Àìsáyà
52 Jí! Jí! Gbé agbára wọ̀,+ ìwọ Síónì!+
Wọ aṣọ rẹ tó rẹwà,+ ìwọ Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́!
Torí ẹni tí kò dádọ̀dọ́* àti aláìmọ́ kò ní wọ inú rẹ mọ́.+
2 Gbọn eruku kúrò, gbéra kí o sì jókòó, ìwọ Jerúsálẹ́mù.
Tú ìdè ọrùn rẹ, ìwọ ọmọbìnrin Síónì tí wọ́n mú lẹ́rú.+
3 Torí ohun tí Jèhófà sọ nìyí:
4 Torí ohun tí Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ sọ nìyí:
“Àwọn èèyàn mi kọ́kọ́ lọ sí Íjíbítì, wọ́n sì gbé níbẹ̀ bí àjèjì;+
Ásíríà wá fìyà jẹ wọ́n láìnídìí.”
5 “Kí wá ni kí n ṣe níbí?” ni Jèhófà wí.
“Ọ̀fẹ́ ni wọ́n kó àwọn èèyàn mi lọ.
Àwọn tó ń jọba lé wọn lórí ń kígbe pé àwọn ti ṣẹ́gun,”+ ni Jèhófà wí,
“Nígbà gbogbo, láti àárọ̀ ṣúlẹ̀, wọn ò bọ̀wọ̀ fún orúkọ mi.+
6 Ìyẹn máa mú kí àwọn èèyàn mi mọ orúkọ mi;+
Ìyẹn máa mú kí wọ́n mọ̀ ní ọjọ́ yẹn pé èmi ni Ẹni tó ń sọ̀rọ̀.
Wò ó, èmi ni!”
7 Wo bí ẹsẹ̀ ẹni tó ń mú ìhìn rere wá ṣe rẹwà tó lórí àwọn òkè,+
Ẹni tó ń kéde àlàáfíà,+
Ẹni tó ń mú ìhìn rere wá nípa ohun tó sàn,
Ẹni tó ń kéde ìgbàlà,
Ẹni tó ń sọ fún Síónì pé: “Ọlọ́run rẹ ti di Ọba!”+
8 Fetí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè.
Wọ́n kígbe ayọ̀ níṣọ̀kan,
Torí wọ́n máa rí i kedere* tí Jèhófà bá pa dà kó Síónì jọ.
9 Ẹ tújú ká, ẹ kígbe ayọ̀ níṣọ̀kan, ẹ̀yin àwókù Jerúsálẹ́mù,+
Torí Jèhófà ti tu àwọn èèyàn rẹ̀ nínú;+ ó ti tún Jerúsálẹ́mù rà.+
11 Ẹ yíjú pa dà, ẹ yíjú pa dà, ẹ jáde kúrò níbẹ̀,+ ẹ má fọwọ́ kan ohun àìmọ́ kankan!+
12 Ẹ ò ní fi ìbẹ̀rù lọ,
Ẹ ò sì ní sá lọ,
Torí Jèhófà máa ṣáájú yín,+
Ọlọ́run Ísírẹ́lì á sì máa ṣọ́ yín láti ẹ̀yìn.+
13 Wò ó! Ìránṣẹ́ mi+ máa fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà.
A máa gbé e ga,
A máa gbé e lékè, a sì máa gbé e ga gidigidi.+
14 Bó ṣe jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ló ń wò ó tìyanutìyanu,
Tí wọ́n ba ìrísí rẹ̀ jẹ́ ju ti èèyàn èyíkéyìí míì,
Tí wọ́n sì ba ìrísí rẹ̀ tó buyì kún un jẹ́ ju ti ọmọ aráyé,