Àgbàyanu Àgbáálá Ayé
‘Ó Ku Ohun Kan’—Kí Ni Ohun Náà?
LẸ́YÌN títẹjú mọ́ àwọn ìràwọ̀ ní alẹ́ kìjikìji, tí ó mọ́lẹ̀ kan, a wọlé, òtútù ń mú wa, a sì ń ṣẹ́jú péképéké, ẹwà rẹpẹtẹ àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ ìbéèrè ní ń yí lọ yí bọ̀ nínú èrò inú wa. Èé ṣe tí àgbáálá ayé fi wà? Ibo ni ó ti wá? Ibo ni ó ń lọ? Àwọn ìbéèrè tí ọ̀pọ̀ ènìyàn ń gbìyànjú láti dáhùn nìyí.
Lẹ́yìn tí òǹkọ̀wé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, Dennis Overbye, ṣèwádìí nípa ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà fún ọdún márùn-ún, tí ó gbé e lọ sí àwọn ibi àpérò ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti àwọn ibùdó ìṣèwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ jákèjádò àgbáyé, ó ṣàpèjúwe ìjíròrò kan tí ó ní pẹ̀lú onímọ̀ ìjìnlẹ̀ physics tí ó lókìkí káàkiri àgbáyé náà, Stephen Hawking pé: “Ní òpin rẹ̀, ohun tí mo fẹ́ láti gbọ́ lẹ́nu Hawking ni ohun tí mo máa ń fìgbà gbogbo fẹ́ láti gbọ́ lẹ́nu Hawking: Ibi tí a ń lọ nígbà tí a bá kú.”
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀dà ọ̀rọ̀ wà nínú àyọkà òkè yìí, àwọn ọ̀rọ̀ náà fi púpọ̀ hàn nípa sànmánì wa. Kò fi bẹ́ẹ̀ sí iyè méjì lọ títí nípa àwọn ìràwọ̀ náà fúnra wọn àti àwọn àbá èrò orí àti àwọn ojú ìwòye títakora tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà tí wọ́n ṣèwádìí wọn ní. Àwọn ènìyàn lónìí ṣì ń yán hànhàn fún àwọn ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè pàtàkì tí ó ti ń gbé aráyé lọ́kàn lemọ́lemọ́ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún: Èé ṣe tí a fi wà níhìn-ín? Ọlọrun kan ha wà bí? Ibo ni a ń lọ tí a bá kú? Ibo ni a ti lè rí ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè yìí? A ha lè rí wọn nínú àwọn ìràwọ̀ bí?
Òǹkọ̀wé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ míràn, John Boslough, ṣàkíyèsí pé, bí àwọn ènìyàn ti ń jáwọ́ nínú ìsìn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ti di “ẹgbẹ́ àlùfáà pípé fún sànmánì tí kò bá ọ̀nà ìsìn lọ yìí. Àwọn ni wọn yóò wá ṣí gbogbo àṣírí àgbáálá ayé payá ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀lé báyìí, kì í ṣe àwọn aṣáájú ìsìn, kì í ṣe lábẹ́ ìbòjú ìdíbọ́n nípa tẹ̀mí, ṣùgbọ́n lọ́nà ìṣèṣirò tí gbogbo ènìyàn kò mọ̀ àyàfi àwọn aṣáájú nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀.” Ṣùgbọ́n wọn óò ha ṣí gbogbo àṣírí àgbáálá ayé payá, kí wọ́n sì dáhùn gbogbo àwọn ìbéèrè tí ó ti ń gbé aráyé lọ́kàn fún ọ̀pọ̀ ọdún bí?
Kí ni àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà ń ṣí payá nísinsìnyí? Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń gbà, wọ́n sì ń rọ̀ mọ́ àwọn apá kan lára “àbá èrò orí” ìbúgbàù ńlá náà, tí ó ti di ìsìn tí kò bá ọ̀nà ìsìn lọ ní àkókò wa, kódà bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn náà kò lè sọ gbogbo kúlẹ̀kúlẹ̀ tán. Boslough sọ pé: “Síbẹ̀, tí a bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn àkíyèsí tuntun àti ẹ̀rí tí ó ta kora, àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá bẹ̀rẹ̀ sí í dà bí àpèjúwe tí a mú rọrùn jù tí ń wá ọ̀nà àtiṣọ̀kan pẹ̀lú àpèjúwe náà. Ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1990, àbá èrò orí ìbúgbàù ńlá náà . . . di èyí tí kò lè dáhùn àwọn ìbéèrè tí ó ṣe pàtàkì jù lọ síwájú àti síwájú sí i.” Ó fi kún un pé, “ìwọ̀nba àwọn alábàá èrò orí díẹ̀ ni wọ́n ti sọ èrò náà jáde pé, kò tilẹ̀ ní ré kọjá àwọn ọdún 1990.”
Bóyá díẹ̀ lára àwọn ìméfò lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àgbáálá ayé yóò wá tọ̀nà, bóyá wọn kò sì ní wá tọ̀nà—gan-an bí ó ti jẹ́ pé bóyá àwọn pílánẹ́ẹ̀tì wà ní ti gidi tí wọ́n ń jáde wá láti inú àwọn ohun àfojúrí nínú ìgbì ìmọ́lẹ̀ nebula Orion, bóyá wọn kò sì jáde wá láti inú rẹ̀. Òkodoro òtítọ́ tí a kò lè sẹ́ náà ni pé kò sí ẹnikẹ́ni lórí ilẹ̀ ayé yìí tí ó mọ̀ dájú ní ti gidi. Àwọn àbá èrò orí pọ̀ lọ salalu, ṣùgbọ́n àwọn alákìíyèsí olótìítọ́ ọkàn kín àkíyèsí ọlọgbọ́n ti Margaret Geller lẹ́yìn pé, láìka ti ọ̀rọ̀ dídùn náà sí, ó jọ pé ó ku ohun pàtàkì kan ti ó ṣẹ́ kù nínú òye ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àgbáálá ayé.
Ohun Tí Ó Kù—Ṣíṣe Tán Láti Dojú Kọ Àwọn Òkodoro Òtítọ́ Tí Kò Bára Dé
Ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀—èyí sì ní ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà nínú—ṣètìlẹ́yìn fún àbá èrò orí ẹfolúṣọ̀n. Wọ́n rí àwọn ọ̀rọ̀ tí ń fún ìlọ́gbọ́nlóye àti ète ní ipa kan nínú iṣẹ́ ìṣẹ̀dá gẹ́gẹ́ bí èyí tí kò bára dé, wọ́n sì máa ń wárìrì tí a bá wulẹ̀ mẹ́nu kàn án pé Ọlọrun ni Ẹlẹ́dàá. Wọ́n tilẹ̀ kọ̀ láti gbé irú àdámọ̀ bẹ́ẹ̀ yẹ̀ wò. Orin Dafidi 10:4 bu ẹnu àtẹ́ lu agbéraga tí “kò fẹ́ ṣe àfẹ́rí Ọlọrun: Ọlọrun kò sí ní gbogbo ìrònú rẹ̀.” Ọlọrun Èèṣì ni ó ṣẹ̀dá rẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ìmọ̀ ti ń pọ̀ sí i, tí èèṣì àti ìṣekòńgẹ́ sì ń ṣubú lábẹ́ ẹ̀rí tí ń ga pelemọ sí i, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yíjú sí irú àwọn ohun àìṣètẹ́wọ́gbà bẹ́ẹ̀ bí ọgbọ́n òye àti ìwéwèéṣètò. Gbé àwọn àpẹẹrẹ tí ó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò:
Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà, Fred Hoyle, kọ nínú ìwé rẹ̀, The Intelligent Universe, ojú ìwé 189, pé: “Ó dájú pé, ó ku ohun kan nínú àwọn ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àgbáálá ayé. Orísun Àgbáálá Ayé ń béèrè ìlọ́gbọ́nlóye, bí wíwá ojútùú sí ìgọ̀n Rubik ti béèrè fún un.”
“Bí mo bá ṣe ṣàyẹ̀wò àgbáálá ayé tí mo sì ṣèwádìí kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa ìgbékalẹ̀ rẹ̀ tó, bẹ́ẹ̀ ni ẹ̀rí tí mo máa ń rí ń pọ̀ tó pé, lọ́nà kan, àgbáálá ayé gbọ́dọ̀ ti mọ̀ pé ìran ènìyàn ń bọ̀ wá.”—Disturbing the Universe, láti ọwọ́ Freeman Dyson, ojú ìwé 250.
“Àwọn apá fífani mọ́ra wo ló pọn dandan nínú Àgbáálá Ayé fún gbígbé àwọn ìṣẹ̀dá bí àwa fúnra wa jáde, ó ha sì lè jẹ́ pé nípa ìṣekòńgẹ́, tàbí nítorí àwọn ìdí jíjinlẹ̀ kan, ni Àgbáálá Ayé wa fi ní àwọn apá fífani mọ́ra wọ̀nyí? . . . Àwọn ìwéwèé jíjinlẹ̀ kan ha wà tí ó mú un dáni lójú pé, a ṣe Àgbáálá Ayé fún ìran aráyé bí?”—Cosmic Coincidences, láti ọwọ́ John Gribbin àti Martin Rees, ojú ìwé xiv, 4.
Fred Hoyle pẹ̀lú sọ̀rọ̀ nípa àwọn apá fífani mọ́ra wọ̀nyí nínú ìwé rẹ̀ tí a fa ọ̀rọ̀ yọ nínú rẹ̀ lókè, lójú ewé 220 pé: “Ó jọ pé irú àwọn apá fífani mọ́ra bẹ́ẹ̀ wà káàkiri àgbáyé àdánidá tí ó dà bí ìrìnnàkore. Ṣùgbọ́n ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ló wà nínú irú àwọn ìṣekòńgẹ́ títa gọngọ bẹ́ẹ̀ tí ó wúlò fún ìgbésí ayé, tí ó fi jọ pé, ó yẹ kí a béèrè fún àwọn àlàyé díẹ̀ nípa wọn.”
“Kì í ṣe pé àwọn ènìyàn ti mú ara bá ipò inú àgbáálá ayé mu nìkan ni. Àgbáálá ayé ti mú ara rẹ̀ bá ipò ènìyàn mu. Finú wòye àgbáálá ayé kan, níbi tí a ti yí ọ̀kan tàbí òmíràn lára àwọn ohun aláìṣeédíwọ̀n tí kò ṣeé yí padà ṣíṣe kókó nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa àjọṣepọ̀ ohun aṣeéfojúrí àti agbára padà pẹ̀lú ìpín díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún lọ́nà kan tàbí òmíràn? Ènìyàn ì bá máà sí nínú irú àgbáálá ayé bẹ́ẹ̀. Ojúkò ìlànà nípa bí ènìyàn ti pẹ́ láyé tó nìyẹn. Gẹ́gẹ́ bí ìlànà náà ti sọ, ohun kan tí ń fúnni ní ìyè ni ó wà nídìí orísun gbogbo ohun èèlò àti ìwéwèé ṣètò àgbáyé.”—The Anthropic Cosmological Principle,” láti ọwọ́ John Barrow àti Frank Tipler, ojú ìwé vii.
Ọlọrun, Ìwéwèéṣètò àti Àwọn Ohun Tí Kò Ṣeé Yí Padà Nínú Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Physics
Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun tí kò ṣeé yí padà ṣíṣe kókó nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ physics tí ó ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè láti máa wà nìṣó nínú àgbáálá ayé? Ìròyìn kan nínú ìwé agbéròyìnjáde The Orange County Register ti January 8, 1995, ṣàkọsílẹ̀ díẹ̀ lára àwọn ohun tí kò ṣeé yí padà wọ̀nyí. Ó tẹnu mọ́ bí a ṣe gbọ́dọ̀ mú àwọn apá fífani mọ́ra wọ̀nyí ṣe gẹ́ẹ́, ní sísọ pé: “Àwọn ìjẹ́pàtàkì gbígbé pẹ́ẹ́lí ìpilẹ̀ aṣeéfojúrí nínú ọ̀pọ̀ àwọn ohun tí kò ṣeé yí padà tí ń ṣàlàyé àgbáálá ayé—fún àpẹẹrẹ, gbígbagbára electron, tàbí ìwọ̀n ìyára iná tí ó wà gbandi, tàbí ìṣirò ìfiwéra àwọn okun ti àwọn ipá ṣíṣe kókó inú ìṣẹ̀dá—ṣe rẹ́gí lọ́nà yíyani lẹ́nu, àwọn kan ní ipò 120 lẹ́yìn àmì ẹ̀sún. Ìgbékalẹ̀ àgbáálá ayé kan tí ń ṣọlọ́jọ̀jọ̀ ìwàláàyè máa ń mọ àwọn ìfihàn pàtó wọ̀nyí lára lọ́nà pípeléke. Bí a bá mú ìyàtọ̀ bín-ń-tín èyíkéyìí—bí ìdá kan nínú bílíọ̀nù ìṣẹ́jú àáyá níhìn-ín, ìdámẹ́wàá ìpín bílíọ̀nù lọ́hùn-ún—àgbáálá ayé ì bá ti dòkú àti aṣálẹ̀ ní báyìí.”
Lẹ́yìn náà, ẹni tí ó gbé ìròyìn yìí jáde mẹ́nu kan àwọn ohun tí a kì í sábà mẹ́nu kàn pé: “Ó jọ pé ó túbọ̀ bọ́gbọ́n mu láti ronú pé àwọn ìtẹ̀sí àràmàǹdà kan há sáàárín ìlànà náà, bóyá nínú ìgbésẹ̀ agbára àmọ̀ọ́mọ̀-ṣe-nǹkan, tí ó sì jẹ́ olóye, tí ó mú kí àgbáálá ayé ṣe gẹ́ẹ́ ní ìmúrasílẹ̀ fún dídé wa.”
George Greenstein, ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà àti ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé, pèsè àkọsílẹ̀ jàn-ànràn nípa àwọn ohun aṣeéfojúrí tí kò ṣeé yí padà wọ̀nyí nínú ìwé rẹ̀, The Symbiotic Universe. Lára àwọn ohun tí ó tò jọ ni àwọn ohun tí kò ṣeé yí padà tí a mú kí ó ṣe gẹ́ẹ́ débi pé bí wọ́n bá yẹ̀ díẹ̀ ṣíún, kò sí átọ́ọ̀mù, ìràwọ̀, àgbáálá ayé, tí ì bá wà. Àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ ipò ìbátan wọ̀nyí ni a tò jọ sínú àpótí àlàyé yìí. Wọ́n gbọ́dọ̀ wà, kí ìwàláàyè tí ó ṣeé fojú rí lè ṣeé ṣe. Wọ́n lọ́jú pọ̀, ó sì ṣeé ṣe kí ó máà jẹ́ gbogbo àwọn òǹkàwé ni yóò lóye wọn, ṣùgbọ́n àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìṣẹ̀dá inú sánmà, tí a dá lẹ́kọ̀ọ́ ní àwọn ọ̀nà yìí, mọ̀ wọ́n àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ní àmọ̀jẹ́wọ́.
Bí àkọsílẹ̀ yìí ti ń pọ̀ sí i, ìmọ̀lára bo Greenstein mọ́lẹ̀ pátápátá. Ó wí pé: “Ìṣekòńgẹ́ náà pọ̀ jù! Bí mo ṣe ń kàwé púpọ̀ sí i tó, bẹ́ẹ̀ ni ó ń dá mi lójú púpọ̀ tó pé, agbára káká ni irú ‘ìṣekòńgẹ́’ bẹ́ẹ̀ yóò fi ṣèèṣì ṣẹlẹ̀. Ṣùgbọ́n bí ìdánilójú yìí ṣe ń gbèrú sí i, ohun mìíràn gbèrú pẹ̀lú. Kódà, ó ṣòro nísinsìnyí láti ṣàlàyé ‘ohun’ yìí lọ́rọ̀. Ìfàsẹ́yìn jíjinlẹ̀ kan ni, ó sì máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ èyí tí ó ṣeé fojú rí lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Ara mi kì í lélẹ̀. . . . Ó ha ṣeé ṣe pé lójijì, láìsì rò tẹ́lẹ̀, a ṣèèṣì rí ẹ̀rí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa wíwà Olùwà Gíga Jù Lọ kan bí? Ṣé Ọlọrun ni ó lọ́wọ́ sí i tí ó sì ṣẹ̀dá àgbáálá ayé fún àǹfààní wa pẹ̀lú ìdarí àtọ̀runwá bí?”
Bí èrò náà ti mú ọkàn Greenstein gbọgbẹ́, tí ó sì bà á lẹ́rù, ó yára yọwọ́ nínú rẹ̀, ó sì kọ́fẹ padà sínú títẹ̀ lé ìlànà ìsìn tí a gbé karí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀, ó sì ké gbàjarè pé: “Ọlọrun kì í ṣe àlàyé náà.” Èyí kì í ṣe ìdí gúnmọ́ kan—ó wulẹ̀ jẹ́ pé kò bára dé fún un láti pa ọ̀rọ̀ náà mọ́ra ni!
Ohun Àdánidá Tí Ẹ̀dá Ènìyàn Nílò
Èyí kì í ṣe láti bẹnu àtẹ́ lu iṣẹ́ ńlá tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olótìítọ́ inú ń ṣe, títí kan ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa sánmà. Ní pàtàkì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa mọrírì ọ̀pọ̀ àwọn àwárí tí wọ́n ń ṣe nípa ìṣẹ̀dá, tí ń fi agbára àti ọgbọ́n àti ìfẹ́ Ọlọrun tòótọ́ náà, Jehofa, hàn. Romu 1:20 polongo pé: “Awọn ànímọ́ rẹ̀ tí a kò lè rí ni a rí ní kedere lati ìgbà ìṣẹ̀dá ayé síwájú, nitori a ń fi òye mọ̀ wọ́n nípasẹ̀ awọn ohun tí ó dá, àní agbára ayérayé ati Jíjẹ́ Ọlọrun rẹ̀, tó bẹ́ẹ̀ tí wọn kò ní àwíjàre.”
Àwọn ìwádìí àti iṣẹ́ tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ń ṣe jẹ́ ìhùwàpadà àdánidá ẹ̀dá ènìyàn sí àìní kan tí ó ṣe pàtàkì gan-an sí aráyé bíi àìní fún oúnjẹ, ibùgbé àti aṣọ. Ó jẹ́ àìní láti mọ ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè kan nípa ọjọ́ ọ̀la àti ète ìwàláàyè. Ọlọrun ti “fi èrò ayérayé sí ọkàn-àyà àwọn ènìyàn; síbẹ̀ wọn kò lè lóye ohun tí Ọlọrun ti ṣe láti ìbẹ̀rẹ̀ dé òpin.”—Oniwasu 3:11, The Holy Bible—New International Version.
Èyí kì í ṣe ìròyìn tí ó burú tó bẹ́ẹ̀. Ó túmọ̀ sí pé aráyé kò lè mọ gbogbo rẹ̀ tán, ṣùgbọ́n bẹ́ẹ̀ náà ni wọn kò ní fìgbà kan máà ní ohun tuntun láti kọ́: “Mo wo gbogbo iṣẹ́ Ọlọrun, pé ènìyàn kò lè rídìí iṣẹ́ tí a ń ṣe lábẹ́ oòrùn: nítorí pé, bí ènìyàn tilẹ̀ gbìyànjú àti wádìí rẹ̀, síbẹ̀ kì yóò lè rí i; àti pẹ̀lúpẹ̀lú bí ọlọ́gbọ́n ènìyàn rò láti wádìí rẹ̀, síbẹ̀ kì yóò lè rídìí rẹ̀.”—Oniwasu 8:17.
Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ kan jiyàn pé, fífi Ọlọrun ṣe “ojútùú” sí ìṣòro kan yóò fòpin sí ìsúnniṣe fún ìwádìí síwájú sí i. Bí ó ti wù kí ó rí, ẹnì kan tí ó bá ka Ọlọrun sí Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé ní ọ̀pọ̀ yanturu àwọn kúlẹ̀kúlẹ̀ amóríyá láti ṣàwárí àti àwọn ohun àràmàǹdà tí ń rú ọkàn-ìfẹ́ sókè láti wádìí. Ńṣe ni yóò jọ pé a fún un ní ọlá àṣẹ láti máa bá a lọ nínú ìrírí amọ́kànyọ̀ ti ṣíṣe àwárí ohun tuntun àti ìkẹ́kọ̀ọ́!
Ta ni kò ní tẹ́wọ́ gba ìkésíni inú Isaiah 40:26 náà? “Gbé ojú yín sókè síbi gíga, kí ẹ sì wò.” A ti gbé ojú wa sókè síbi gíga nínú àwọn ojú ewé díẹ̀ yìí, ohun tí a sì rí ni ‘ohun tí ó kù’ tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà kò mọ̀. A tún ti rí àwọn ìdáhùn pàtàkì sí àwọn ìbéèrè tí ń wá léraléra, tí ń yọ èrò inú ènìyàn lẹ́nu láti ọdún púpọ̀.
A Rí Àwọn Ìdáhùn Náà Nínú Ìwé Kan
Gbogbo ìgbà ni àwọn ìdáhùn náà máa ń wà níbẹ̀, ṣùgbọ́n bíi ti àwọn onísìn ọjọ́ Jesu, àwọn ènìyàn púpọ̀ ti fọ́ ara wọn lójú, wọ́n ti dijú wọn, wọ́n sì ti mú ọkàn-àyà wọn yigbì sí àwọn ìdáhùn tí kò bá àwọn àbá èrò orí ti ẹ̀dá ènìyàn wọn tàbí ọ̀nà ìgbésí ayé tí wọ́n yàn mu. (Matteu 13:14, 15) Jehofa ti sọ ibi tí àgbáálá ayé ti wá fún wa, bí ilẹ̀ ayé ṣe dé ìhín, àti àwọn tí wọn óò gbé orí rẹ̀. Ó ti wí fún wa pé àwọn ẹ̀dá ènìyàn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ tọ́jú rẹ̀ kí wọ́n sì fi tìfẹ́tìfẹ́ bójú tó àwọn irúgbìn àti àwọn ẹranko tí ń bá wọn ṣàjọpín rẹ̀. Ó tún ti sọ fún wa ohun tí ń ṣẹlẹ̀ nígbà tí àwọn ènìyàn bá kú, pé wọ́n lè padà ní ìwàláàyè, àti ohun tí wọ́n gbọ́dọ̀ ṣe láti wà láàyè lórí ilẹ̀ ayé títí láé.
Bí o bá ní ọkàn-ìfẹ́ nínú pé kí a fún ọ ní àwọn ìdáhùn ní èdè ti Ọ̀rọ̀ onímìísí Ọlọrun, Bibeli, jọ̀wọ́ ka àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ tí ó tẹ̀ lé e yìí: Genesisi 1:1, 26-28; 2:15; Owe 12:10; Matteu 10:29; Isaiah 11:6-9; 45:18; Genesisi 3:19; Orin Dafidi 146:4; Oniwasu 9:5; Ìṣe 24:15; Johannu 5:28, 29; 17:3; Orin Dafidi 37:10, 11; Ìṣípayá 21:3-5.
O kò ṣe ka àwọn ẹsẹ̀ ìwé mímọ́ wọ̀nyí pẹ̀lú ìdílé rẹ tàbí pẹ̀lú aládùúgbò kan tàbí pẹ̀lú àwùjọ àwọn ọ̀rẹ́ kan ní ilé rẹ ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan? Jẹ́ kí ó dá ọ lójú pé yóò jẹ́ ìjíròrò tí ó kún fún ẹ̀kọ́, tí ó sì gbádùn mọ́ni!
Àwọn ohun àràmàǹdà nípa àgbáálá ayé ha ń ru ọkàn-ìfẹ́ rẹ sókè bí, ẹwà rẹ̀ ha sì ń wú ọ lórí bí? O kò ṣe gbìyànjú láti túbọ̀ mọ Ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ dáradára sí i? Ìfẹ́ ìtọpinpin àti ìyàlẹ́nu tí a ń ní kò túmọ̀ sí nǹkan kan sí ọ̀run tí ó ṣeé fojú rí, ṣùgbọ́n Jehofa Ọlọrun, Ẹlẹ́dàá wọn, ni Ẹlẹ́dàá àwa pẹ̀lú, ó sì bìkítà fún àwọn ọlọ́kàn tútù ènìyàn tí wọ́n lọ́kàn-ìfẹ́ nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ nípa òun àti àwọn ìṣẹ̀dá rẹ̀. A ń nawọ́ ìkésíni náà jákèjádò ayé pé: “‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí ń gbọ́ sì wí pé: ‘Máa bọ̀!’ Kí ẹnikẹ́ni tí òùngbẹ ń gbẹ sì máa bọ̀; kí ẹnikẹ́ni tí ó bá fẹ́ gba omi ìyè lọ́fẹ̀ẹ́.”—Ìṣípayá 22:17.
Ẹ wo irú ìkésíni amọ́kànyọ̀ tí èyí jẹ́ láti ọ̀dọ̀ Jehofa! Dípò kí àgbáálá ayé jẹ́ nípasẹ̀ ìbúgbàù aláìnírònú, tí kò ní ète kan, ẹni tí ó ṣẹ̀dá rẹ̀ ni Ọlọrun tí ìlọ́gbọ́nlóye rẹ̀ kò lópin tí ó sì ní ète pàtó lọ́kàn, ẹni tí ó ní ọ lọ́kàn láti ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Ó ń fi tìṣọ́ratìṣọ́ra ṣàkóso àkójọ agbára aláìlópin rẹ̀, ó sì máa ń wà lárọ̀ọ́wọ́tó nígbà gbogbo láti gbé ẹ̀mí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ró. (Isaiah 40:28-31) Èrè ẹ̀san rẹ fún gbígbìyànjú láti mọ̀ ọ́n yóò jẹ́ aláìlópin bí àgbáálá ayé ọlọ́láńlá náà fúnra rẹ̀ kò ti lópin!
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 13]
Àkọsílẹ̀ Díẹ̀ Lára Àwọn Ohun Tí Kò Ṣeé Yí Padà, Tí Ó Ṣeé Fojú Rí, Tí Ó Pọn Dandan fún Ìwàláàyè Láti Máa Bá A Lọ
Iná tí ó wọ ara electron àti proton gbọ́dọ̀ dọ́gba, kí wọ́n sì dojú kọra; neutron gbọ́dọ̀ fi ìpín díẹ̀ nínú ọgọ́rùn-ún tẹ̀wọ̀n ju proton lọ; ìbáradọ́gba gbọ́dọ̀ wà láàárín ìwọ̀n ìgbóná òun ìtutù oòrùn àti àwọn ohun àfojúrí chlorophyll kí photosynthesis tó lè ṣẹlẹ̀; bí ipá lílágbára rẹ̀ kò bá fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, oòrùn kò ní lè mú agbára jáde nípa ìṣiṣẹ́padà àwọn agbára átọ́míìkì, ṣùgbọ́n bí ó bá lágbára, epo tí a nílò láti mú agbára jáde yóò máa ru gùdù láìsilẹ̀; láìsí ohun tí ń ṣèpínkiri ohun àfojúrí méjì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú àárín gbùngbùn àwọn ìràwọ̀ ràgàjì pupa, kò sí èròjà tí ó tayọ helium tí a ì bá ti mú jáde; bí ó bá ṣe pé òfuurufú dín sí ìwọ̀n onípele mẹ́ta ni, ìsokọ́ra káàkiri tí ó wà fún ìṣànkiri ẹ̀jẹ̀ àti ètò ìgbékalẹ̀ iṣan ọpọlọ kò ní ṣeé ṣe; bí ó bá sì ti jẹ́ pé gbalasa òfuurufú pọ̀ ju ìwọ̀n onípele mẹ́ta lọ ni, àwọn pílánẹ́ẹ̀tì kò ní lè dáró láti yí oòrùn po.—The Symbiotic Universe, ojú ewé 256 sí 257.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 14]
Ta Ló Bá Mi Rí Ìṣù Mi Tí Ó Kù?
Bíi gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ayíbírí, ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ Andromeda ń yí po nínú ọláńlá ní gbalasa òfuurufú bíi pé ìjì líle kan ni. Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà lè ṣírò ìwọ̀n àyípoyípo ọ̀pọ̀ àwọn ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ láti inú ìgbì ìmọ́lẹ̀, tí wọ́n bá sì ṣe bẹ́ẹ̀, wọn óò rí ohun rírúni lójú kan. Ó jọ pé ìwọ̀n àyípoyípo rẹ̀ ti kàmàmà jù! Ó jọ pé gbogbo ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ ayíbírí ti ń yára jù. Wọ́n máa ń ṣe bíi pé àwọn ìràwọ̀ tí ó ṣeé fojú rí nínú ètò ìgbékalẹ̀ ìṣùpọ̀ ìràwọ̀ sá pamọ́ sáàárín ìṣùjọ àwọn ohun dúdú kan tí ó túbọ̀ tóbi, tí awò asọǹkan-di-ńlá kò lè rí. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ sánmà, James Kaler, jẹ́wọ́ pé: “A kò mọ bí àwọn ohun dúdú náà ṣe rí.” Àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé fojú díwọ̀n pé, ìpín 90 nínú ọgọ́rùn-ún lára ìṣù tí ó kù náà ni a kò mọ bí wọ́n ṣe rìn ín. Wọ́n ń jà kìtàkìtà láti wá a rí, yálà bí òkìtì egunrín tàbí bí irú àwọn ohun púpọ̀ jaburata tí a kò mọ̀.
Bí o bá rí ìṣù tí ó kù náà, rí i dájú pé o fi tó onímọ̀ ìjìnlẹ̀ nípa ìpìlẹ̀ òun ìrísí ayé tí ó wà ládùúgbò rẹ létí lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀!