Èé Ṣe Tí A Fi Dá Ilé Ẹjọ́ Jákèjádò Àwọn Orílẹ̀-èdè Europe Sílẹ̀?
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ NETHERLANDS
NÍGBÀ tí a kọ̀ láti fún ẹni tí ó ni ilé ìtọ́kọ̀ṣe kan ní ìhà àríwá Netherlands ní ìyọ̀ǹda láti máa ta epo mọ́tò, tí ó tún dọ́gbọ́n túmọ̀ sí pé wọn kò ní fún un láyè láti yí ẹńjìnnì ọkọ̀ padà sí èyí tí ń lo epo náà, ó jà fitafita lọ láti pẹjọ́ ní onírúurú ilé ẹjọ́ kí wọ́n baà lè tú ìkálọ́wọ́kò tí ìjọba gbé lé e kúrò. Níbi tí ó ti ń ṣe eléyìí, ó wọko gbèsè.
Nítorí tí ó dà bí ẹni pé àwọn ilé ẹjọ́ Netherlands ti ṣẹjọ́ rẹ̀ lọ́nà tí kò tọ́, ó pẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe tí ó wà ni Strasbourg. Ní 1985, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe dá ẹjọ́ gbè é. Ẹni tí ó ni ilé ìtọ́kọ̀ṣe náà wo ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ náà dá gẹ́gẹ́ bí ìjagunṣẹ́gun ìwà híhù kíkàmàmà kan, nítorí pé, gẹ́gẹ́ bí ó ti sọ ọ́, ‘ó fi hàn pé òún wà lórí àre òun tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.’
Ó jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ àwọn ará ìlú orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe tí wọ́n ti pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe láàárín àwọn ẹ̀wádún tí ó ti kọjá. Kì í ṣe kìkì pé ilé ẹjọ́ yìí wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti gbọ́ àròyé àwọn ènìyàn tí ó wà ní Europe lẹ́nì kọ̀ọ̀kan nìkan ni, àmọ́ ó tún ń gbọ́ àròyé tí àwọn orílẹ̀-èdè ní sí orílẹ̀-èdè míràn, nígbà tí ó bá dà bí ẹni pé a tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn lójú. Pípọ̀ tí iye ẹjọ́ tí à ń gbé lọ sí àwọn ilé ẹjọ́ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè Europe ń pọ̀ fi hàn bí àwọn ará ìlú àti àwọn ìjọba kan ṣe ń yán hànhàn fún ìdájọ́ òdodo.
Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe
Ní ọdún 1950, ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe, tí gbogbo wọn kóra jọ pọ̀ nínú Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe, tí wọ́n sì pàdé ní Romu, pinnu láti ṣe àdéhùn kan nínú èyí tí wọ́n ti lè fi àwọn ẹ̀tọ́ àti òmìnira pàtó kan dá àwọn ará ìlú àti àwọn àjèjì tí ń gbé lábẹ́ àkóso wọn lójú. Nígbà tí ó yá, wọ́n fí àwọn ẹ̀tọ́ mìíràn kún un, nígbà tí ó sì jẹ́ pé nígbà kan náà, iye tí ń pọ̀ sí i lára àwọn orílẹ̀-èdè ilẹ̀ Europe ní ń dara pọ̀ mọ́ Àdéhùn Ilẹ̀ Europe náà, kí wọ́n baà lè dáàbò bo ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn àti àwọn òmìnira ṣíṣe kókó kan. Díẹ̀ lára àwọn ẹ̀tọ́ wọ̀nyí ní í ṣe pẹ̀lú dídáàbò bo ìwàláàyè àti ṣíṣe ìdíwọ́ fún dídá àwọn ènìyàn lóró, àwọn yòókù sì ní í ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé ìdílé àti òmìnira ìsìn, ti ọ̀rọ̀ sísọ, ti ojú ìwòye, àti ti pípéjọ pọ̀ àti kíkóra jọ. Ẹnikẹ́ni tí a bá tẹ ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn rẹ̀ yìí lójú lè gbé ẹ̀sùn dìde sí orílẹ̀-èdè náà lọ́dọ̀ọ akọ̀wé àgbà Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè Ilẹ̀ Europe.
Láti ìgbà tí ilé ẹjọ́ náà ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, ó ti jú 20,000 ẹ̀sùn lọ tí àwọn ènìyàn ti mú wá. Báwo ni ilé ẹjọ́ náà ṣe ń pinnu ẹjọ́ tí ó yẹ kí òun gbọ́? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, wọn yóò sapá láti bá wọ́n parí ìjà. Bí ìyẹn kò bá ṣeé ṣe, tí wọ́n sì ṣàkíyèsí pé ẹjọ́ náà lẹ́sẹ̀ nílẹ̀, wọn yóò gbé e lọ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe tí ó wà ní Strasbourg. Kìkì ìpín 5 nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn ẹ̀sùn tí wọ́n ń mú wá ló ń dé ilé ẹjọ́ náà. Títí fi di ìparí ọdún 1995, ilé ẹjọ́ náà tí dá ẹjọ́ 554. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹjọ́ tí ilé ẹjọ́ náà bá dá nígbà tí ẹnì kan bá gbé ẹ̀sùn kan dìde máa ń gbé orílẹ̀-èdè tí ọ̀ràn bá kàn dè, nígbà tí ó bá di ọ̀ràn pé orílẹ̀-èdè kan tàbí ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ló gbé ẹ̀sùn náà dìde, ọ̀ràn náà kì í ṣe kèrémí. Tí ó bá ti di ọ̀ràn bẹ́ẹ̀, àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé orílẹ̀-èdè tí a bá dá lẹ́bi yóò yan ipa ọ̀nà tí yóò lérè fún un ní ti ìṣèlú, dípò kí ó gbà pẹ̀lú ohun tí àdéhùn náà bèèrè fún. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé Ilé Ẹjọ́ Àgbáyé ní Hague máa ń yanjú kìkì èdèkòyedè tí ó bá wà láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe máa ń dájọ́ àwọn ọ̀ràn tí ó bá wà láàárín àwọn ará ìlú àti orílẹ̀-èdè.
Àwọn Ìdájọ́ Tí Ń Gbe Òmìnira Ìjọ́sìn ní Ilẹ̀ Europe Lẹ́yìn
Ní ọdún 1993, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn ti Ilẹ̀ Europe dé orí ìpinnu pàtàkì méjì kan tí ó gbe òmìnira ìjọsìn lẹ́yìn. Ọ̀ràn àkọ́kọ́ ni ti ọmọ ilẹ̀ Gíríìkì kan, Minos Kokkinakis. Nítorí pé ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, wọ́n ti fàṣẹ ọba mú un fún ohun tí ó ju 60 ìgbà lọ láti ọdún 1938, wọ́n sì ti mú kí ó fara hàn nígbà 18 níwájú àwọn ilé ẹjọ́ ilẹ̀ Gíríìkì, ó sì ti lo ohun tí ó ju ọdún mẹ́fà lọ ní ọgbà ẹ̀wọ̀n.
Ní May 25, 1993, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe dájọ́ pé ìjọba ilẹ̀ Gíríìkì ti tẹ òmìnira ìsìn tí Minos Kokkinakis, tí ó jẹ́ ọmọ ọdún 84 nígbà náà, ní lójú, wọ́n sì sọ pé kí wọ́n san owó ìtanràn tí ó jẹ́ 14,400 dọ́là fún un. Ilé ẹjọ́ kò gba awuyewuye ìjọba ilẹ̀ Gíríìkì náà pé, Kokkinakis àti àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa lápapọ̀ máa ń lo ọgbọ́n ìfagbáramúni nígbà tí wọ́n bá ń jíròrò nípa ìsìn wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn.—Fún àfikún ìsọfúnni, wo Ilé-Ìṣọ́nà ti September 1, 1993, ojú ewé 27 sí 31.
Nínú ẹjọ́ kejì, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe dá àre fún Ingrid Hoffmann ti Austria. Nítorí pé ó di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa nígbà tí ó wà nílé ọkọ, a kò fún un ní ẹ̀tọ́ àtibójútó àwọn ọmọ rẹ̀ méjì, lẹ́yìn tí ó ti kọ ọkọ rẹ̀ sílẹ̀. Ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, àwọn ilé ẹjọ́ kéékèèké ti fún un ní ẹ̀tọ́ àtibójútó àwọn ọmọ, ṣùgbọ́n, Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ fi ẹ̀tọ́ náà fún ọkọ rẹ̀ tí ó jẹ́ Kátólíìkì. Ilé ẹjọ́ náà gbé ìgbésẹ̀ wọn lórí òfin Austria kan tí ó sọ pè, a gbọ́dọ̀ tọ́ àwọn ọmọ dàgbà nínú ìsìn Kátólíìkì bí àwọn òbí náà bá jẹ́ ẹlẹ́sìn Kátólíìkì nígbà tí wọ́n ṣègbeyàwó, àyàfi tí àwọn méjèèjì bá gbà láti yí ìsìn wọn padà. Ọkọ rẹ̀ àná náà ránnu mọ́ ọn pé, nísinsìnyí tí ìyàwó ti di ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jehofa, kò ṣeé ṣe fún un láti tọ́ àwọn ọmọ dàgbà lọ́nà tí ó bójú mu, tí ó sì tọ́. Ní June 23, 1993, Ilé Ẹjọ́ Ilẹ̀ Europe dájọ́ pé Austria ti ṣègbè nínú ọ̀ràn Ìyáàfin Hoffmann nítorí ìsìn rẹ̀, àti pé wọ́n ti tẹ ẹ̀tọ́ tí ó ní láti bójú tó ìdílé rẹ̀ lójú. Wọ́n sọ pé kí wọ́n sanwó ìtanràn fún un.—Fún àfikún ìsọfúnni, wo Jí! ti October 8, 1993, ojú ewé 15.
Àwọn ìdájọ́ yìí kan gbogbo àwọn ènìyàn tí wọn nífẹ̀ẹ́ òmìnira ìsìn àti ti ọ̀rọ̀ sísọ. Pípẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn sí àwọn ilé ẹjọ́ jákèjádò àwọn orílẹ̀-èdè Europe lè pa kún ààbò ẹ̀tọ́ ṣíṣe kókó tí àwọn ará ìlú ní. Ó tún lọ́gbọ́n nínú láti mọ ààlà àwọn ẹ̀ka ìdájọ́. Kò sí bí èrò wọn ti lè dára tó láyé yìí, wọn kò lè mú àlàáfíà tí ó wà pẹ́ títí àti ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún ẹ̀tọ́ ọmọnìyàn dájú.