Nehemáyà
11 Àwọn olórí àwọn èèyàn náà ń gbé ní Jerúsálẹ́mù;+ àmọ́ ìyókù àwọn èèyàn náà ṣẹ́ kèké+ láti mú ẹnì kan nínú èèyàn mẹ́wàá láti lọ máa gbé ní Jerúsálẹ́mù, ìlú mímọ́, nígbà tí àwọn mẹ́sàn-án yòókù á máa gbé ní àwọn ìlú míì. 2 Àwọn èèyàn náà sì súre fún gbogbo àwọn ọkùnrin tó yọ̀ǹda ara wọn láti lọ máa gbé ní Jerúsálẹ́mù.
3 Àwọn tó tẹ̀ lé e yìí ni àwọn olórí ìpínlẹ̀* tí wọ́n ń gbé ní Jerúsálẹ́mù. (Ìyókù àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì, àwọn àlùfáà, àwọn ọmọ Léfì, àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ àti àwọn ọmọ àwọn ìránṣẹ́ Sólómọ́nì,+ wọ́n ń gbé ní àwọn ìlú míì ní Júdà, kálukú sì ń gbé lórí ohun ìní rẹ̀ nínú ìlú rẹ̀.+
4 Àwọn míì tó tún ń gbé ní Jerúsálẹ́mù ni àwọn kan lára àwọn èèyàn Júdà àti Bẹ́ńjámínì.) Lára àwọn èèyàn Júdà ni Átáyà ọmọ Ùsáyà ọmọ Sekaráyà ọmọ Amaráyà ọmọ Ṣẹfatáyà ọmọ Máhálálélì látinú àwọn ọmọ Pérésì+ 5 àti Maaseáyà ọmọ Bárúkù ọmọ Kólíhósè ọmọ Hasáyà ọmọ Ádáyà ọmọ Jóyáríbù ọmọ Sekaráyà látinú ìdílé àwọn ọmọ Ṣélà. 6 Gbogbo àwọn ọmọ Pérésì tó ń gbé ní Jerúsálẹ́mù jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́rin ó lé méjìdínláàádọ́rin (468) ọkùnrin tó dáńgájíá.
7 Àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì nìyí: Sáálù+ ọmọ Méṣúlámù ọmọ Jóédì ọmọ Pedáyà ọmọ Koláyà ọmọ Maaseáyà ọmọ Ítíélì ọmọ Jeṣáyà, 8 àwọn tó tẹ̀ lé e ni Gábáì àti Sáláì, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ó lé méjìdínlọ́gbọ̀n (928); 9 Jóẹ́lì ọmọ Síkírì ni alábòójútó wọn, Júdà ọmọ Hásénúà sì ni igbá kejì rẹ̀ ní ìlú náà.
10 Látinú àwọn àlùfáà: Jedáyà ọmọ Jóyáríbù, Jákínì,+ 11 Seráyà ọmọ Hilikáyà ọmọ Méṣúlámù ọmọ Sádókù ọmọ Méráótì ọmọ Áhítúbù,+ aṣáájú ní ilé* Ọlọ́run tòótọ́ 12 àti àwọn arákùnrin wọn tó ń ṣiṣẹ́ ìsìn ní tẹ́ńpìlì, wọ́n jẹ́ ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ ó lé méjìlélógún (822) àti Ádáyà ọmọ Jéróhámù ọmọ Pẹlaláyà ọmọ Ámísì ọmọ Sekaráyà ọmọ Páṣúrì+ ọmọ Málíkíjà 13 àti àwọn arákùnrin rẹ̀, àwọn olórí agbo ilé, iye wọn jẹ́ igba ó lé méjìlélógójì (242) àti Ámáṣísáì ọmọ Ásárẹ́lì ọmọ Ásáì ọmọ Méṣílémótì ọmọ Ímérì 14 àti àwọn arákùnrin wọn tí wọ́n lágbára tí wọ́n sì nígboyà, wọ́n jẹ́ méjìdínláàádóje (128), alábòójútó wọn ni Sábídíẹ́lì, ó wá láti ìdílé kan tó lókìkí.
15 Látinú àwọn ọmọ Léfì: Ṣemáyà+ ọmọ Háṣúbù, ọmọ Ásíríkámù ọmọ Haṣabáyà ọmọ Búnì 16 àti Ṣábétáì+ àti Jósábádì,+ látinú àwọn olórí àwọn ọmọ Léfì, tí wọ́n ń bójú tó àwọn iṣẹ́ míì tó jẹ mọ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́ 17 àti Matanáyà,+ ọmọ Míkà ọmọ Sábídì ọmọ Ásáfù,+ olùdarí orin, tó máa ń gbé orin ìyìn nígbà àdúrà+ àti Bakibúkáyà tó jẹ́ èkejì nínú àwọn arákùnrin rẹ̀ pẹ̀lú Ábídà ọmọ Ṣámúà ọmọ Gálálì ọmọ Jédútúnì.+ 18 Gbogbo àwọn ọmọ Léfì tó wà nínú ìlú mímọ́ náà jẹ́ igba ó lé mẹ́rìnlélọ́gọ́rin (284).
19 Àwọn aṣọ́bodè ni Ákúbù, Tálímónì+ àti àwọn arákùnrin wọn tó ń ṣọ́ àwọn ẹnubodè, wọ́n jẹ́ méjìléláàádọ́sàn-án (172).
20 Ìyókù àwọn tó wà ní Ísírẹ́lì àti àwọn àlùfáà pẹ̀lú àwọn ọmọ Léfì sì wà nínú gbogbo àwọn ìlú míì ní Júdà, kálukú lórí ilẹ̀ tó jogún.* 21 Àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì*+ ń gbé ní Ófélì.+ Síhà àti Gíṣípà ló sì ń bójú tó àwọn ìránṣẹ́ tẹ́ńpìlì.*
22 Alábòójútó àwọn ọmọ Léfì ní Jerúsálẹ́mù ni Úsáì ọmọ Bánì ọmọ Haṣabáyà ọmọ Matanáyà+ ọmọ Máíkà látinú àwọn ọmọ Ásáfù, àwọn akọrin; òun ló sì ń bójú tó iṣẹ́ ilé Ọlọ́run tòótọ́. 23 Ọba pàṣẹ kan nítorí wọn,+ ètò sì wà fún ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa fún àwọn akọrin bí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ṣe gbà. 24 Petaháyà ọmọ Meṣesábélì látinú àwọn ọmọ Síírà ọmọ Júdà sì ni agbani-nímọ̀ràn ọba* nínú gbogbo ọ̀ràn àwọn èèyàn náà.
25 Ní ti àwọn ibi tí wọ́n tẹ̀ dó sí pẹ̀lú àwọn pápá wọn, àwọn kan lára àwọn èèyàn Júdà ń gbé ní Kiriati-ábà+ àti àwọn àrọko rẹ̀,* ní Díbónì àti àwọn àrọko rẹ̀, ní Jekabúsélì+ àti àwọn ìgbèríko rẹ̀, 26 ní Jéṣúà, ní Móládà,+ ní Bẹti-pélétì,+ 27 ní Hasari-ṣúálì,+ ní Bíá-ṣébà àti àwọn àrọko rẹ̀,* 28 ní Síkílágì,+ ní Mékónà àti àwọn àrọko rẹ̀,* 29 ní Ẹ́ń-rímónì,+ ní Sórà+ àti ní Jámútì, 30 ní Sánóà,+ ní Ádúlámù àti àwọn ìgbèríko wọn, ní Lákíṣì+ àti àwọn pápá rẹ̀ àti ní Ásékà+ àti àwọn àrọko* rẹ̀. Wọ́n ń gbé láti* Bíá-ṣébà títí lọ dé Àfonífojì Hínómù.+
31 Àwọn èèyàn Bẹ́ńjámínì sì wà ní Gébà,+ Míkímáṣì, Áíjà, Bẹ́tẹ́lì+ àti àwọn àrọko* rẹ̀, 32 Ánátótì,+ Nóbù,+ Ananíà, 33 Hásórì, Rámà,+ Gítáímù, 34 Hádídì, Sébóímù, Nébálátì, 35 Lódì àti Ónò,+ àfonífojì àwọn oníṣẹ́ ọnà. 36 Wọ́n sì pín lára àwọn àwùjọ àwọn ọmọ Léfì tó wà ní Júdà sọ́dọ̀ Bẹ́ńjámínì.