábìlì rẹ, nítorí bí wọ́n ṣe dúró tì mí+ nìyẹn nígbà tí mo sá lọ nítorí Ábúsálómù+ ẹ̀gbọ́n rẹ.
8 “Ṣíméì ọmọ Gérà ọmọ Bẹ́ńjámínì láti Báhúrímù náà wà nítòsí rẹ. Òun ló ń ṣẹ́ èpè burúkú+ lé mi lórí lọ́jọ́ tí mò ń lọ sí Máhánáímù;+ àmọ́ nígbà tó wá pàdé mi ní Jọ́dánì, mo fi Jèhófà búra fún un pé: ‘Mi ò ní fi idà pa ọ́.’+ 9 Má ṣàìfi ìyà jẹ ẹ́,+ nítorí ọlọ́gbọ́n ni ọ́, o sì mọ ohun tí ó yẹ kí o ṣe sí i; má ṣe jẹ́ kí ó fọwọ́ rọrí kú.”*+
10 Lẹ́yìn náà, Dáfídì sinmi pẹ̀lú àwọn baba ńlá rẹ̀, wọ́n sì sin ín sí Ìlú Dáfídì.+ 11 Gbogbo ọdún* tí Dáfídì fi jọba lórí Ísírẹ́lì jẹ́ ogójì (40) ọdún. Ọdún méje ló fi jọba ní Hébúrónì,+ ó sì fi ọdún mẹ́tàlélọ́gbọ̀n (33)+ jọba ní Jerúsálẹ́mù.
12 Lẹ́yìn náà, Sólómọ́nì jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá rẹ̀, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ìjọba rẹ̀ fìdí múlẹ̀ gbọn-in.+
13 Nígbà tó yá, Ádóníjà ọmọ Hágítì wá sọ́dọ̀ Bátí-ṣébà, ìyá Sólómọ́nì. Bátí-ṣébà béèrè pé: “Ṣé àlàáfíà lo bá wá o?” Ó fèsì pé: “Àlàáfíà ni.” 14 Ó wá sọ pé: “Ohun kan wà tí mo fẹ́ sọ fún ọ.” Torí náà, ó sọ pé: “Sọ ọ́.” 15 Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “O mọ̀ dáadáa pé èmi ni ọba tọ́ sí, gbogbo Ísírẹ́lì sì ń retí* pé màá di ọba;+ ṣùgbọ́n ó bọ́ mọ́ mi lọ́wọ́, ó sì di ti àbúrò mi, nítorí pé Jèhófà lọ́wọ́ sí i ló ṣe di tirẹ̀.+ 16 Àmọ́ ní báyìí, ohun kan péré ni mo fẹ́ tọrọ lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe da ọ̀rọ̀ mi nù.” Torí náà, ó sọ fún un pé: “Sọ ọ́.” 17 Ó sì sọ pé: “Jọ̀wọ́, sọ fún Sólómọ́nì ọba pé kó fún mi ní Ábíṣágì+ ará Ṣúnémù láti fi ṣe aya. Mo mọ̀ pé kò ní da ọ̀rọ̀ rẹ nù.” 18 Bátí-ṣébà fèsì pé: “Ó dáa! Màá bá ọ sọ fún ọba.”
19 Nítorí náà, Bátí-ṣébà wọlé lọ sọ́dọ̀ Ọba Sólómọ́nì kí ó lè bá a sọ̀rọ̀ nítorí Ádóníjà. Ní kíá, ọba dìde láti pàdé rẹ̀, ọba sì tẹrí ba fún un. Lẹ́yìn náà, ó jókòó sórí ìtẹ́ rẹ̀, ó sì ní kí wọ́n gbé ìtẹ́ kan wá fún ìyá ọba, kí ó lè jókòó sí apá ọ̀tún rẹ̀. 20 Ìgbà náà ni Bátí-ṣébà sọ pé: “Ohun kékeré kan wà tí mo fẹ́ béèrè lọ́wọ́ rẹ. Má ṣe da ọ̀rọ̀ mi nù.” Torí náà, ọba sọ fún un pé: “Béèrè, ìyá mi; mi ò ní da ọ̀rọ̀ rẹ nù.” 21 Ó sọ pé: “Jẹ́ kí a fún Ádóníjà ẹ̀gbọ́n rẹ ní Ábíṣágì ará Ṣúnémù láti fi ṣe aya.” 22 Ni Ọba Sólómọ́nì bá dá ìyá rẹ̀ lóhùn pé: “Kí ló dé tí o fi ní kí n fún Ádóníjà ní Ábíṣágì ará Ṣúnémù? Ò bá kúkú ní kí n fún un ní ìjọba pẹ̀lú+ nítorí pé ẹ̀gbọ́n mi ni,+ ẹ̀yìn rẹ̀ sì ni àlùfáà Ábíátárì àti Jóábù+ ọmọ Seruáyà+ wà.”
23 Ni Ọba Sólómọ́nì bá fi Jèhófà búra pé: “Kí Ọlọ́run fìyà jẹ mí gan-an, tí kò bá jẹ́ pé ohun tó máa gbẹ̀mí* Ádóníjà ló ń béèrè yìí. 24 Ní báyìí, bí Jèhófà ti wà láàyè, ẹni tí ó fìdí mi múlẹ̀ gbọn-in,+ tí ó mú mi jókòó sórí ìtẹ́ Dáfídì bàbá mi, tí ó sì kọ́ ilé fún mi*+ bí ó ti ṣèlérí, òní ni a ó pa Ádóníjà.”+ 25 Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ọba Sólómọ́nì rán Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà, ó jáde lọ, ó ṣá Ádóníjà balẹ̀,* ó sì kú.
26 Ọba sọ fún àlùfáà Ábíátárì+ pé: “Lọ sí ilẹ̀ rẹ ní Ánátótì!+ Ikú tọ́ sí ọ, àmọ́ mi ò ní pa ọ́ lónìí yìí, torí pé o gbé Àpótí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ níwájú Dáfídì bàbá mi+ àti nítorí pé o jẹ nínú gbogbo ìyà tó jẹ bàbá mi.”+ 27 Nítorí náà, Sólómọ́nì lé Ábíátárì kúrò lẹ́nu ṣíṣe àlùfáà fún Jèhófà, láti mú ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ sí ilé Élì+ ní Ṣílò+ ṣẹ.
28 Nígbà tí Jóábù gbọ́ ìròyìn náà, ó sá lọ sínú àgọ́ Jèhófà,+ ó sì di àwọn ìwo pẹpẹ mú, torí pé ẹ̀yìn Ádóníjà+ ni Jóábù wà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò ti Ábúsálómù+ lẹ́yìn. 29 Ìgbà náà ni wọ́n wá sọ fún Ọba Sólómọ́nì pé: “Jóábù ti sá lọ sínú àgọ́ Jèhófà, ó sì wà níbẹ̀ lẹ́gbẹ̀ẹ́ pẹpẹ.” Torí náà, Sólómọ́nì rán Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà pé: “Lọ pa á!” 30 Lẹ́yìn náà, Bẹnáyà lọ sínú àgọ́ Jèhófà, ó sọ fún Jóábù pé: “Ohun tí ọba sọ nìyí, ‘Jáde wá!’” Ṣùgbọ́n ó sọ pé: “Rárá! Ibí ni màá kú sí.” Bẹnáyà pa dà wá sọ fún ọba pé: “Ohun tí Jóábù sọ nìyí, èsì tó sì fún mi nìyí.” 31 Ni ọba bá sọ fún un pé: “Ohun tí ó sọ ni kí o ṣe; ṣá a balẹ̀, kí o sin ín, kí o sì mú ẹ̀jẹ̀ tí Jóábù ta sílẹ̀ láìyẹ+ kúrò lórí mi àti kúrò lórí ilé bàbá mi. 32 Jèhófà yóò mú ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ wá sórí rẹ̀, nítorí ó fi idà ṣá àwọn ọkùnrin méjì tí wọ́n lóòótọ́ jù ú lọ balẹ̀, tí wọ́n sì dára jù ú, ó pa wọ́n láìjẹ́ kí Dáfídì bàbá mi mọ̀. Àwọn ọkùnrin náà ni: Ábínérì+ ọmọ Nérì, olórí ọmọ ogun Ísírẹ́lì+ àti Ámásà+ ọmọ Jétà, olórí ọmọ ogun Júdà.+ 33 Ẹ̀jẹ̀ wọn yóò wá sórí Jóábù àti sórí àwọn ọmọ* rẹ̀ títí láé;+ àmọ́ kí àlàáfíà Jèhófà wà lórí Dáfídì àti àwọn ọmọ* rẹ̀, kí ó wà lórí ilé rẹ̀ àti ìtẹ́ rẹ̀ títí láé.” 34 Ìgbà náà ni Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà lọ ṣá Jóábù balẹ̀, ó pa á, wọ́n sì sin ín sí ilé rẹ̀ ní aginjù. 35 Lẹ́yìn náà, ọba yan Bẹnáyà+ ọmọ Jèhóádà ṣe olórí ọmọ ogun ní ipò rẹ̀, ọba tún yan àlùfáà Sádókù+ sí ipò Ábíátárì.
36 Nígbà náà, ọba ránṣẹ́ pe Ṣíméì,+ ó sì sọ fún un pé: “Kọ́ ilé kan fún ara rẹ ní Jerúsálẹ́mù, kí o sì máa gbé ibẹ̀; má ṣe kúrò níbẹ̀ lọ sí ibikíbi. 37 Ọjọ́ tí o bá jáde síta, tí o sì sọdá Àfonífojì Kídírónì,+ mọ̀ dájú pé wàá kú. Ẹ̀jẹ̀ rẹ á sì wà lórí ìwọ fúnra rẹ.” 38 Ṣíméì dá ọba lóhùn pé: “Ohun tí o sọ dára. Ìránṣẹ́ rẹ yóò ṣe ohun tí olúwa mi ọba sọ.” Torí náà, ọ̀pọ̀ ọjọ́ ni Ṣíméì fi gbé ní Jerúsálẹ́mù.
39 Àmọ́ nígbà tí ọdún mẹ́ta kọjá, méjì lára àwọn ẹrú Ṣíméì sá lọ sọ́dọ̀ Ákíṣì+ ọmọ Máákà ọba Gátì. Nígbà tí wọ́n sọ fún Ṣíméì pé: “Wò ó! Àwọn ẹrú rẹ wà ní Gátì,” 40 lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Ṣíméì de ohun tí wọ́n fi ń jókòó mọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ rẹ̀,* ó sì lọ rí Ákíṣì ní Gátì láti wá àwọn ẹrú rẹ̀. Nígbà tí Ṣíméì kó àwọn ẹrú rẹ̀ dé láti Gátì, 41 wọ́n sọ fún Sólómọ́nì pé: “Ṣíméì jáde kúrò ní Jerúsálẹ́mù lọ sí Gátì, ó sì ti pa dà.” 42 Ni ọba bá ránṣẹ́ pe Ṣíméì, ó sì sọ fún un pé: “Ṣé mi ò fi Jèhófà búra fún ọ, tí mo sì kìlọ̀ fún ọ pé: ‘Ọjọ́ tí o bá jáde kúrò níbí lọ sí ibikíbi, mọ̀ dájú pé wàá kú’? Ṣebí o sọ fún mi pé, ‘Ohun tí o sọ dára; màá ṣègbọràn’?+ 43 Kí wá nìdí tí o kò fi pa ìbúra Jèhófà mọ́ àti àṣẹ tí mo pa fún ọ?” 44 Lẹ́yìn náà, ọba sọ fún Ṣíméì pé: “Nínú ọkàn rẹ, o mọ gbogbo jàǹbá tí o ṣe fún Dáfídì bàbá mi,+ Jèhófà yóò sì dá jàǹbá náà pa dà sórí rẹ.+ 45 Àmọ́ Ọba Sólómọ́nì yóò gba ìbùkún,+ ìtẹ́ Dáfídì yóò sì fìdí múlẹ̀ gbọn-in níwájú Jèhófà títí láé.” 46 Ni ọba bá pàṣẹ fún Bẹnáyà ọmọ Jèhóádà, Bẹnáyà jáde lọ, ó ṣá a balẹ̀, ó sì kú.+
Bí ìjọba náà ṣe fìdí múlẹ̀ gbọn-in lọ́wọ́ Sólómọ́nì nìyẹn.+